Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Seekers

165 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Àwọn ènìyàn yóò sá à tún wa, àti ẹni tí yóò gbe ìlú ńlá púpọ̀.

  2. Àwọn ẹni tí ń gbé ìlú ńlá kan yóò lọ sí òmíràn, wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a yára lọ gbàdúrà kí a sì wá ojúrere Olúwa, àti láti wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Èmi pẹ̀lú yóò sì lọ.’

  3. Nítòótọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti àwọn alágbára orílẹ̀-èdè yóò wá láti wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní Jerusalẹmu; àti láti gbàdúrà, àti láti wá ojúrere Olúwa.”

  4. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ni ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àti orílẹ̀-èdè yóò dìímú, àní yóò di etí aṣọ ẹni tí i ṣe Júù mú, wí pé, ‘Àwa yóò ba ọ lọ, nítorí àwa tí gbọ́ pé, Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.’ ”

  5. Alábùkún fún ni àwọn tí ebi ń pa tí òǹgbẹ ń gbẹ́ nítorí òdodo, nítorí wọn yóò yó.

  6. Ṣùgbọ́n, ẹ kọ́kọ́ wá ìjọba Ọlọ́run ná àti òdodo rẹ̀, yóò sì fi gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí kún un fún yín pẹ̀lú.

  7. “Béèrè, a ó sì fi fún yín; wá kiri, ẹ̀yin yóò sì rí; kànkùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín.

  8. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó béèrè ń rí gbà, ẹni tí ó bá sì wà kiri ń rí, ẹni bá sì kànkùn ni a yóò ṣi sílẹ̀ fún.

  9. “Ta ni ọkùnrin náà tí ń bẹ nínú yín, bí ọmọ rẹ̀ béèrè àkàrà, tí yóò jẹ́ fi òkúta fún un?

  10. Tàbí bí ó béèrè ẹja, tí yóò jẹ́ fún un ní ejò?

  11. Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí í ṣe ènìyàn búburú bá mọ̀ bí a ti í fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòó mélòó ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ohun rere fún àwọn tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?

  12. Nítorí náà, nínú gbogbo ohunkóhun ti ẹ̀yin bá ń fẹ́ kí ènìyàn kí ó ṣe sí yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó ṣe sí wọn gẹ́gẹ́; nítorí èyí ni òfin àti àwọn wòlíì.

  13. Alábùkún fún ni ẹ̀yin tí ebi ń pa nísinsin yìí; nítorí tí ẹ ó yóò. Alábùkún fún ni ẹ̀yin tí ń sọkún nísinsin yìí: nítorí tí ẹ̀yin ó rẹ́rìn-ín.

  14. “Èmí sì wí fún yín, ẹ béèrè, a ó sì fi fún un yín; ẹ wá kiri, ẹ̀yin ó sì rí; ẹ kànkùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín.

  15. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá béèrè, ó rí gbà; ẹni tí ó sì ń wá kiri, ó rí; àti ẹni tí ó kànkùn ni a ó ṣí i sílẹ̀ fún.

  16. “Ta ni baba nínú yín tí ọmọ rẹ̀ yóò béèrè àkàrà lọ́dọ̀ rẹ̀, tí yóò fún un ní òkúta? Tàbí bí ó béèrè ẹja, tí yóò fún un ní ejò?

  17. Tàbí bí ó sì béèrè ẹ̀yin, tí yóò fún un ní àkéekèe?

  18. Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí ó jẹ́ ènìyàn búburú bá mọ bí a ti í fi ẹ̀bùn dáradára fún àwọn ọmọ yín, mélòó mélòó ha ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ fún àwọn tí ó béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀!”

  19. “Ẹ làkàkà láti gba ojú ọ̀nà tóóró wọlé, nítorí mo wí fún yín, ènìyàn púpọ̀ ni yóò wá ọ̀nà láti wọ̀ ọ́, wọn kì yóò sì lè wọlé.

  20. “Bí ẹnìkan bá tọ̀ mí wá, tí kò sì kórìíra baba àti ìyá, àti aya, àti ọmọ, àti arákùnrin, àti arábìnrin, àní àti ọkàn ara rẹ̀ pẹ̀lú, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.

  21. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ru àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.

  22. “Nítorí ta ni nínú yín tí ń pète láti kọ́ ilé ìṣọ́, tí kì yóò kọ́kọ́ jókòó kí ó ṣírò iye owó rẹ̀, bí òun ní tó tí yóò fi parí rẹ̀.

  23. Kí ó má ba à jẹ́ pé nígbà tí ó bá fi ìpìlẹ̀ ilé sọlẹ̀ tan, tí kò lè parí rẹ̀ mọ́, gbogbo àwọn tí ó rí i a bẹ̀rẹ̀ sí í fi í ṣe ẹlẹ́yà.

  24. Wí pé, ‘Ọkùnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé, kò sì lè parí rẹ̀.’

  25. “Tàbí ọba wo ni ó ń lọ bá ọba mìíràn jà, tí kì yóò kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbèrò bí yóò lè fi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) pàdé ẹni tí ń mú ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) bọ̀ wá ko òun lójú?