Fò sí àkóónú

circa 605–538 BC

The Babylonian Exile

Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.

1,784 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Esekiẹli 19:5nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    “ ‘Nígbà tí abo kìnnìún yìí rí pé ìrètí rẹ̀ sì jásí asán, ó mú ọmọ rẹ̀ mìíràn ó sì tún tọ́ ọ dàgbà di kìnnìún tó ní agbára.

  2. Esekiẹli 19:6nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Ó sì ń rìn káàkiri láàrín àwọn kìnnìún nítorí pé ó ti lágbára, o kọ ọdẹ ṣíṣe, ó sì pa àwọn ènìyàn.

  3. Esekiẹli 19:7nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Ó sì wó odi wọn palẹ̀ ó sì sọ àwọn ìlú wọn di ahoro. Ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé ibẹ̀ sì wà ní ìpayà nítorí bíbú ramúramù rẹ̀.

  4. Esekiẹli 19:8nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè dìde sí i, àwọn tó yìí ká láti ìgbèríko wá. Wọn dẹ àwọ̀n wọn fún un, wọn sì mú nínú ihò wọn.

  5. Esekiẹli 19:9nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Wọn fi ìwọ̀ gbé e sínú àgò, wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli, wọn fi sínú ìhámọ́, a kò sì gbọ́ bíbú rẹ̀ mọ́ lórí òkè Israẹli.

  6. Esekiẹli 19:10nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    “ ‘Ìyá rẹ dàbí àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ̀; tí á gbìn sí etí odò ó, kún fún èso, ó sì kún fún ẹ̀ka nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.

  7. Esekiẹli 19:11nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lágbára tó láti fi ṣe ọ̀pá àṣẹ ìjòyè, ó ga sókè láàrín ewé rẹ̀, gíga rẹ̀ hàn jáde láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ka rẹ̀.

  8. Esekiẹli 19:12nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ó fà á tu ní ìrunú, á sì wọ́ ọ lulẹ̀, afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn sì gbé èso rẹ̀, ọ̀pá líle rẹ̀ ti ṣẹ́, ó sì rọ iná sì jó wọn run.

  9. Esekiẹli 19:13nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Báyìí, a tún ún gbìn sínú aṣálẹ̀ ni ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tó ń pòǹgbẹ omi.

  10. Esekiẹli 19:14nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Iná sì jáde láti ọ̀kan lára ẹ̀ka rẹ̀ ó sì pa ẹ̀ka àti èso rẹ̀ run, dé bi pé kò sí ẹ̀ka tó lágbára lórí rẹ̀ mọ́; èyí to ṣe fi ṣe ọ̀pá fún olórí mọ́.’ Èyí ni orin ọ̀fọ̀ a o sì máa lo bí orin ọ̀fọ̀.”

  11. Esekiẹli 20:1nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    Ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù karùn-ún ọdún keje, ní díẹ̀ nínú àwọn àgbàgbà Israẹli wá wádìí lọ́wọ́ Olúwa, wọn jókòó níwájú mi.

  12. Esekiẹli 20:2nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé,

  13. Esekiẹli 20:3nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    “Ọmọ ènìyàn, sọ fún àwọn àgbàgbà Israẹli, kì ó sì wí fún wọn pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí, ṣe ki ẹ lè wádìí lọ́dọ̀ mi ni ẹ ṣe wá? Bí mo ti wà láààyè, ní Olúwa Olódùmarè wí, Èmi kì yóò gbà kí ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi.’

  14. Esekiẹli 20:4nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    “Ìwọ fẹ́ dájọ́ wọn bí? Ìwọ fẹ́ dájọ́ wọn bí ọmọ ènìyàn? Nítorí náà fi gbogbo ìwà ìríra baba wọn kò wọ́n lójú,

  15. Esekiẹli 20:5nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    kí ó sì sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí, ní ọjọ́ tí mo yàn Israẹli, mo gbé ọwọ́ mi sókè nínú ìbúra sí àwọn ọmọ ilé Jakọbu, mo sì fi ara mi hàn wọn ní Ejibiti, mo gbé ọwọ́ mi sókè nínú ẹ̀jẹ́ wí pé, “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.”

  16. Esekiẹli 20:6nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    Ní ọjọ́ náà mo lọ búra fún wọn pé, èmi yóò mú wọn jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti lọ sí ilẹ̀ ti mo ti wá sílẹ̀ fún wọn, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ilẹ̀ tí ó lẹ́wà jùlọ láàrín àwọn ilẹ̀ yòókù.

  17. Esekiẹli 20:7nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    Mo sì wí fún wọn pé, “Kí olúkúlùkù nínú yín gbé ìríra ojú rẹ̀ kúrò, kí ẹ sì má bá sọ ara yín di àìmọ́ pẹ̀lú àwọn òrìṣà Ejibiti, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.”

  18. Esekiẹli 20:8nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    “ ‘Ṣùgbọ́n wọn ṣọ̀tẹ̀ sí mi wọn kò sì gbọ́rọ̀, wọn kò gbé àwòrán ìríra tí wọ́n dojúkọ kúrò níwájú wọn bẹ́ẹ̀ ni wọn kò si kọ̀ àwọn òrìṣà Ejibiti sílẹ̀, torí náà mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú gbígbóná mi lé wọn lórí, èmi yóò sì jẹ́ kí ìbínú mi sẹ̀ lórí wọn ní ilẹ̀ Ejibiti.

  19. Esekiẹli 20:9nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mi, mo ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kí orúkọ mi bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ń gbé láàrín wọn, lójú àwọn ẹni tí mo ti fi ara hàn fún ara Israẹli nípa mímú wọn jáde ní ilẹ̀ Ejibiti.

  20. Esekiẹli 20:10nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà, mo mú wọn jáde ní ilẹ̀ Ejibiti mo sì mú wọn wá sínú aginjù.

  21. Esekiẹli 20:11nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    Mo sì fún wọn ni òfin mi, mo sì fi àwọn òfin mi hàn wọ́n; nítorí pé ẹni tó bá ṣe wọ́n yóò yè nípa wọn.

  22. Esekiẹli 20:12nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni mo fún wọn ní ọjọ́ ìsinmi gẹ́gẹ́ bí àmì láàrín àwọn àti èmi, kí wọn lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa tó sọ wọn di mímọ́.

  23. Esekiẹli 20:13nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    “ ‘Síbẹ̀; ilé Israẹli ṣọ̀tẹ̀ sí mí nínú aginjù. Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn sì kọ àwọn òfin mi sílẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá pa á mọ́ yóò yè nínú rẹ̀. Wọn sì sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́ lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Nítorí náà, mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú gbígbóná mi sórí wọn, èmi yóò sì pa wọ́n run nínú aginjù.

  24. Esekiẹli 20:14nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mi, mo ṣe ohun tí kò ní mú kí orúkọ mi bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí mo kó wọn jáde.

  25. Esekiẹli 20:15nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà, mo tún gbọ́wọ́ mi sókè ní ìbúra fún wọn nínú aginjù pé, èmi kì yóò mú wọn dé ilẹ̀ tí mo fi fún wọn—ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ilẹ̀ tí ó lẹ́wà jùlọ láàrín àwọn ilẹ̀ yòókù.