Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà tí ipa ọ̀nà rẹ bá lọ sísàlẹ̀, nígbà náà ni ìwọ o wí pé, ‘Ìgbésókè ń bẹ!’ Ọlọ́run yóò sì gba onírẹ̀lẹ̀ là!

  2. Háà! èmi ìbá mọ ibi tí èmí ìbá wá Ọlọ́run rí, kí èmí kí ó tọ̀ ọ́ lọ sí ibùgbé rẹ̀!

  3. Èmi ìbá sì to ọ̀ràn náà níwájú rẹ̀, ẹnu mi ìbá sì kún fún àròyé.

  4. Èmi ìbá sì mọ ọ̀rọ̀ tí òun ìbá fi dá mi lóhùn; òye ohun tí ìbáwí a sì yé mi.

  5. Yóò ha fi agbára ńlá bá mi wíjọ́ bí? Àgbẹdọ̀, kìkì pé òun yóò sì kíyèsi mi.

  6. Níbẹ̀ ni olódodo le è bá a wíjọ́, níwájú rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì bọ́ ni ọwọ́ onídàájọ́ mi láéláé.

  7. “Sì wò ó, bí èmi bá lọ sí iwájú, òun kò sí níbẹ̀, àti sí ẹ̀yìn, èmi kò sì rí òye rẹ̀.

  8. Ni apá òsì bí ó bá ṣiṣẹ́ níbẹ̀, èmi kò rí i, ó fi ara rẹ̀ pamọ́ ni apá ọ̀tún, tí èmi kò le è rí i.

  9. Ṣùgbọ́n òun mọ ọ̀nà tí èmi ń tọ̀, nígbà tí ó bá dán mí wò, èmi yóò jáde bí wúrà.

  10. Ẹsẹ̀ mí ti tẹ̀lé ipasẹ̀ ìrìn rẹ̀; ọ̀nà rẹ̀ ni mo ti kíyèsi, tí ń kò sì yà kúrò.

  11. Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò padà sẹ́yìn kúrò nínú òfin ẹnu rẹ̀, èmi sì pa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ mọ́ ju oúnjẹ òòjọ́ lọ.

  12. “Ṣùgbọ́n onínú kan ni òun, ta ni yóò sì yí i padà? Èyí tí ọkàn rẹ̀ sì ti fẹ́, èyí náà ní í ṣe.

  13. Nítòótọ́ ohun tí a ti yàn fún mi ní í ṣe; ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú ohun bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀.

  14. Nítorí náà ni ara kò ṣe rọ̀ mí níwájú rẹ̀; nígbà tí mo bá rò ó, ẹ̀rù a bà mi.

  15. Nítorí pé Ọlọ́run ti pá mi ní àyà, Olódùmarè sì ń dààmú mi.

  16. Nítorí tí a kò tí ì ké mi kúrò níwájú òkùnkùn, bẹ́ẹ̀ ni kò pa òkùnkùn biribiri mọ́ kúrò níwájú mi.

  17. “Ṣe bí ìgbà kò pamọ́ lọ́dọ̀ Olódùmarè fún ìdájọ́? Èéṣe tí ojúlùmọ̀ rẹ̀ kò fi rí ọjọ́ rẹ̀?

  18. Àwọn ènìyàn ń kérora láti ìlú wá, ọkàn àwọn ẹni tí ó gbọgbẹ́ kígbe sókè fún ìrànlọ́wọ́ síbẹ̀ Ọlọ́run kò kíyèsi àṣìṣe náà.

  19. Ọlọ́run sì fi àìléwu fún un, àti nínú èyí ni a ó sì tì i lẹ́yìn, ojú rẹ̀ sì wà ní ipa ọ̀nà wọn.

  20. “Ìjọba àti ẹ̀rù ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀, òun ní i ṣe ìlàjà ní ibi gíga gíga ọ̀run.

  21. Àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ha ní ìyè bí, tàbí ara ta ni ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kò tàn sí?

  22. Èéha ti ṣe tí a ó fi dá ènìyàn láre lọ́dọ̀ Ọlọ́run? Tàbí ẹni tí a bí láti inú obìnrin wá yóò ha ṣe mọ́?

  23. Kíyèsi i, òṣùpá kò sì lè tàn ìmọ́lẹ̀, àní àwọn ìràwọ̀ kò mọ́lẹ̀ ní ojú rẹ̀,

  24. Ìhòhò ni ipò òkú níwájú Ọlọ́run, ibi ìparun kò sí ní ibojì.

  25. Ó di omi pọ̀ nínú ìkùùkuu àwọsánmọ̀ rẹ̀ tí ó nípọn; àwọsánmọ̀ kò sì ya nísàlẹ̀ wọn.