Jesus
A tún mọ̀ ọ́n sí: Jesus Christ, Immanuel, Emmanuel, Christ
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jesus
Ó sì kìlọ̀ fún wọn, pé, kí wọn má ṣe sọ èyí fún ẹnìkan.
Ó sì wí pé, “Ọmọ ènìyàn yóò jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà, olórí àlùfáà àti láti ọ̀dọ̀ àwọn akọ̀wé, a ó sì pa á, ní ọjọ́ kẹta a ó sì jí i dìde.”
Ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Bí ẹnìkan bá ń fẹ́ láti máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀ ní ọjọ́ gbogbo, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.
Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ọkàn rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọkàn rẹ̀ nù nítorí mi, òun náà ni yóò sì gbà á là.
Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá tijú mi, àti ọ̀rọ̀ mi, òun ni Ọmọ Ènìyàn yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá dé inú ògo tirẹ̀, àti ti baba rẹ̀, àti ti àwọn angẹli mímọ́.
“Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹlòmíràn dúró níhìn-ín yìí, tí kì yóò rí ikú, títí wọn ó fi rí ìjọba Ọlọ́run.”
Ó sì ṣe bí ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Peteru àti Johanu àti Jakọbu, ó gun orí òkè lọ láti lọ gbàdúrà.
Bí ó sì ti ń gbàdúrà, àwọ̀ ojú rẹ̀ yípadà, aṣọ rẹ̀ sì funfun gbòò,
Sì kíyèsi i, àwọn ọkùnrin méjì, Mose àti Elijah, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀,
tí wọ́n fi ara hàn nínú ògo, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ikú rẹ̀, tí òun yóò ṣe parí ní Jerusalẹmu.
Ṣùgbọ́n ojú Peteru àti ti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wúwo fún oorun. Nígbà tí wọ́n sì tají, wọ́n rí ògo rẹ̀, àti ti àwọn ọkùnrin méjèèjì tí ó bá a dúró.
Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, Peteru wí fún Jesu pé, “Olùkọ́, ó dára fún wa kí a máa gbé ìhín yìí, jẹ́ kí àwa pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fún ìwọ, àti ọ̀kan fún Mose, àti ọ̀kan fún Elijah.” (Kò mọ èyí tí òun ń wí.)
Ohùn kan sì ti inú ìkùùkuu wá wí pé, “Èyí yìí ni àyànfẹ́ ọmọ mi: ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.”
Nígbà tí ohùn náà sì dákẹ́, Jesu nìkan ṣoṣo ni a rí. Wọ́n sì pa á mọ́, wọn kò sì sọ ohunkóhun tí wọ́n rí fún ẹnikẹ́ni ní ọjọ́ wọ̀nyí.
Ó sì ṣe, ní ọjọ́ kejì, nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti orí òkè, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn wá pàdé rẹ̀.
Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan nínú ìjọ ènìyàn kígbe sókè pé, “Olùkọ́ mo bẹ̀ ọ́, wo ọmọ mi: nítorí ọmọ mi kan ṣoṣo náà ni.
Mo sì bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ láti lé e jáde: wọn kò sì lè ṣe é.”
Jesu sì dáhùn pé, “Ìran aláìgbàgbọ́ àti àrékérekè, èmi ó ti bá yín gbé pẹ́ tó? Èmi yóò sì ti ṣe sùúrù fún yín pẹ́ tó? Fa ọmọ rẹ wá níhìn-ín yìí.”
Bí ó sì ti ń bọ̀, ẹ̀mí èṣù náà gbé e ṣánlẹ̀, ó sì nà án tàntàn. Jesu sì bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí, ó sì mú ọmọ náà láradá, ó sì fà á lé baba rẹ̀ lọ́wọ́.
Ẹnu sì ya gbogbo wọn sí iṣẹ́ títóbi Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nígbà tí hà sì ń ṣe gbogbo wọn sí ohun gbogbo tí Jesu ṣe, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé,
“Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wọ̀ yín létí, nítorí a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́.”
Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà kò yé wọn, ó sì ṣú wọn lójú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì mọ̀ ọ́n: ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti béèrè ìdí ọ̀rọ̀ náà.
Nígbà tí Jesu sì mọ èrò ọkàn wọn, ó mú ọmọdé kan, ó gbé e jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀.
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọdé yìí nítorí orúkọ mi, ó gbà mí: àti ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi: nítorí ẹni tí ó bá kéré jù nínú gbogbo yín, òun náà ni yóò pọ̀jù.”
Johanu sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́, àwa rí ẹnìkan ó ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde; àwa sì dá a lẹ́kun, nítorí tí kò bá wa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”