Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Riches: Examples of those truly rich

10 ẹsẹ · 107 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Examples of those truly rich

  1. Alábùkún fún ni àwọn ọlọ́kàn mímọ́, nítorí wọn yóò rí Ọlọ́run.

  2. Nígbà tí Jesu gbọ́ èyí ẹnu yà á, ó sì wí fún àwọn tí ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi kò rí ẹnìkan ni Israẹli tó ní ìgbàgbọ́ ńlá bí irú èyí.

  3. “Bákan náà ni ìjọba ọ̀run dàbí oníṣòwò kan tí ó ń wá òkúta olówó iyebíye láti rà.

  4. Nígbà tí ó rí ọ̀kan tí ó ni iye lórí, ó lọ láti ta gbogbo ohun ìní rẹ̀ láti le rà á.

  5. Ṣùgbọ́n ohun kan ni a kò lè ṣe aláìní, Maria sì ti yan ipa rere náà tí a kò lè gbà lọ́wọ́ rẹ̀.”

  6. Filipi rí Natanaeli, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni náà tí Mose kọ nípa rẹ̀ nínú òfin àti ẹni tí àwọn wòlíì ti kọ̀wé rẹ̀, Jesu ti Nasareti, ọmọ Josẹfu.”

  7. Nítòótọ́ láìṣe àní àní mo sì ka ohun gbogbo sí òfo nítorí ìtayọ ìmọ̀ Kristi Jesu Olúwa mi; nítorí ẹni ti mo ti ṣòfò ohun gbogbo, mo si kà wọn sí ohun tí kò ní èrè, kí èmi lè jèrè Kristi,

  8. Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́: Ọlọ́run kò ha ti yan àwọn tálákà ayé yìí láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́, àti ajogún ìjọba náà, tí ó ti ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ?

  9. Báyìí fún ẹ̀yin ti ẹ gbà á gbọ́, ó ṣe iyebíye; ṣùgbọ́n fún àwọn tí kò gbà á gbọ́, “Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, òun ni ó di pàtàkì igun ilé,”

  10. Èmi fún ọ ni ìmọ̀ràn pé kí o ra wúrà lọ́wọ́ mi tí a ti dà nínú iná, kí ìwọ lè di ọlọ́rọ̀; àti aṣọ funfun, kí ìwọ lè fi wọ ara rẹ̀, àti kí ìtìjú ìhòhò rẹ̀ má ba hàn kí ìwọ sì fi ohun ìkunra kun ojú rẹ̀, kí ìwọ lè ríran.