Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Resurrection: Persecution

6 ẹsẹ · 36 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Persecution

  1. Ṣùgbọ́n nígbà tí Paulu ṣàkíyèsí pé, apá kan wọn jẹ́ Sadusi, apá kan sì jẹ́ Farisi, ó kígbe ní ìgbìmọ̀ pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi jẹ́ Farisi, ọmọ Farisi sì ni èmi. Mo dúró ní ìdájọ́ nítorí ìrètí mi nínú àjíǹde òkú.”

  2. Ìwọ pẹ̀lú sì ní òye rẹ̀ pé, ìjejìlá ni mo lọ sí Jerusalẹmu láti lọ jọ́sìn.

  3. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn olùfisùn mi kò rí mi kí ń máa bá ẹnikẹ́ni jiyàn nínú tẹmpili, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ru àwọn ènìyàn sókè nínú Sinagọgu tàbí ní ibikíbi nínú ìlú.

  4. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò lè fi ìdí ẹ̀sùn múlẹ̀ níwájú rẹ, èyí tí wọn fi mí sùn sí nísinsin yìí.

  5. Ṣùgbọ́n, èmí jẹ́wọ́ fún ọ pé, èmi ń sin Ọlọ́run àwọn baba wa gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń tẹ̀lé ọ̀nà tí wọ́n ń pè ni ìyapa ìsìn. Èmi ń gbá gbogbo nǹkan ti a kọ sínú ìwé òfin gbọ́, àti tí a kọ sínú ìwé àwọn wòlíì,

  6. mo sí ní ìrètí kan náà nínú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí àwọn tìkára wọn jẹ́wọ́ pẹ̀lú, wí pé àjíǹde òkú ń bọ̀, àti tí olóòtítọ́, àti tí aláìṣòótọ́.