Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Riches

225 ẹsẹ · 107 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Abramu sì ti di ọlọ́rọ̀ gidigidi; ní ẹran ọ̀sìn, ó ní fàdákà àti wúrà.

  2. Àti Lọti pẹ̀lú, tí ó ń bá Abramu rìn kiri, ní agbo ẹran, ọ̀wọ́ ẹran àti àgọ́.

  3. Ṣùgbọ́n ilẹ̀ náà kò le gbà wọ́n tí wọ́n bá ń gbé pọ̀, nítorí, ohun ìní wọn pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, dé bi wí pé wọn kò le è gbé pọ̀.

  4. Ọkùnrin náà sì di ọlọ́rọ̀ púpọ̀, ọrọ̀ rẹ̀ sì ń pọ̀ si, títí ó fi di ènìyàn ńlá.

  5. Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran ọ̀sìn àti agbo ẹran àti àwọn ìránṣẹ́ tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn Filistini ń ṣe ìlara rẹ̀.

  6. Ìwọ̀nba díẹ̀ sá à ni o ní kí èmi tó dé, ó sì ti pọ̀ sí i gidigidi, Olúwa sì ti bùkún ọ nínú gbogbo èyí tí mo ṣe. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nígbà wo ní èmi yóò pèsè fún ìdílé tèmi.”

  7. Mo ní màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn àti ewúrẹ́. Mo tún ni àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin. Mo ń ránṣẹ́ yìí sí olúwa mi kí èmi le è rí ojúrere rẹ.’ ”

  8. èmi kò tilẹ̀ yẹ fún àánú àti òtítọ́ tí o ń fihàn fún ìránṣẹ́ rẹ. Nítorí pé, kìkì ọ̀pá mi ni mo mu kúrò ni ilé kọjá Jordani yìí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, èmi ti di ẹgbẹ́ méjì.

  9. Ohun ìní wọn pọ̀ ju èyí tí àwọn méjèèjì lè máa gbé ní ojú kan lọ. Ilẹ̀ tí wọ́n wà kò le gba àwọn méjèèjì nítorí àwọn ohun ọ̀sìn wọn.

  10. “Nítorí náà, kì í ṣe ẹ̀yin ni ó rán mi wá sí ibí yìí, bí kò ṣe Ọlọ́run. Ó fi mí ṣe baba, Olùdámọ̀ràn fún Farao, olúwa fún gbogbo ilé Farao àti alákòóso gbogbo ilẹ̀ Ejibiti.

  11. Ẹ sọ fún baba mi nípa gbogbo ọlá tí a fún mi ní ilẹ̀ Ejibiti àti ohun gbogbo tí ẹ̀yin ti rí, kí ẹ sì mú baba mi tọ̀ mí wá sí ìhín yìí kíákíá.”

  12. Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá mú yín dé ilẹ̀ náà tí ó ti búra fún àwọn baba yín, fún Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu láti fi fún un yín, ilẹ̀ tí ó kún fún àwọn ìlú ńlá ńlá tí kì í ṣe ẹ̀yin ló kọ́ ọ,

  13. àwọn ilé tí ó kún fún gbogbo ohun mèremère tí kì í ṣe ẹ̀yin ló rà wọ́n, àwọn kànga tí ẹ kò gbẹ́, àti àwọn ọgbà àjàrà àti èso olifi tí kì í ṣe ẹ̀yin ló gbìn wọ́n. Nígbà tí ẹ bá jẹ tí ẹ sì yó,

  14. ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe gbàgbé Olúwa, tí o mú un yín jáde láti Ejibiti wá, kúrò ní oko ẹrú.

  15. Nígbà tí ẹ bá ti jẹ tí ẹ sì yó tán ẹ yin Olúwa Ọlọ́run yín fún pípèsè ilẹ̀ rere fún un yín.

  16. Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, nípa kíkùnà láti pa àṣẹ rẹ̀, àwọn òfin rẹ̀, àti àwọn ìlànà rẹ̀ tí mo ń fún un yín lónìí mọ́.

  17. Kí ó má ba à jẹ́ pé, nígbà tí ẹ bá jẹun yó tán, tí ẹ bá kọ́ ilé tí ó dára tán, tí ẹ sí ń gbé inú rẹ̀,

  18. nígbà tí àwọn agbo màlúù yín àti tí ewúrẹ́ ẹ yín bá pọ̀ sí i tán, tí fàdákà àti wúrà yín sì ń peléke sí i, tí ohun gbogbo tí ẹ ní sì ń pọ̀ sí i,

  19. nígbà náà ni ọkàn yín yóò gbéga, tí ẹ̀yin yóò sì gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti wá, nínú oko ẹrú.

  20. Òun ni ó mú un yín la aginjù ẹlẹ́rù ńlá já, ilẹ̀ tí kò sí omi tí ó sì kún fún òǹgbẹ, pẹ̀lú àwọn ejò olóró ńlá ńlá àti àkéekèe. Ó mú omi jáde fún un yín láti inú àpáta.

  21. Ó fún yín ní manna láti jẹ nínú aginjù, ohun tí àwọn baba yín kò mọ̀ rí, kí Òun bá à le tẹ orí yín ba kí ó sì lè dán an yín wò, kí ó bá à lè dára fún un yín.

  22. Ẹ lè rò nínú ara yín pé, “Agbára mi àti iṣẹ́ ọwọ́ mi ni ó mú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá fún mi.”

  23. Ṣùgbọ́n ẹ rántí Olúwa Ọlọ́run yín tí ó fún un yín ní agbára àti lè ní àwọn ọrọ̀ wọ̀nyí, tí ó sì fi mú májẹ̀mú rẹ̀ ṣẹ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá a yín bí ó ti rí lónìí.

  24. Nígbà tí mo ti mú wọn wá sí ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti fún oyin, ilẹ̀ tí mo ti ṣe ìlérí ní ìbúra fún àwọn baba ńlá wọn, àti nígbà tí wọ́n bá jẹ, tí ó sì tẹ́ wọn lọ́rùn, tí wọ́n sì gbilẹ̀, wọn yóò yí padà sí ọlọ́run mìíràn wọn yóò sì sìn wọ́n, wọn yóò kọ̀ mí sílẹ̀, wọn yóò sì da májẹ̀mú mi.

  25. Jeṣuruni sanra tán ó sì tàpá; ìwọ sanra tán, ìwọ ki tan, ọ̀rá sì bò ọ́ tán. O kọ Ọlọ́run tí ó dá ọ o sì kọ àpáta ìgbàlà rẹ.