- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 605–538 BC
The Babylonian Exile
Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Esekiẹli 37:14nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Èmi yóò fi èémí mi sínú yín, ẹ̀yin yóò sì yè, èmi yóò sì mú kí ẹ fi lélẹ̀ ní ilẹ̀ ẹ̀yin tìkára yín. Nígbà náà ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Olúwa ti sọ̀rọ̀, èmi sì ti ṣe ni Olúwa wí.’ ”
- Esekiẹli 37:15nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mi wá:
- Esekiẹli 37:16nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
“Ọmọ ènìyàn, mú igi pátákó kan kí ó sì kọ̀wé sí ara rẹ̀, ‘Tí ó jẹ́ ti Juda àti ti Israẹli tí ó ní àṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.’ Lẹ́yìn náà, kí ó mú igi pátákò mìíràn kí ó sì kọ̀wé sí ara rẹ̀, ‘Tí ó jẹ́ ti tí Josẹfu (tí ó túmọ̀ sí ti Efraimu) àti gbogbo ilé Israẹli tí ó ni àṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.’
- Esekiẹli 37:17nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
So wọ́n papọ̀ sí ara igi kan nítorí náà wọn yóò di ọ̀kan ní ọwọ́ rẹ.
- Esekiẹli 37:18nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
“Nígbà tí àwọn ara ìlú rẹ bá béèrè lọ́wọ́ rẹ pé, ‘Ṣé ìwọ kò ní sọ ohun tí èyí túmọ̀ sí fún wa?’
- Esekiẹli 37:19nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Sọ fún wọn pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò gba igi Josẹfu—èyí tí ó wà ní ọwọ́ Efraimu—àti ti ẹ̀yà Israẹli tí ó parapọ̀ mọ́ ọn, kí ó sì só papọ̀ mọ́ igi Juda, láti sọ wọ́n di igi kan ṣoṣo, wọn yóò sì di ọ̀kan ní ọwọ́ mi.’
- Esekiẹli 37:20nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Gbé igi pátákó tí ó kọ nǹkan sí i sókè ní iwájú wọn,
- Esekiẹli 37:21nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
kí ó sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò mú Israẹli jáde kúrò ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti lọ. Èmi yóò ṣà wọ́n jọ pọ̀ láti gbogbo agbègbè, èmi yóò sì mú wọn padà sí ilẹ̀ ara wọn.
- Esekiẹli 37:22nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Èmi yóò ṣe wọ́n ní orílẹ̀-èdè kan ní ilẹ̀ náà, ní orí òkè Israẹli, ọba kan ni yóò wà lórí gbogbo wọn, wọn kì yóò sì jẹ́ orílẹ̀-èdè méjì mọ́, tàbí kí a pín wọn sí ìjọba méjì.
- Esekiẹli 37:23nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Wọn kì yóò sì tún fi àwọn òrìṣà wọn ba ara wọn jẹ́ mọ́, tàbí ohun ìríra wọn, tàbí ohun ìrékọjá wọn: ṣùgbọ́n èmi yóò gbà wọn là kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àgàbàgebè wọn, èmi yóò sì wẹ̀ wọn mọ́. Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.
- Esekiẹli 37:24nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
“ ‘Dafidi ìránṣẹ́ mi ni yóò jẹ ọba lórí wọn, gbogbo wọn yóò sì ní olùṣọ àgùntàn kan. Wọn yóò sì tẹ̀lé òfin mi, wọn yóò sì ṣe àníyàn láti pa àṣẹ mi mọ́.
- Esekiẹli 37:25nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Wọn yóò gbé ní ilẹ̀ tí mo fún Jakọbu ìránṣẹ́ mi, ilẹ̀ tí àwọn baba yín ń gbé. Àwọn àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ọmọ ọmọ wọn ni yóò máa gbé ibẹ̀ láéláé, ìránṣẹ́ mi Dafidi ni yóò jẹ́ Ọmọ-aládé wọn láéláé.
- Esekiẹli 37:26nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Èmi yóò dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn, yóò sì jẹ́ májẹ̀mú títí ayérayé. Èmi yóò gbé wọn kalẹ̀, èmi yóò sì sọ wọ́n di púpọ̀ ní iye, èmi yóò sì gbé ilé mímọ́ mi kalẹ̀ ní àárín wọn títí láé.
- Esekiẹli 37:27nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Ibùgbé mí yóò wà pẹ̀lú wọn, Èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.
- Esekiẹli 37:28nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè yóò mọ̀ pé, Èmi Olúwa sọ Israẹli di mímọ́, nígbà tí ibi mímọ́ mi bá wà ní àárín wọn títí ayérayé.’ ”
- Esekiẹli 38:1nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Ọrọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
- Esekiẹli 38:2nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
“Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí Gogu, ti ilẹ̀ Magogu; olórí ọmọ-aládé, Meṣeki, àti Tubali sọtẹ́lẹ̀ ní ìlòdì sí i
- Esekiẹli 38:3nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Gogu, olórí ọmọ-aládé, Meṣeki àti Tubali.
- Esekiẹli 38:4nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Èmi yóò yí ọ kiri, èmi yóò sì fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní ẹnu, èmi yóò sì fà ọ́ jáde pẹ̀lú gbogbo ọmọ-ogun rẹ, àwọn ẹṣin àti àwọn agẹṣinjagun nínú ìhámọ́ra, àti ìpéjọ ńlá pẹ̀lú asà ogun ńlá àti kéékèèké, gbogbo wọn ń fi idà wọn.
- Esekiẹli 38:5nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Persia, Kuṣi àti Puti yóò wà pẹ̀lú wọn, gbogbo wọn yóò wà pẹ̀lú asà àti ìṣíborí wọn
- Esekiẹli 38:6nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Gomeri náà pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, àti Beti-Togarma láti jìnnàjìnnà àríwá pẹ̀lú gbogbo àwọn ọ̀wọ́ ogun rẹ̀—ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú rẹ̀.
- Esekiẹli 38:7nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
“ ‘Múra sílẹ̀, múra tán, kí ìwọ àti gbogbo ìjọ náà péjọpọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí o sì pàṣẹ fún wọn.
- Esekiẹli 38:8nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, àwa yóò bẹ̀ ọ wò; ní ọdún ìkẹyìn ìwọ yóò dó ti ilẹ̀ tí a ti gbà padà lọ́wọ́ idà, tí àwọn ènìyàn wọn kórajọ pọ̀ láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè sí àwọn òkè gíga ti Israẹli, tí ó ti di ahoro fún ìgbà pípẹ́. A ti mú wọn jáde láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, nísinsin yìí gbogbo wọn ń gbé ní àìléwu.
- Esekiẹli 38:9nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Ìwọ àti ọ̀wọ́ ogun rẹ àti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè pẹ̀lú rẹ yóò gòkè, ẹ̀yin yóò tẹ̀síwájú bí ìjì; ìwọ yóò dàbí ìkùùkuu tí ó bo ilẹ̀ mọ́lẹ̀.
- Esekiẹli 38:10nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
“ ‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ náà èrò kan yóò wá sọ́kàn rẹ, ìwọ yóò sì pète ìlànà búburú.