Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Time

82 ẹsẹ · 44 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹrin tí mo di ọmọ ọgbọ̀n ọdún tí mo wà láàrín àwọn ìgbèkùn ní etí odò Kebari, àwọn ọ̀run ṣí sílẹ̀, mo sì rí ìran Ọlọ́run.

  2. Ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kẹwàá, ọdún kejìlá ìkólọ wa, ọkùnrin kan tí ó sá kúrò ni Jerusalẹmu wá sọ́dọ̀ mi, ó sì wí pé, “Ìlú ńlá náà ti ṣubú!”

  3. Ní ọdún kẹẹdọ́gbọ̀n tí a ti wà ni oko ẹrú wa, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún, ni oṣù kẹwàá ọdún kẹrìnlá lẹ́yìn ìṣubú ìlú ńlá náà ní ọjọ́ náà gan an ọwọ́ Olúwa ń bẹ̀ lára mi, òun sì mú mi lọ síbẹ̀.

  4. Lójijì, ìka ọwọ́ ènìyàn jáde wá, ó sì ń kọ̀wé sára ẹfun ògiri ní ẹ̀gbẹ́ ibi tí fìtílà ń dúró ní ààfin ọba. Ọba ń wo ọwọ́ náà bí ó ṣe ń kọ ọ́.

  5. Yóò sọ̀rọ̀ odi sí Ọ̀gá-ògo, yóò sì pọ́n ẹni mímọ́ lójú, yóò sì gbèrò láti yí ìgbà àti òfin padà. A ó fi àwọn ẹni mímọ́ lé e lọ́wọ́ fún ìgbà díẹ̀, ní ọdún méjì àti ààbọ̀.

  6. Ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba rẹ̀, èmi Daniẹli fi iyè sí i láti inú ìwé, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí wòlíì Jeremiah, wá pé, àádọ́rin ọdún ni Jerusalẹmu yóò fi wà ní ahoro.

  7. Ní àsìkò náà, èmi Daniẹli ṣọ̀fọ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta.

  8. Ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò, gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti ọwọ́ òsì rẹ̀, mo gbọ́ tí ó fi ẹni tí ó wà títí láé búra, ó sọ wí pé, “Yóò ṣe ní àkókò kan, àkókò méjì àti ààbọ̀. Nígbà tí agbára àwọn ẹni mímọ́ yóò ti fọ́ tán pátápátá, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò sì parí.”

  9. Ní déédé ago mẹ́rin òwúrọ̀, Jesu tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi.

  10. Ó sì kéde wí pé, “Àkókò náà dé wàyí, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀. Ẹ yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì gba ìyìnrere yìí gbọ́.”

  11. Ó rí i wí pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wà nínú wàhálà púpọ̀ ní wíwa ọkọ̀ náà nítorí ti ìjì líle ṣe ọwọ́ òdì sí wọn, nígbà tí ó sì dì ìwọ̀n ìṣọ́ kẹrin òru, ó tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi Òkun, òun sì fẹ́ ré wọn kọjá,

  12. Ní ọdún kẹ́ẹ̀dógún ìjọba Tiberiu Kesari, nígbà tí Pọntiu Pilatu jẹ́ baálẹ̀ Judea, tí Herodu sì jẹ́ tetrarki Galili, Filipi arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ tetrarki Iturea àti ti Trakoniti, Lisania sì jẹ́ tetrarki Abilene,

  13. Lójúkan náà, èṣù sì mú un lọ sí orí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ ọba ayé hàn án.

  14. Àwọn ti orí àpáta ni àwọn, tí wọ́n gbọ́, wọ́n fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà, àwọn wọ̀nyí kò sì ní gbòǹgbò, wọ́n á gbàgbọ́ fún sá à díẹ̀; nígbà ìdánwò, wọn á padà sẹ́yìn.

  15. Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lójoojúmọ́.

  16. Èmi ń gbààwẹ̀ lẹ́ẹ̀méjì ní ọ̀sẹ̀, mo ń san ìdámẹ́wàá ohun gbogbo tí mo ní.’

  17. Jesu dáhùn pé, “Wákàtí méjìlá kọ́ ni ó bẹ nínú ọ̀sán kan bí? Bí ẹnìkan bá rìn ní ọ̀sán, kì yóò kọsẹ̀, nítorí tí ó rí ìmọ́lẹ̀ ayé yìí.

  18. Nítorí náà ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì yípadà sí Ọlọ́run, kí a lè pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àkókò ìtura bá a lè ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá,

  19. Ẹni tí ọ̀run kò lé ṣàìmá gbà títí di ìgbà ìmúpadà ohun gbogbo, tí Ọlọ́run ti sọ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tí wọn ti ń bẹ nígbà tí ayé ti ṣẹ̀.

  20. Ó sì tí tipasẹ̀ ẹnìkan dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti tẹ̀dó sí ojú àgbáyé, ó sì ti pinnu àkókò tí a yàn tẹ́lẹ̀, àti ààlà ibùgbé wọn;

  21. Lọ́gán, ni ìṣẹ́jú kan, nígbà ìpè ìkẹyìn: nítorí ìpè yóò dún, a ó sì jí àwọn òkú dìde ní àìdíbàjẹ́, a ó sì pa wá láradà.

  22. Nítorí o wí pé, “Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mi, èmi tí gbọ́ ohùn rẹ, àti ọjọ́ ìgbàlà, èmi sì ti ràn ọ́ lọ́wọ́.” Èmi wí fún ọ, nísinsin yìí ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, nísinsin yìí ni ọjọ́ ìgbàlà.

  23. Ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kíkún náà dé, Ọlọ́run rán ọmọ rẹ̀ jáde wá, ẹni tí a bí nínú obìnrin tí a bí lábẹ́ òfin.

  24. èyí tí yóò jẹ jáde ní kíkún àkókò, láti ṣe àkójọpọ̀ àwọn ohun tí ọ̀run àti ti ayé lábẹ́ Kristi.

  25. ẹ máa ra ìgbà padà, nítorí búburú ní àwọn ọjọ́.