Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Unbelief

208 ẹsẹ · 61 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ta ni nínú yín tí ó ti dá mi lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀? Bí mo bá ń ṣọ òtítọ́, èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà mí gbọ́?

  2. Ẹni tí ń ṣe ti Ọlọ́run, a máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nítorí èyí ni ẹ̀yin kò ṣe gbọ́, nítorí ẹ̀yin kì í ṣe ti Ọlọ́run.”

  3. Àwọn Júù wí fún un pé, “Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé ìwọ ní ẹ̀mí èṣù. Abrahamu kú, àti àwọn wòlíì; ìwọ sì wí pé, ‘Bí ẹnìkan bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò tọ́ ikú wò láéláé.’

  4. Ìwọ ha pọ̀ ju Abrahamu Baba wa lọ, ẹni tí ó kú? Àwọn wòlíì sì kú, ta ni ìwọ ń fi ara rẹ pè?”

  5. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi ti wí fún yín, ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́; iṣẹ́ tí èmi ń ṣe lórúkọ Baba mi, àwọn ni ó ń jẹ́rìí mi.

  6. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbàgbọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí nínú àwọn àgùntàn mi, gẹ́gẹ́ bí mo tí wí fún yín.

  7. Bí èmi kò bá ṣe iṣẹ́ Baba mi, ẹ má ṣe gbà mí gbọ́.

  8. Ṣùgbọ́n bí èmi bá ṣe wọ́n, bí ẹ̀yin kò tilẹ̀ gbà mí gbọ́, ẹ gbà iṣẹ́ náà gbọ́, kí ẹ̀yin ba à lè mọ̀, kí ó sì lè yé yín pé, Baba wà nínú mi, èmi sì wà nínú rẹ̀.”

  9. Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì tó báyìí lójú wọn, wọn kò gbà á gbọ́.

  10. Kí ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah lè ṣẹ, èyí tí ó sọ pé, “Olúwa, ta ni ó gba ìwàásù wa gbọ́ Àti ta ni a sì fi apá Olúwa hàn fún?”

  11. Nítorí èyí ni wọn kò fi lè gbàgbọ́, nítorí Isaiah sì tún sọ pé,

  12. “Ó ti fọ́ wọn lójú, Ó sì ti sé àyà wọn le; kí wọn má ba à fi ojú wọn rí, kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀, kí wọn má ba à yípadà, kí èmi má ba à mú wọn láradá.”

  13. “Bí ẹnikẹ́ni bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí kò sì pa wọ́n mọ́, èmi kì yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ nítorí tí èmi kò wá láti ṣe ìdájọ́ ayé, bí kò ṣe láti gba ayé là.

  14. Ẹni tí ó bá kọ̀ mí, tí kò sì gba ọ̀rọ̀ mi, ó ní ẹnìkan tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀; ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ, òun náà ni yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn.

  15. Òun ni Ẹ̀mí òtítọ́. Ayé kò le gbà á. Nítorí ayé kò mọ̀ ọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò rí i rí. Ẹ̀yin mọ̀ ọn nítorí láti ìgbà tí ẹ ti wà pẹ̀lú mí. Òun náà ti wà pẹ̀lú yín. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan yóò wọ inú yín láti máa gbé ibẹ̀.

  16. Nígbà tí òun bá sì dé, yóò fi òye yé aráyé ní ti ẹ̀ṣẹ̀, àti ní ti òdodo, àti ní ti ìdájọ́,

  17. ní ti ẹ̀ṣẹ̀, nítorí tí wọn kò gbà mí gbọ́;

  18. Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù wí fún un pé, “Àwa ti rí Olúwa!” Ṣùgbọ́n ó wí fún un pé, “Bí kò ṣe pé mo bá rí àpá ìṣó ni ọwọ́ rẹ̀ kí èmi sì fi ìka mi sí àpá ìṣó náà, kí èmi sì fi ọwọ́ mi sí ìhà rẹ̀, èmi kì yóò gbàgbọ́!”

  19. Nígbà náà ni ó wí fún Tomasi pé, “Mú ìka rẹ wá níhìn-ín yìí, kí o sì wo ọwọ́ mi; sì mú ọwọ́ rẹ wá níhìn-ín, kí o sì fi sí ìhà mi: kí ìwọ má ṣe jẹ́ aláìgbàgbọ́ mọ́, ṣùgbọ́n jẹ́ onígbàgbọ́.”

  20. Nítorí náà, ẹ kíyèsára, kí èyí tí a ti sọ nínú ìwé àwọn wòlíì má ṣe dé bá yín pé:

  21. “ ‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn, kí ẹnu sì yà yín, kí a sì fẹ́ yín kù; nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín, tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́, bí a tilẹ̀ sọ fún yin.’ ”

  22. Ṣùgbọ́n àwọn aláìgbàgbọ́ Júù rú ọkàn àwọn aláìkọlà sókè, wọ́n sì mú wọn ni ọkàn ìkorò sí àwọn arákùnrin náà.

  23. Ṣùgbọ́n àwọn Júù jowú, wọn sì fa àwọn jàgídíjàgan nínú àwọn ọmọ ènìyàn mọ́ra, wọ́n ko ẹgbẹ́ jọ, wọ́n sì ń dá ìlú rú; wọ́n sì kọlu ilé Jasoni, wọ́n ń fẹ́ láti mú Paulu àti Sila jáde tọ àwọn ènìyàn lọ.

  24. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn àwọn mìíràn nínú wọn di líle, tí wọn kò sì gbàgbọ́, tí wọn ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọ̀nà náà níwájú ìjọ ènìyàn, ó lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sọ́tọ̀, ó sì ń sọ àsọyé lójoojúmọ́ ni ilé ìwé Tirannusi.

  25. mo sì rí Olúwa, ó ń sọ̀rọ̀ fún mi pé, ‘Kíá! Jáde kúrò ní Jerusalẹmu kánkán, nítorí wọn kì yóò gba ẹ̀rí rẹ nípa mi gbọ́.’