Fò sí àkóónú

Jesus

3,872 ẹsẹ · 6 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jesus Christ, Immanuel, Emmanuel, Christ

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jesus

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Sì kíyèsi i amòfin kan dìde, ó ń dán an wò, ó ní, “Olùkọ́, kín ni èmi ó ṣe kí èmi lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”

  2. Ó sì dáhùn wí pé, “ ‘Kí ìwọ fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ’; àti, ‘Ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.’ ”

  3. Ó sì wí fún un pé, “Ìwọ́ dáhùn rere. Ṣe èyí, ìwọ ó sì yè.”

  4. Ṣùgbọ́n ó ń fẹ́ láti da ara rẹ̀ láre, ó wí fún Jesu wí pé, “Ta ha sì ni ẹnìkejì mi?”

  5. Jesu sì dáhùn ó wí pé, “Ọkùnrin kan ń ti Jerusalẹmu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jeriko, ó sì bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà; wọ́n gbà á ní aṣọ, wọ́n sá a lọ́gbẹ́, wọ́n sì fi sílẹ̀ lọ ní àìpatán.

  6. Ó sì dáhùn wí pé, “Ẹni tí ó ṣàánú fún un ni.” Jesu sì wí fún un pé, “Lọ, kí o ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́!”

  7. Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, o wọ ìletò kan, obìnrin kan tí a ń pè ní Marta sì gbà á sí ilé rẹ̀.

  8. Ó sì ní arábìnrin kan tí a ń pè ní Maria tí ó sì jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Olúwa, tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

  9. Ṣùgbọ́n Marta ń ṣe ìyọnu ohun púpọ̀, ó sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Olúwa, ìwọ kò sì bìkítà sí ti arábìnrin mi pé ó fi mí sílẹ̀ láti máa nìkan ṣe ìránṣẹ́? Wí fún un kí ó ràn mí lọ́wọ́.”

  10. Ṣùgbọ́n Olúwa sì dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Marta, Marta, ìwọ ń ṣe àníyàn àti làálàá nítorí ohun púpọ̀.

  11. Bí ó ti ń gbàdúrà ní ibi kan, bí ó ti dákẹ́, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olúwa, kọ́ wa bí a ti ń gbàdúrà, bí Johanu ti kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.”

  12. Ó sì wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ máa wí pé: “ ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ yín. Kí ìjọba yín dé, ìfẹ́ tiyín ni kí a ṣe, bí i ti ọrun, bẹ́ẹ̀ ni ní ayé.

  13. Ó sì wí fún wọn pé, “Ta ni nínú yín tí yóò ní ọ̀rẹ́ kan, tí yóò sì tọ̀ ọ́ lọ láàrín ọ̀gànjọ́, tí yóò sì wí fún un pé, ‘Ọ̀rẹ́, yá mi ní ìṣù àkàrà mẹ́ta.

  14. Ó sì ń lé ẹ̀mí èṣù kan jáde, tí ó sì yadi. Nígbà tí ẹ̀mí èṣù náà jáde, odi sọ̀rọ̀; ẹnu sì ya ìjọ ènìyàn.

  15. Àwọn ẹlòmíràn sì ń dán an wò, wọ́n ń fẹ́ àmì lọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọ̀run wá.

  16. Ṣùgbọ́n òun mọ èrò inú wọn, ó wí fún wọn pé, “Gbogbo ìjọba tí ó ya ara rẹ̀ ní ipá, ni a ń sọ di ahoro; ilé tí ó sì ya ara rẹ̀ nípá yóò wó.

  17. Bí Satani ba yapa sí ara rẹ̀, ìjọba rẹ̀ yóò ha ṣe dúró? Nítorí ẹ̀yin wí pé, nípa Beelsebulu ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.

  18. Bí ó ba ṣe pé nípa Beelsebulu ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, nípa ta ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde, nítorí náà àwọn ni yóò ṣe onídàájọ́ yín.

  19. Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe pé nípa ìka ọwọ́ Ọlọ́run ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ǹjẹ́ ìjọba Ọlọ́run dé bá yín tán.

  20. “Ẹni tí kò bá wà pẹ̀lú mi, ó lòdì sí mi, ẹni tí kò bá sì bá mi kójọpọ̀, ó fọ́nká.

  21. Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, obìnrin kan gbóhùn rẹ̀ sókè nínú ìjọ, ó sì wí fún un pé, “Ìbùkún ni fún inú tí ó bí ọ, àti ọmú tí ìwọ mu!”

  22. Ṣùgbọ́n òun wí pé, nítòótọ́, kí ó kúkú wí pé, “Ìbùkún ni fún àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì pa á mọ́!”

  23. Nígbà tí ìjọ ènìyàn sì ṣùjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, “Ìran búburú ni èyí, wọ́n ń wá àmì; a kì yóò sì fi àmì kan fún un bí kò ṣe àmì Jona wòlíì!

  24. Nítorí bí Jona ti jẹ́ àmì fún àwọn ará Ninefe, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ Ènìyàn yóò ṣe jẹ́ àmì fún ìran yìí.

  25. Bí ó sì ti ń wí, Farisi kan bẹ̀ ẹ́ kí ó bá òun jẹun: ó sì wọlé, ó jókòó láti jẹun.