Fò sí àkóónú

Jesus

3,872 ẹsẹ · 6 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jesus Christ, Immanuel, Emmanuel, Christ

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jesus

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà tí a sì ta ẹ̀jẹ̀ Stefanu ẹlẹ́rìí rẹ sílẹ̀, èmi náà pẹ̀lú dúró níbẹ̀, mo sì ní ohùn sí ikú rẹ̀, mo sì ń ṣe ìtọ́jú aṣọ àwọn ẹni tí ó pa á.’

  2. “Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, ‘Máa lọ; nítorí èmi ó rán ọ sí àwọn aláìkọlà lókèèrè réré.’ ”

  3. Ní òru ọjọ́ náà Olúwa dúró tì Paulu, ó wí pé, “Mú ọkàn le! Bí ìwọ ti jẹ́rìí fún mi ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò lè ṣàìjẹ́rìí ni Romu pẹ̀lú.”

  4. Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan Feliksi pẹ̀lú Drusilla ìyàwó rẹ̀ dé, obìnrin tí í ṣe Júù. Ó ránṣẹ́ pé Paulu, ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ nípa ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu.

  5. Ṣùgbọ́n wọ́n ní ọ̀ràn kan sí i, ní ti ìsìn wọn, àti ní ti Jesu kan tí o tí kú, tí Paulu tẹnumọ́ pé ó wà láààyè.

  6. “Èmi tilẹ̀ rò nínú ará mi nítòótọ́ pé, ó yẹ ki èmi ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun lòdì sí orúkọ Jesu tí Nasareti.

  7. Gbogbo wa sì ṣubú lulẹ̀, mo gbọ́ ohùn tí ń fọ sì mi ni èdè Heberu pé, ‘Saulu, Saulu! Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi? Ohun ìrora ní fún ọ láti tàpá sí ẹ̀gún!’

  8. “Èmi sì wí pé, ‘Ìwọ ta ni, Olúwa?’ “Olúwa sì wí pé, ‘Èmi ni Jesu tí ìwọ ń ṣe inúnibíni sí.

  9. Ṣùgbọ́n dìde, kí o sí fi ẹsẹ̀ rẹ tẹlẹ̀: nítorí èyí ni mo ṣe farahàn ọ́ láti yàn ọ́ ní ìránṣẹ́ àti ẹlẹ́rìí, fún ohun wọ̀nyí tí ìwọ tí rí nípa mi, àti àwọn ohun tí èmi yóò fi ara hàn fún ọ.

  10. Èmi yóò gbà ọ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn rẹ àti lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́. Èmi rán ọ sí wọn nísinsin yìí

  11. láti là wọ́n lójú, kí wọn lè yípadà kúrò nínú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ agbára Satani sí Ọlọ́run, kí wọn lè gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, àti ogún pẹ̀lú àwọn tí a sọ di mímọ́ nípa ìgbàgbọ́ nínú mi.’

  12. Pé, Kristi yóò jìyà, àti pé òun ni yóò jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láti jíǹde kúrò nínú òkú, òun ni yóò sí kéde ìmọ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn àti fún àwọn aláìgbàgbọ́.”

  13. Àwọn fi ẹnu kò lórí ọjọ́ tí wọn yóò ṣe ìpàdé pẹ̀lú Paulu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni ó tọ̀ ọ́ wa ni ilé àgbàwọ̀ rẹ̀; àwọn ẹni tí òun sọ àsọyé ọ̀rọ̀ ìjọba Ọlọ́run fún, ó ń yí wọn padà nípa ti Jesu láti inú òfin Mose àti àwọn wòlíì, láti òwúrọ̀ títí ó fi di àṣálẹ́.

  14. Ó ń wàásù ìjọba Ọlọ́run, ó ń fi ìgboyà kọ́ni ní àwọn ohun tí i ṣe ti Jesu Kristi Olúwa, ẹnìkan kò si dá a lẹ́kun.

  15. Paulu, ìránṣẹ́ Jesu Kristi, ẹni tí a ti pè láti jẹ́ aposteli, tí a sì ti yà sọ́tọ̀ láti wàásù ìyìnrere Ọlọ́run,

  16. Ní ti Ọmọ rẹ̀, ẹni tí a bí láti inú irú-ọmọ Dafidi nípa ti ara,

  17. ẹni tí a pinnu rẹ̀ láti jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run nínú agbára gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ìwà mímọ́, nípa àjíǹde kúrò nínú òkú, àní Jesu Kristi Olúwa wa.

  18. Láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwa rí oore-ọ̀fẹ́ àti jíjẹ́ aposteli gbà, fún ìgbọ́ràn ìgbàgbọ́ láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè, nítorí orúkọ rẹ̀.

  19. Ẹ̀yin pẹ̀lú si wa lára àwọn tí a pè sọ́dọ̀ Jesu Kristi.

  20. Sí gbogbo àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà ní Romu tí a ti pè láti jẹ́ ènìyàn mímọ́: Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa Jesu Kristi.

  21. Ní àkọ́kọ́, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ Jesu Kristi fún gbogbo yín, nítorí a ń ròyìn ìgbàgbọ́ yin káàkiri gbogbo ayé.

  22. Ọlọ́run ṣá à ni ẹlẹ́rìí mi, ẹni tí èmí ń fi gbogbo ẹ̀mí mi sìn nínú ìyìnrere Ọmọ rẹ̀, bí ó ti ṣe pé ní àìsimi ni èmí ń rántí yín nígbà gbogbo nínú àdúrà mi

  23. Èmi kò tijú ìyìnrere Jesu, nítorí agbára Ọlọ́run ní ín ṣe láti gba gbogbo àwọn tí ó bá gbàgbọ́ là, ọ̀rọ̀ yìí ni a kọ́kọ́ wàásù sí àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nísinsin yìí fún àwọn Helleni pẹ̀lú.

  24. Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀, bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí.

  25. Èyí yóò farahàn ní ọjọ́ náà nígbà tí Ọlọ́run yóò tipasẹ̀ Jesu Kristi ṣe ìdájọ́ àwọn àṣírí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìyìnrere mi.