Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Resurrection

91 ẹsẹ · 36 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Bí ẹni erùpẹ̀ ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe erùpẹ̀: bí ẹni tí ọ̀run ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe tí ọ̀run.

  2. Bí àwa ti rú àwòrán ẹni erùpẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwa ó sì rú àwòrán ẹni ti ọ̀run.

  3. Kíyèsi í, ohun ìjìnlẹ̀ ni mo sọ fún un yín, gbogbo wá kì yóò sùn, ṣùgbọ́n gbogbo wá ní a ó paláradà.

  4. Nítorí àwa mọ̀ pé, bi ilé àgọ́ wa ti ayé ba wó, àwa ní ilé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́, ti ayérayé nínú àwọn ọ̀run.

  5. nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀ kí èmi lè ní àjíǹde kúrò nínú òkú.

  6. Ẹni tí yóò sọ ara ìrẹ̀lẹ̀ wa di ọ̀tún kí ó lè bá ara ògo rẹ̀ mu, nípa agbára tí ó mú kí ó ṣe é ṣe fún un láti tẹ orí ohun gbogbo bá fún ara rẹ̀.

  7. Nígbà tí Kristi, ẹni tí í ṣe ìyè yín yóò farahàn, nígbà náà ni ẹ̀yin pẹ̀lú yóò farahàn pẹ̀lú rẹ̀ nínú ògo.

  8. Nítorí pé, Olúwa fúnra rẹ̀ yóò sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, pẹ̀lú ariwo àṣẹ ńlá àti ohùn àwọn angẹli ti àwọn angẹli ti àwọn ti ìpè Ọlọ́run, àwọn òkú nínú Kristi yóò sì kọ́kọ́ jíǹde.

  9. Nígbà náà ni a ó gba àwa tí ó sì wà láààyè sókè nínú àwọsánmọ̀ láti ọwọ́ Olúwa. A ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀ títí láéláé.

  10. àwọn ẹni tí ó ti ṣìnà kúrò nínú òtítọ́, tí ń wí pé àjíǹde ti kọjá ná; tí wọ́n sì ń bi ìgbàgbọ́ àwọn mìíràn ṣubú.

  11. Nítorí náà, ó yẹ kí á fi àwọn ẹ̀kọ́ ìgbà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Kristi sílẹ̀, kí á tẹ̀síwájú nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí yóò mú wa dàgbàsókè ní pípé. Láìtún ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ máa tẹnumọ́ ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ bí i ìrònúpìwàdà kúrò nínú òkú iṣẹ́ àti ìgbàgbọ́ nípa ti Ọlọ́run,

  12. ti ẹ̀kọ́ àwọn bamitiisi, àti ti ìgbọ́wọ́-léni, ti àjíǹde òkú, àti tí ìdájọ́ àìnípẹ̀kun.

  13. Àwọn obìnrin ri òkú wọn gbà nípa àjíǹde: a sì da àwọn ẹlòmíràn lóró, wọ́n kọ̀ láti gba ìdásílẹ̀; kí wọn ba lè rí àjíǹde tí o dára jù gbà.

  14. Olùfẹ́, ọmọ Ọlọ́run ni àwa ń ṣe nísinsin yìí, a kò ì tí i fihàn bí àwa ó ti rí: àwa mọ̀ pé, nígbà tí òun ba farahàn, àwa yóò dàbí rẹ̀; nítorí àwa yóò rí i, àní bí òun tí rí.

  15. Ẹni ìbùkún àti mímọ́ ni ẹni tí ó ní ipa nínú àjíǹde èkínní náà. Lórí àwọn wọ̀nyí ikú ẹ̀ẹ̀kejì kò ní agbára, ṣùgbọ́n wọn ó jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kristi, wọn ó sì máa jẹ ọba pẹ̀lú rẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún.

  16. Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́; àti òkú àti ipò òkú sì jọ̀wọ́ òkú tí ó wà nínú wọn pẹ̀lú: a sì ṣe ìdájọ́ wọn, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.