Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Uprightness

60 ẹsẹ · 55 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ó to ìgbàlà fún àwọn olódodo, Òun ni asà fún àwọn tí ń rìn déédé,

  2. ẹni tí ó kúrò ní ọ̀nà ìdúró ṣinṣin láti rìn ní ọ̀nà tí ó ṣókùnkùn,

  3. Nítorí ẹni dídúró ṣinṣin yóò gbé ní ilé náà àwọn aláìlẹ́gàn sì ni yóò máa wà nínú rẹ̀.

  4. Ẹni tí ó ń rìn déédé, ń rìn láìléwu, ṣùgbọ́n àṣírí ẹni tí ń rin ọ̀nà pálapàla yóò tú.

  5. Ọ̀nà Olúwa jẹ́ ààbò fún olódodo, ṣùgbọ́n ìparun ni ó jẹ́ fún àwọn tí ń ṣe ibi.

  6. Òtítọ́ inú ẹni dídúró ṣinṣin ń ṣe amọ̀nà rẹ̀, ṣùgbọ́n aláìṣòótọ́ yóò parun nípasẹ̀ àìṣòótọ́ wọn.

  7. Òdodo ẹni ìdúró ṣinṣin gbà wọ́n là, ṣùgbọ́n ìdẹ̀kùn ètè búburú mú aláìṣòótọ́.

  8. Nípasẹ̀ ìbùkún, olódodo a gbé ìlú ga: ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹnu ènìyàn búburú, a pa ìlú run.

  9. Olúwa kórìíra àwọn ènìyàn ọlọ́kàn búburú ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn tí ọ̀nà wọn kò lábùkù.

  10. Ọ̀rọ̀ ènìyàn búburú lúgọ de ẹ̀jẹ̀ ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ àwọn olódodo gbà wọ́n là.

  11. Òdodo ń ṣamọ̀nà ènìyàn olóòtítọ́ inú, ṣùgbọ́n ìwà búburú ṣí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ipò.

  12. Ẹni tí ń rìn déédé bẹ̀rù Olúwa, ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ kò tọ́ kẹ́gàn Olúwa.

  13. A ó pa ilé ènìyàn búburú run, ṣùgbọ́n àgọ́ olódodo yóò máa gbèrú sí i.

  14. Olúwa kórìíra ìrúbọ àwọn ènìyàn búburú ṣùgbọ́n àdúrà olódodo tẹ́ ẹ lọ́rùn.

  15. Inú ènìyàn aláìlóye a máa dùn sí ìwà òmùgọ̀; ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa rin ọ̀nà tààrà.

  16. Òpópó ọ̀nà àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yàgò fún ibi, ẹni tí ó ṣọ́ ọ̀nà rẹ̀, ṣọ́ ẹnu ara rẹ̀.

  17. Ó sàn kí ènìyàn jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ kò lábùkù ju aláìgbọ́n tí ètè rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà.

  18. Ènìyàn búburú mú ojú ara rẹ̀ le: ṣùgbọ́n ẹni ìdúró ṣinṣin ni ó ń mú ọ̀nà rẹ̀ tọ́.

  19. Ó sàn láti jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ jẹ́ aláìlábùkù ju ọlọ́rọ̀ tí ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla.

  20. Ẹni tí ó mú olódodo rìn ọ̀nà búburú yóò bọ́ sínú pàkúté ara rẹ̀ ṣùgbọ́n aláìlẹ́gàn yóò gba ogún rere.

  21. Ẹni tí ń rìn déédéé ní yóò là, ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà ni yóò ṣubú lójijì.

  22. Àwọn tí ó ń tàjẹ̀ sílẹ̀ kò rí ẹni dídúró ṣinṣin wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa olódodo.

  23. Bí ènìyàn kan bá kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lákẹ̀ẹ́jù láti kékeré yóò mú ìbànújẹ́ wá ní ìgbẹ̀yìn.

  24. Eléyìí nìkan ni mo tí ì rí: Ọlọ́run dá ìran ènìyàn dáradára, ṣùgbọ́n ènìyàn ti lọ láti ṣàwárí ohun púpọ̀.”

  25. Fà mí lọ pẹ̀lú rẹ, kí a lọ kíákíá ọba ti mú mi wá sínú yàrá rẹ̀. Ọ̀rẹ́ Àwa yọ̀ inú wa sì dùn sí ọ; a gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí wáìnì lọ. Olólùfẹ́ Wọ́n fẹ́ ọ nítòótọ́!