Skip to content

Martha

12 ẹsẹ · 3 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Martha

  1. Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, o wọ ìletò kan, obìnrin kan tí a ń pè ní Marta sì gbà á sí ilé rẹ̀.

  2. Ṣùgbọ́n Marta ń ṣe ìyọnu ohun púpọ̀, ó sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Olúwa, ìwọ kò sì bìkítà sí ti arábìnrin mi pé ó fi mí sílẹ̀ láti máa nìkan ṣe ìránṣẹ́? Wí fún un kí ó ràn mí lọ́wọ́.”

  3. Ṣùgbọ́n Olúwa sì dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Marta, Marta, ìwọ ń ṣe àníyàn àti làálàá nítorí ohun púpọ̀.

  4. Ara ọkùnrin kan kò sì dá, Lasaru, ará Betani, tí í ṣe ìlú Maria àti Marta arábìnrin rẹ̀.

  5. Jesu sì fẹ́ràn Marta, àti arábìnrin rẹ̀ àti Lasaru.

  6. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù sì wá sọ́dọ̀ Marta àti Maria láti tù wọ́n nínú nítorí ti arákùnrin wọn.

  7. Nítorí náà, nígbà tí Marta gbọ́ pé Jesu ń bọ̀ wá, ó jáde lọ pàdé rẹ̀, ṣùgbọ́n Maria jókòó nínú ilé.

  8. Nígbà náà, ni Marta wí fún Jesu pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú.

  9. Marta wí fún un pé, “Mo mọ̀ pé yóò jíǹde ní àjíǹde ìkẹyìn.”

  10. Jesu kò tí ì wọ ìlú, ṣùgbọ́n ó wà ní ibi kan náà tí Marta ti pàdé rẹ̀.

  11. Jesu wí pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò!” Marta, arábìnrin ẹni tí ó kú náà wí fún un pé, “Olúwa, ó ti ń rùn nísinsin yìí, nítorí pé ó di ọjọ́ kẹrin tí ó tí kú.”

  12. Wọ́n sì ṣe àsè alẹ́ fún un níbẹ̀. Marta sì ń ṣe ìránṣẹ́, ṣùgbọ́n Lasaru jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó jókòó níbi tábìlì rẹ̀.