Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Regeneration

256 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n títí di àsìkò yìí Olúwa kò fi ọkàn ìmòye tàbí ojú tí ó ń rí tàbí etí tí ó n gbọ́ fún ọ.

  2. Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò kọ ọkàn rẹ ní ilà àti ọkàn àwọn ọmọ yín, nítorí kí o lè fẹ́ ẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, àti ayé rẹ.

  3. Kí ó fa ọkàn wa sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀, láti máa rìn nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, àti àṣẹ rẹ̀, àti ìlànà rẹ̀, tí ó ti pàṣẹ fún àwọn baba wa.

  4. Nítorí pé pẹ̀lú rẹ ni orísun ìyè wà: nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀.

  5. Wẹ gbogbo àìṣedéédéé mi nù kúrò kí o sì wẹ̀ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi!

  6. Wẹ̀ mí pẹ̀lú ewé hísópù, èmi yóò sì mọ́; fọ̀ mí, èmi yóò sì funfun ju yìnyín lọ.

  7. Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run, kí o sì tún ẹ̀mí dídúró ṣinṣin ṣe sínú mi.

  8. Ọ̀ràn àìṣedéédéé borí mi bí ó ṣe ti ìrékọjá wa ni! Ìwọ ni yóò wẹ̀ wọ́n nù kúrò.

  9. Ìwọ ti gòkè sí ibi gíga ìwọ ti di ìgbèkùn ní ìgbèkùn lọ; ìwọ ti gba ẹ̀bùn fún ènìyàn: nítòótọ́, fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ pẹ̀lú, kí Olúwa Ọlọ́run lè máa bá wọn gbé.

  10. “Èmi ó dárúkọ Rahabu àti Babeli láàrín àwọn tí ó jẹ́wọ́ mi: Filistia pẹ̀lú, àti Tire, pẹ̀lú Kuṣi, yóò sọ pé, ‘Èyí ni a bí ní Sioni.’ ”

  11. Olúwa yóò kọ nínú àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀: “Eléyìí ni a bí ní Sioni.”

  12. Àwọn ènìyàn rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtinúwá ní ọjọ́ ìjáde ogun rẹ, nínú ẹwà mímọ́, láti inú òwúrọ̀ wá ìwọ ni ìrì ẹwà rẹ.

  13. Ju gbogbo nǹkan tókù lọ, pa ọkàn rẹ mọ́, nítorí òun ni orísun ìyè.

  14. Ní ọ̀nà àwọn olódodo ni ìyè wà ní ọ̀nà náà ni àìkú wà.

  15. Ìbẹ̀rù Olúwa jẹ́ orísun ìyè, tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú.

  16. Ti ènìyàn ni ìgbèrò inú ọkàn ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìdáhùn ahọ́n ti ń wá.

  17. “Wẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí ara yín mọ́. Ẹ mú ìwà ibi yín kúrò níwájú mi! Dáwọ́ àìṣedéédéé dúró,

  18. kọ́ láti ṣe rere! Wá ìdájọ́ òtítọ́, tu àwọn tí a ń pọ́n lójú nínú. Ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba, gbà ẹjọ́ opó rò.

  19. Èmi yóò pa ọwọ́ mi dà sí ọ, èmi ó sì ku ìpẹ́pẹ́ rẹ dànù, n ó sì mú gbogbo ìdọ̀tí rẹ kúrò.

  20. Olúwa yóò wẹ ẹ̀gbin àwọn obìnrin Sioni kúrò yóò sì fọ gbogbo àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ kúrò ní Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹ̀mí ìdájọ́ àti ẹ̀mí iná.

  21. Pẹ̀lú ayọ̀ ni ìwọ yóò máa pọn omi láti inú kànga ìgbàlà.

  22. Olúwa, ìwọ fi àlàáfíà lélẹ̀ fún wa; ohun gbogbo tí a ti ṣe yọrí ìwọ ni ó ṣe é fún wa.

  23. Nígbà tí wọ́n bá rí i láàrín àwọn ọmọ wọn, àwọn iṣẹ́ ọwọ́ mi, wọn yóò ya orúkọ mi sí mímọ́, wọn yóò tẹ́wọ́gbà mímọ́ Ẹni Mímọ́ Jakọbu wọn yóò dìde dúró ní ìbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Israẹli.

  24. Nígbà náà ni ojú àwọn tí ó rí kò ní padé mọ́, àti etí àwọn tí ó gbọ́ yóò tẹ́tí sílẹ̀.

  25. Ọkàn àwọn oníwàdùwàdù ni yóò là tí yóò sì yè, àti ahọ́n tí ń kólòlò ni yóò là geerege.