Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Heathen: Will finally judge

5 ẹsẹ · 37 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Will finally judge

  1. Gbogbo àwọn tí ó ṣẹ̀ ní àìlófin wọn ó sì ṣègbé láìlófin, àti iye àwọn tí ó ṣẹ̀ lábẹ́ òfin, àwọn ni a ó fi òfin dá lẹ́jọ́.

  2. Nítorí kì í ṣe àwọn olùgbọ́ òfin ni ẹni ìdáláre lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn olùṣe òfin ni a ó dá láre.

  3. Nítorí nígbà tí àwọn aláìkọlà, tí kò ní òfin, bá ṣe ohun tí ó wà nínú òfin nípa ìwà ẹ̀dá, àwọn wọ̀nyí, jẹ́ òfin fún ara wọn bí wọn kò tilẹ̀ ní òfin.

  4. Àwọn ẹni tí ó fihàn pé, a kọ̀wé iṣẹ́ òfin sí wọn lọ́kàn, tí ẹ̀rí ọkàn wọn pẹ̀lú sì tún ń jẹ́ wọn lẹ́rìí, àti pé, èrò ọkàn wọn tí ó jẹ́ ọ̀nà ìfinisùn, sì ń gbè wọ́n lẹ́yìn ní ìsinsin yìí.

  5. Èyí yóò farahàn ní ọjọ́ náà nígbà tí Ọlọ́run yóò tipasẹ̀ Jesu Kristi ṣe ìdájọ́ àwọn àṣírí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìyìnrere mi.