Fò sí àkóónú

circa AD 30–62

The Early Church

Pentecost ignites a movement; Peter, Paul, and countless others carry the gospel from Jerusalem to the ends of the earth.

1,007 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Ìṣe àwọn Aposteli 24:5nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    “Nítorí àwa rí ọkùnrin yìí, ó jẹ́ oníjàngbàn ènìyàn, ẹni tí ó ń dá rúkèrúdò sílẹ̀ láàrín gbogbo àwọn Júù tí ó wà ní gbogbo ayé. Òun ni aṣáájú búburú kan nínú ẹ̀yà àwọn Nasarene,

  2. Ìṣe àwọn Aposteli 24:6nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    ẹni tí ó gbìyànjú láti ba tẹmpili jẹ́.

  3. Ìṣe àwọn Aposteli 24:7nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    But the chief captain Lysias came upon us, and with great violence took him away out of our hands,

  4. Ìṣe àwọn Aposteli 24:8nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ìwọ fúnra rẹ̀ bá wádìí ọ̀rọ̀ fínní fínní lẹ́nu rẹ̀, ìwọ ó lè ní òye òtítọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí àwa fi ẹ̀sùn rẹ̀ kàn án.”

  5. Ìṣe àwọn Aposteli 24:9nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn Júù pẹ̀lú sì fi ohùn sí i wí pé, ní òtítọ́ bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.

  6. Ìṣe àwọn Aposteli 24:10nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí baálẹ̀ ṣẹ́wọ́ sì i pé kí ó sọ̀rọ̀, Paulu sì dáhùn wí pe, “Bí mo tí mọ̀ pé láti ọdún mélòó yìí wá, ní ìwọ tí ṣe onídàájọ́ orílẹ̀-èdè yìí, nítorí náà mo fi tayọ̀tayọ̀ wí tí ẹnu mi.

  7. Ìṣe àwọn Aposteli 24:11nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ìwọ pẹ̀lú sì ní òye rẹ̀ pé, ìjejìlá ni mo lọ sí Jerusalẹmu láti lọ jọ́sìn.

  8. Ìṣe àwọn Aposteli 24:12nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni àwọn olùfisùn mi kò rí mi kí ń máa bá ẹnikẹ́ni jiyàn nínú tẹmpili, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ru àwọn ènìyàn sókè nínú Sinagọgu tàbí ní ibikíbi nínú ìlú.

  9. Ìṣe àwọn Aposteli 24:13nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò lè fi ìdí ẹ̀sùn múlẹ̀ níwájú rẹ, èyí tí wọn fi mí sùn sí nísinsin yìí.

  10. Ìṣe àwọn Aposteli 24:14nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n, èmí jẹ́wọ́ fún ọ pé, èmi ń sin Ọlọ́run àwọn baba wa gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń tẹ̀lé ọ̀nà tí wọ́n ń pè ni ìyapa ìsìn. Èmi ń gbá gbogbo nǹkan ti a kọ sínú ìwé òfin gbọ́, àti tí a kọ sínú ìwé àwọn wòlíì,

  11. Ìṣe àwọn Aposteli 24:15nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    mo sí ní ìrètí kan náà nínú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí àwọn tìkára wọn jẹ́wọ́ pẹ̀lú, wí pé àjíǹde òkú ń bọ̀, àti tí olóòtítọ́, àti tí aláìṣòótọ́.

  12. Ìṣe àwọn Aposteli 24:16nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nínú èyí ni èmi sì ti ń gbìyànjú láti ní ẹ̀rí ọkàn tí kò lẹ́sẹ̀ sí Ọlọ́run, àti sí ènìyàn nígbà gbogbo.

  13. Ìṣe àwọn Aposteli 24:17nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    “Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdún púpọ̀, mo wá sí Jerusalẹmu láti mu ẹ̀bùn wá fún àwọn ènìyàn mi fún aláìní àti láti fi ọrẹ lélẹ̀.

  14. Ìṣe àwọn Aposteli 24:18nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nínú ṣíṣe nǹkan wọ̀nyí, wọ́n rí mí nínú ìyẹ̀wù tẹmpili, bí mo ti ń parí ètò ìwẹ̀nù, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ní àárín àwùjọ ènìyàn, tàbí pẹ̀lú ariwo.

  15. Ìṣe àwọn Aposteli 24:19nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n àwọn Júù kan láti ẹkùn Asia wà níbẹ̀, àwọn tí ìbá wà níhìn-ín yìí níwájú rẹ, kí wọn já mi nírọ́, bí wọ́n bá ní ohunkóhun sí mi.

  16. Ìṣe àwọn Aposteli 24:20nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí tìkára wọn sọ iṣẹ́ búburú tí wọ́n rí lọ́wọ́ mi, nígbà tí mo dúró níwájú àjọ ìgbìmọ̀.

  17. Ìṣe àwọn Aposteli 24:21nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Bí kò ṣe tí gbólóhùn kan yìí, tí mo kégbe rẹ̀ síta nígbà tí mo dúró láàrín wọn: ‘Èyí ni tìtorí àjíǹde òkú ni a ṣe ba mi wíjọ́ lọ́dọ̀ yín ló ni yìí!’ ”

  18. Ìṣe àwọn Aposteli 24:22nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí Feliksi gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, òye sá à ye é ní àyétán nípa ọ̀nà náà; ó tú wọn ká ná, ó ní, “Nígbà tí Lisia olórí ogun bá sọ̀kalẹ̀ wá, èmi ó wádìí ọ̀ràn yín dájú.”

  19. Ìṣe àwọn Aposteli 24:23nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì pàṣẹ fún balógun ọ̀run kan kí ó máa ṣe ìtọ́jú Paulu, kí ó fún un ní ààyè, àti pé kí ó má ṣe dá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lẹ́kun láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún un.

  20. Ìṣe àwọn Aposteli 24:24nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan Feliksi pẹ̀lú Drusilla ìyàwó rẹ̀ dé, obìnrin tí í ṣe Júù. Ó ránṣẹ́ pé Paulu, ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ nípa ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu.

  21. Ìṣe àwọn Aposteli 24:25nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Bí Paulu sì tí ń sọ àsọyé nípa tí òdodo àti àìrékọjá àti ìdájọ́ tí ń bọ̀, ẹ̀rù ba Feliksi, ó dáhùn wí pé, “Èyí tí o sọ nì tó ná! Máa lọ nísinsin yìí ná. Nígbà tí mo bá sì ní àkókò tí ó wọ̀, èmi ó ránṣẹ́ pè ọ́.”

  22. Ìṣe àwọn Aposteli 24:26nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ní àkókò yìí kan náà, ó ń retí pẹ̀lú pé Paulu yóò mú owó ẹ̀yìn wá fún òun, kí òun ba à lè dá a sílẹ̀, nítorí náà a sì máa ránṣẹ́ sì í nígbàkígbà, a máa bá a sọ̀rọ̀.

  23. Ìṣe àwọn Aposteli 24:27nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Lẹ́yìn ọdún méjì, Porkiu Festu rọ́pò Feliksi, Feliksi sì ń fẹ́ ṣe ojúrere fún àwọn Júù, ó fi Paulu sílẹ̀ nínú túbú.

  24. Ìṣe àwọn Aposteli 25:1nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tí ó dé sí ilẹ̀ náà, Festu gòkè láti Kesarea lọ sì Jerusalẹmu,

  25. Ìṣe àwọn Aposteli 25:2nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    ní ibi tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn pàtàkì nínú àwọn Júù ti gbé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Paulu wá, wọ́n sì bẹ̀ ẹ́.