Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Lazarus: Resurrection of
Àwọn ẹsẹ nípa Resurrection of
Nígbà náà ni Jesu tún kérora nínú ara rẹ̀, ó wá sí ibojì, ó sì jẹ́ ihò, a sì gbé òkúta lé ẹnu rẹ̀.
Jesu wí pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò!” Marta, arábìnrin ẹni tí ó kú náà wí fún un pé, “Olúwa, ó ti ń rùn nísinsin yìí, nítorí pé ó di ọjọ́ kẹrin tí ó tí kú.”
Jesu wí fún un pé, “Èmi kò ti wí fún ọ pé, bí ìwọ bá gbàgbọ́, ìwọ yóò rí ògo Ọlọ́run?”
Nígbà náà ni wọ́n gbé òkúta náà kúrò (níbi tí a tẹ́ ẹ sí). Jesu sì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì wí pé, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí tí ìwọ gbọ́ tèmi.
Èmi sì ti mọ̀ pé, ìwọ a máa gbọ́ ti èmi nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n nítorí ìjọ ènìyàn tí ó dúró yìí ni mo ṣe wí i, kí wọn ba à lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi.”
Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó kígbe lóhùn rara pé, “Lasaru, jáde wá.”
Ẹni tí ó kú náà sì jáde wá, tí a fi aṣọ òkú dì tọwọ́ tẹsẹ̀ a sì fi gèlè dì í lójú. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ!”
Nítorí náà, ìjọ ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí o pé Lasaru jáde nínú ibojì rẹ̀, tí ó sì jí i dìde kúrò nínú òkú, jẹ́rìí sí i.
Nítorí èyí ni ìjọ ènìyàn sì ṣe lọ pàdé rẹ̀, nítorí tí wọ́n gbọ́ pé ó ti ṣe iṣẹ́ àmì yìí.