Fò sí àkóónú

Saul

265 ẹsẹ · 11 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Saul

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ó sì lé Dafidi jáde ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì fi jẹ olórí ogun ẹgbẹ̀rún kan (1,000), Dafidi ń kó wọn lọ, ó ń kó wọn bọ̀ nínú ìgbòkègbodò ogun.

  2. Nígbà tí Saulu rí bi àṣeyọrí rẹ̀ ti tó, ó sì bẹ̀rù rẹ̀.

  3. Saulu wí fún Dafidi pé, “Èyí ni àgbà nínú àwọn ọmọbìnrin mi Merabu. Èmi yóò fi òun fún ọ ní aya. Kí ìwọ sìn mí bí akọni, kí o sì máa ja ogun Olúwa.” Nítorí tí Saulu wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi kì yóò gbé ọwọ́ mi sókè sí i. Jẹ́ kí àwọn Filistini ṣe èyí.”

  4. Ṣùgbọ́n Dafidi wí fún Saulu pé, “Ta ni mí, kí sì ni ìdílé mi tàbí ìdílé baba mi ní Israẹli, tí èmi yóò di àna ọba?”

  5. Nígbà tí àkókò tó fún Merabu, ọmọbìnrin Saulu, láti fi fún Dafidi, ni a sì fi fún Adrieli ará Mehola ní aya.

  6. Nísinsin yìí ọmọbìnrin Saulu Mikali sì fẹ́ràn Dafidi, nígbà tí wọ́n sọ fún Saulu nípa rẹ̀, ó sì dùn mọ́ ọn.

  7. Ó sọ nínú ara rẹ̀ pé, “Èmi yóò fi fún un kí òun ba à le jẹ́ ìkẹ́kùn fún un, kí ọwọ́ àwọn ará Filistini lè wà lára rẹ̀.” Nígbà náà ni Saulu wí fún Dafidi pé, “Nísinsin yìí ìwọ ní àǹfààní eléyìí láti jẹ́ àna án mi.”

  8. Saulu pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ sọ fún Dafidi ní ìkọ̀kọ̀, kí ẹ sì wí pé, ‘Wò ó, inú ọba dùn sí ọ, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni ó fẹ́ràn rẹ, nísinsin yìí jẹ́ àna ọba.’ ”

  9. Wọ́n tún ọ̀rọ̀ náà sọ fún Dafidi. Ṣùgbọ́n Dafidi wí pé, “Ṣé ẹ rò pé ohun kékeré ni láti jẹ́ àna ọba? Mo jẹ́ tálákà ènìyàn àti onímọ̀ kékeré.”

  10. Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Saulu sọ fún un ohun tí Dafidi sọ,

  11. Saulu dáhùn pé, “Sọ fún Dafidi pé, ‘Ọba kò fẹ́ owó orí láti ọ̀dọ̀ àna rẹ̀ ju awọ iwájú orí ọgọ́rùn-ún Filistini lọ láti fi gba ẹ̀san lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.’ ” Èrò Saulu ni wí pé kí Dafidi ṣubú sí ọwọ́ àwọn ará Filistini.

  12. Dafidi àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jáde lọ wọ́n sì pa igba lára àwọn Filistini. Ó kó awọ iwájú orí wọn wá, ó sì pé iye tí ọba fẹ́ kí ó ba à lè jẹ́ àna ọba. Saulu sì fi ọmọ obìnrin Mikali fún un ní aya.

  13. Nígbà tí Saulu sì wá mọ̀ pé Olúwa wà pẹ̀lú Dafidi tí ọmọbìnrin rẹ̀ Mikali sì fẹ́ràn Dafidi,

  14. Saulu sì tún wá bẹ̀rù Dafidi síwájú àti síwájú, Saulu sì wá di ọ̀tá Dafidi fún gbogbo ọjọ́ rẹ̀ tókù.

  15. Àwọn ọmọ-aládé Filistini tún tẹ̀síwájú láti lọ sí ogun, ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n lọ, Dafidi ṣe àṣeyọrí ju gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Saulu lọ, orúkọ rẹ̀ sì gbilẹ̀.

  16. Saulu sọ fún Jonatani ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n pa Dafidi. Ṣùgbọ́n Jonatani fẹ́ràn Dafidi púpọ̀

  17. Jonatani sì kìlọ̀ fún Dafidi pé, “Baba mi Saulu wá ọ̀nà láti pa ọ́, kíyèsi ara rẹ di òwúrọ̀ ọ̀la; lọ sí ibi ìkọ̀kọ̀, kí o sì sá pamọ́ sí ibẹ̀.

  18. Jonatani sọ̀rọ̀ rere nípa Dafidi fún Saulu baba rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Má ṣe jẹ́ kí ọba kí ó ṣe ohun tí kò dára fún Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀; nítorí tí kò ṣẹ̀ ọ́, ohun tí ó sì ṣe pé ọ púpọ̀.

  19. Saulu fetísí Jonatani, ó sì búra báyìí, “Níwọ́n ìgbà tí Olúwa bá ti ń bẹ láààyè, a kì yóò pa Dafidi.”

  20. Nítorí náà Jonatani pe Dafidi, ó sì sọ gbogbo àjọsọ wọn fún un. Ó sì mú un wá fún Saulu, Dafidi sì wà lọ́dọ̀ Saulu gẹ́gẹ́ bí i ti tẹ́lẹ̀.

  21. Ṣùgbọ́n ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá sí orí Saulu bí ó ti jókòó ní ilé e rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. Bí Dafidi sì ti fọn ohun èlò orin olókùn,

  22. Saulu sì wá ọ̀nà láti gún un mọ́ ògiri pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n Dafidi yẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Saulu ti ju ọ̀kọ̀ náà mọ́ ara ògiri. Ní alẹ́ ọjọ́ náà Dafidi sì fi ara pamọ́ dáradára.

  23. Saulu rán ènìyàn sí ilé Dafidi láti ṣọ́ ọ kí wọ́n sì pa á ní òwúrọ̀. Ṣùgbọ́n Mikali, ìyàwó Dafidi kìlọ̀ fún un pé, “Tí o kò bá sá fún ẹ̀mí rẹ ní alẹ́ yìí, ní ọ̀la ni a yóò pa ọ́.”

  24. Nígbà ti Saulu rán ènìyàn láti lọ fi agbára mú Dafidi, Mikali wí pé, “Ó rẹ̀ ẹ́.”

  25. Nígbà náà ni Saulu rán ọkùnrin náà padà láti lọ wo Dafidi ó sì sọ fún wọn pé, “Mú wa fún mi láti orí ibùsùn rẹ̀ kí èmi kí ó le pa á.”