Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Soldiers

65 ẹsẹ · 13 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà tí ó sì dé orí àtẹ̀gùn, gbígbé ni a gbé e sókè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ogun nítorí ìwà ipá àwọn ènìyàn.

  2. olórí ogun pàṣẹ pé kí a mú Paulu wá sínú àgọ́ àwọn ológun. Ó sì pàṣẹ kí wọ́n ó lù ú, kí wọn fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò, kí òun ba à lè mọ ìdí tí wọ́n fi ń kígbe lé e lórí bẹ́ẹ̀.

  3. Bí wọ́n sí tí fi ọṣán dè é, Paulu bí balógun ọ̀rún tí ó dúró tì í pé, “Ó ha tọ́ fún yín láti na ẹni tí i ṣe ará Romu ni àìdálẹ́bi bí?”

  4. Nígbà tí balógun ọ̀rún sì gbọ́ èyí, ó lọ wí fún olórí ogun pé, “Kín ni ó fẹ́ ṣe yìí: nítorí ọkùnrin yìí ará Romu ní i ṣe?”

  5. Alábojútó-ogun sì dé, ó sì bí Paulu pé, “Sọ fún mi, ará Romu ni ìwọ jẹ́ bí?” Ó sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.”

  6. Alábojútó-ogun sì dáhùn wí pé, “Owó púpọ̀ ni mo fi ra ọlá ìbílẹ̀ yìí.” Paulu wí pé, “Ṣùgbọ́n a bí mi sínú rẹ̀ ni.”

  7. Ó sì pe méjì nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ múra igba ọmọ-ogun sílẹ̀, láti lọ sí Kesarea, àti àádọ́rin ẹlẹ́ṣin, àti igba ọlọ́kọ̀, ní wákàtí kẹta òru.

  8. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun gbe Paulu, wọ́n sì mú un lóru lọ si Antipatrisi, gẹ́gẹ́ bí a tí pàṣẹ fún wọn.

  9. Ní ọjọ́ kejì wọ́n sì fi àwọn ẹlẹ́ṣin sílẹ̀ láti máa bá a lọ, àwọn sì padà wá sínú àgọ́ àwọn ológun.

  10. Nígbà tí wọ́n dé Kesarea, tí wọ́n sí fi ìwé fún baálẹ̀, wọ́n mú Paulu pẹ̀lú wá síwájú rẹ̀.

  11. Bí a sì ti pinnu rẹ̀ pé kí a wọ ọkọ̀ lọ sí Itali, wọn fi Paulu àti àwọn òǹdè mìíràn lé balógun ọ̀rún kan lọ́wọ́, ti a ń pè ní Juliusi, ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun Augustu.

  12. Paulu wí fún balógun ọ̀rún àti fún àwọn ọmọ-ogun pé, “Bí kò ṣe pé àwọn wọ̀nyí bá dúró nínú ọkọ̀ ẹ̀yin kí yóò lè là!”

  13. Èrò àwọn ọmọ-ogun ni ki a pa àwọn òǹdè, kí ẹnikẹ́ni wọn má ba à wẹ̀ jáde sálọ.

  14. Ṣùgbọ́n balógun ọ̀rún ń fẹ́ gba Paulu là, ó kọ èrò wọn, ó sì pàṣẹ fún àwọn tí ó lè wẹ̀ kí wọn bọ́ sí Òkun lọ sì ilẹ̀.

  15. Nígbà tí a sì dé Romu, olórí àwọn ọmọ-ogun fi àwọn òǹdè lé olórí ẹ̀ṣọ́ lọ́wọ́, ṣùgbọ́n wọ́n gba Paulu láààyè láti máa dágbé fún ara rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ-ogun tí ó ń ṣọ́ ọ.