- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Lazarus
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Ara ọkùnrin kan kò sì dá, Lasaru, ará Betani, tí í ṣe ìlú Maria àti Marta arábìnrin rẹ̀.
Maria náà ni ẹni tí ó fi òróró ìkunra kun Olúwa, tí ó sì fi irun orí rẹ̀ nù ún, arákùnrin rẹ̀ ni Lasaru í ṣe, ara ẹni tí kò dá.
Nítorí náà, àwọn arábìnrin rẹ̀ ránṣẹ́ sí i, wí pé, “Olúwa, wò ó, ara ẹni tí ìwọ fẹ́ràn kò dá.”
Nígbà tí Jesu sì gbọ́, ó wí pé, “Àìsàn yìí kì í ṣe sí ikú, ṣùgbọ́n fún ògo Ọlọ́run, kí a lè yin Ọmọ Ọlọ́run lógo nípasẹ̀ rẹ̀.”
Jesu sì fẹ́ràn Marta, àti arábìnrin rẹ̀ àti Lasaru.
Nítorí náà, nígbà tí ó ti gbọ́ pé, ara rẹ̀ kò dá, ó gbé ọjọ́ méjì sí i níbìkan náà tí ó gbé wà.
Ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí a tún padà lọ sí Judea.”
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wí fún un pé, “Rabbi, ní àìpẹ́ yìí ni àwọn Júù ń wá ọ̀nà láti sọ ọ́ ní òkúta; ìwọ sì tún padà lọ síbẹ̀?”
Jesu dáhùn pé, “Wákàtí méjìlá kọ́ ni ó bẹ nínú ọ̀sán kan bí? Bí ẹnìkan bá rìn ní ọ̀sán, kì yóò kọsẹ̀, nítorí tí ó rí ìmọ́lẹ̀ ayé yìí.
Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá rìn ní òru, yóò kọsẹ̀, nítorí tí kò sí ìmọ́lẹ̀ nínú rẹ̀.”
Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ, lẹ́yìn èyí nì ó sì wí fún wọn pé, “Lasaru ọ̀rẹ́ wa sùn; ṣùgbọ́n èmi ń lọ kí èmi kí ó lè jí i dìde nínú orun rẹ̀.”
Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olúwa, bí ó bá ṣe pé ó sùn, yóò sàn.”
Ṣùgbọ́n Jesu ń sọ ti ikú rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n rò pé, ó ń sọ ti orun sísùn.
Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn gbangba pé, “Lasaru ti kú.
Nígbà náà ni Jesu tún kérora nínú ara rẹ̀, ó wá sí ibojì, ó sì jẹ́ ihò, a sì gbé òkúta lé ẹnu rẹ̀.
Jesu wí pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò!” Marta, arábìnrin ẹni tí ó kú náà wí fún un pé, “Olúwa, ó ti ń rùn nísinsin yìí, nítorí pé ó di ọjọ́ kẹrin tí ó tí kú.”
Jesu wí fún un pé, “Èmi kò ti wí fún ọ pé, bí ìwọ bá gbàgbọ́, ìwọ yóò rí ògo Ọlọ́run?”
Nígbà náà ni wọ́n gbé òkúta náà kúrò (níbi tí a tẹ́ ẹ sí). Jesu sì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì wí pé, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí tí ìwọ gbọ́ tèmi.
Èmi sì ti mọ̀ pé, ìwọ a máa gbọ́ ti èmi nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n nítorí ìjọ ènìyàn tí ó dúró yìí ni mo ṣe wí i, kí wọn ba à lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi.”
Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó kígbe lóhùn rara pé, “Lasaru, jáde wá.”
Ẹni tí ó kú náà sì jáde wá, tí a fi aṣọ òkú dì tọwọ́ tẹsẹ̀ a sì fi gèlè dì í lójú. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ!”
Nítorí náà, nígbà tí àjọ ìrékọjá ku ọjọ́ mẹ́fà, Jesu wá sí Betani, níbi tí Lasaru wà, ẹni tí ó ti kú, tí Jesu jí dìde kúrò nínú òkú.
Wọ́n sì ṣe àsè alẹ́ fún un níbẹ̀. Marta sì ń ṣe ìránṣẹ́, ṣùgbọ́n Lasaru jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó jókòó níbi tábìlì rẹ̀.
Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà gbìmọ̀ kí wọn lè pa Lasaru pẹ̀lú,
nítorí pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù jáde lọ, wọ́n sì gbà Jesu gbọ́.