Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Heathen

35 ẹsẹ · 37 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. kí ọ̀nà rẹ le di mí mọ̀ ní ayé, ìgbàlà rẹ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

  2. Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run; kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́!

  3. Kí orílẹ̀-èdè kí ó yọ̀, kí ó sì kọrin fún ayọ̀, nítorí ìwọ fi òdodo darí àwọn ènìyàn, ìwọ sì jẹ ọba àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé.

  4. Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run; kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́. Sela.

  5. Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa, nítorí tí ó ṣe ohun ìyanu; ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti apá mímọ́ rẹ̀ o ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún un

  6. Olúwa ti sọ ìgbàlà rẹ̀ di mí mọ̀ o fi òdodo rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè.

  7. Ó rántí ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ fún àwọn ará ilé Israẹli; gbogbo òpin ayé ni ó ti rí iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run wa.

  8. Ní ìgbẹ̀yìn ọjọ́ òkè tẹmpili Olúwa ni a ó fi ìdí rẹ̀ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olú nínú àwọn òkè, a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ, gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì máa sàn sínú un rẹ̀.

  9. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò wá, wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá Olúwa, àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu. Òun yóò kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.” Òfin yóò jáde láti Sioni wá, àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerusalẹmu.

  10. Òun ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì parí aáwọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn. Wọn yóò fi idà wọn rọ ọkọ́ ìtulẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé. Orílẹ̀-èdè kì yóò sì gbé idà sí orílẹ̀-èdè mọ́, bẹ́ẹ̀ ní wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.

  11. “Dìde, tànmọ́lẹ̀, nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé, ògo Olúwa sì ràdàbò ọ́.

  12. Kíyèsi i, òkùnkùn bo ilẹ̀ ayé òkùnkùn biribiri sì wà lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n Olúwa ràn bò ọ́ ògo rẹ̀ sì farahàn lórí i rẹ.

  13. Àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá sí ìmọ́lẹ̀ rẹ, àti àwọn ọba sí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ rẹ.

  14. “Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wò. Gbogbo wọn ṣa ara jọ pọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ; àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin yóò wá láti ọ̀nà jíjìn, àwọn ọmọ rẹ obìnrin ni a ó tọ́jú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ.

  15. Nígbà náà ni ìwọ yóò wò tí ojú rẹ yóò máa dán, ọkàn rẹ yó fò, yó sì kún fún ayọ̀; ọrọ̀ inú Òkun ni a ó kò wá sọ́dọ̀ rẹ, sí ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá.

  16. Ọ̀wọ́ ìbákasẹ yóò bo gbogbo ilẹ̀ rẹ, àwọn ọ̀dọ́ ìbákasẹ Midiani àti Efani. Àti gbogbo wọn láti Ṣeba yóò wá, wọn yóò mú wúrà àti tùràrí lọ́wọ́ tí wọn yóò sì máa kéde ìyìn Olúwa.

  17. Gbogbo agbo ẹran ìlú Kedari ni a ó kójọ sọ́dọ̀ rẹ, àwọn àgbò ti Nebaioti yóò sìn ọ́; wọn yóò jẹ́ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi, bẹ́ẹ̀ ni n ó sì ṣe tẹmpili ògo mi lọ́ṣọ̀ọ́.

  18. “Ta ni àwọn wọ̀nyí tí ń fò lọ bí i kurukuru, gẹ́gẹ́ bí àwọn àdàbà sí ìtẹ́ wọn?

  19. Ẹ wá kánkán, gbogbo ẹ̀yin kèfèrí láti gbogbo àyíká, kí ẹ sì gbá ara yín jọ yí káàkiri. Níbẹ̀ ní kí o mú àwọn alágbára rẹ sọ̀kalẹ̀, Olúwa.

  20. “Ẹ jí, ẹ sì gòkè wá sí àfonífojì Jehoṣafati ẹ̀yin kèfèrí: nítorí níbẹ̀ ní èmi yóò jókòó láti ṣe ìdájọ́ àwọn kèfèrí yí káàkiri.

  21. Ẹ tẹ dòjé bọ̀ ọ́, nítorí ìkórè pọ́n. Ẹ wá, ẹ sọ̀kalẹ̀, nítorí ìfúntí kún, nítorí àwọn ọpọ́n kún àkúnwọ́sílẹ̀, nítorí ìwà búburú wọn pọ̀!”

  22. “Ẹ wo inú àwọn kèfèrí, ki ẹ sí wòye, kí háà kí ó sì ṣe yin gidigidi. Nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́, bí a tilẹ̀ sọ fún yin.

  23. Nítorí pé, èmi yóò gbé àwọn ara Babeli dìde, àwọn aláìláàánú àti onínú-fùfù ènìyàn tí ó rin gbogbo ilẹ̀ ayé já láti fi agbára gbà àwọn ibùgbé tí kì í ṣe tiwọn.

  24. Wọn jẹ́ ènìyàn ti a bẹ̀rù, tí a sì páyà, ìdájọ́ wọn, àti ọláńlá wọn, yóò máa ti inú wọn jáde.

  25. Ẹṣin wọn yára ju ẹkùn lọ, wọ́n sì gbóná jú ìkookò àṣálẹ́ lọ àwọn ẹlẹ́ṣin wọn yóò sí tan ara wọn ká; wọn yóò sì wá láti ọ̀nà jíjìn réré, wọn yóò sí fò bí ẹyẹ igún tí ń wá láti jẹrun,