- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Privileges of Saints
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Lẹ́yìn èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Abramu wá lójú ìran pé, “Abramu má ṣe bẹ̀rù. Èmi ni ààbò rẹ, Èmi sì ni èrè ńlá rẹ.”
Nígbà náà ni Abrahamu súnmọ́ ọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì wí pé, “Ìwọ yóò ha pa olódodo ènìyàn àti ènìyàn búburú run papọ̀ bí?”
“Bí ó bá ṣe pé ìwọ rí àádọ́ta olódodo nínú ìlú náà, ìwọ yóò ha run ún, ìwọ kì yóò ha dá ìlú náà sí nítorí àwọn àádọ́ta olódodo tí ó wà nínú rẹ̀ náà?
Kò jẹ́ rí bẹ́ẹ̀! Dájúdájú ìwọ kì yóò ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀, láti pa olódodo pẹ̀lú àwọn ènìyàn rere àti àwọn ènìyàn búburú. Dájúdájú, ìwọ kì yóò ṣe èyí tí ó tọ́ bi?”
Olúwa wí pé, “Bí mo bá rí àádọ́ta olódodo ní ìlú Sodomu, èmi yóò dá ìlú náà sí nítorí tiwọn.”
Abrahamu sì tún tẹ̀síwájú pé, “Wò ó nísinsin yìí, níwọ̀n bí èmi ti ní ìgboyà láti bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ níwájú Olúwa, èmi ẹni tí í ṣe erùpẹ̀ àti eérú,
bí ó bá ṣe pe olódodo márùndínláàádọ́ta ni ó wà nínú ìlú, ìwọ yóò ha pa ìlú náà run nítorí ènìyàn márùn-ún bí?” Olúwa dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo márùndínláàádọ́ta nínú rẹ̀.”
Òun sì tún wí lẹ́ẹ̀kan si pé, “Bí ó bá ṣe pé ogójì ni ń kọ́?” Olúwa sì tún wí pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo ogójì nínú rẹ̀.”
Abrahamu sì tún bẹ Olúwa pé, “Kí Olúwa má ṣe bínú, ṣùgbọ́n èmi yóò sọ̀rọ̀. Bí ó bá ṣe pé ọgbọ̀n ni a rí níbẹ̀ ń kọ́?” Olúwa dáhùn pé, “Bí mó bá rí ọgbọ̀n, èmi kì yóò pa ìlú run.”
Abrahamu wí pé, “Níwọ́n bí mo ti ní ìgboyà láti bá Olúwa sọ̀rọ̀ báyìí, jẹ́ kí n tẹ̀síwájú. Bí o bá ṣe pé olódodo ogún péré ni ó wà nínú ìlú náà ń kọ́?” Olúwa sì dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa á run nítorí ogún ènìyàn náà.”
Abrahamu sì wí pé, “Jọ̀wọ́ má ṣe bínú Olúwa. Jẹ́ kí ń béèrè lẹ́ẹ̀kan si. Bí ó bá ṣe pé ènìyàn mẹ́wàá ni ó jẹ́ olódodo ń kọ́?” Olúwa wí pé, “Nítorí ènìyàn mẹ́wàá náà, èmi kì yóò pa á run.”
Olúwa sì bá tirẹ̀ lọ, nígbà tí ó bá Abrahamu sọ̀rọ̀ tán, Abrahamu sì padà sílé.
Ṣé báyìí ni ẹ̀yin yóò ṣe san an fún Olúwa, ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìgbọ́n ènìyàn? Ǹjẹ́ òun kọ́ ni baba yín, Ẹlẹ́dàá yín, tí ó dá a yín tí ó sì mọ yín?
Ó sì wí pé, “Olúwa ni àpáta mi, àti Olùgbàlà mi;
Ọlọ́run mi, àpáta mi, nínú ẹni tí èmi ní ààbò, àti ìwo ìgbàlà mi, ibi ìsádi gíga mi. Àti ibi ìlùmọ̀ mi, Olùgbàlà mi; ìwọ ni ó ti gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá.
Ìwọ ha kọ́ Ọlọ́run wa, tí o ti lé àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí jáde níwájú àwọn ènìyàn Israẹli, tí o sì fi fún irú-ọmọ Abrahamu ọ̀rẹ́ rẹ láéláé?
“Ìwọ sọ̀kalẹ̀ wá sí orí òkè Sinai; ìwọ bá wọn sọ̀rọ̀ láti ọ̀run. Ìwọ fún wọn ní ìlànà àti àwọn òfin tí ó jẹ́ òdodo tí ó sì tọ́ àti ìlànà tí ó dára.
Ìwọ mú ọjọ́ ìsinmi rẹ mímọ́ di mí mọ̀ fún wọn, o sì fún wọn ní àwọn ìlànà, àwọn àṣẹ àti àwọn òfin láti ọwọ́ Mose ìránṣẹ́ rẹ.
Nínú ìyanu yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ ikú àti nínú ogun, yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ idà.
Nítorí pé ìwọ ti bá òkúta igbó mulẹ̀, àwọn ẹranko igbó yóò wà pẹ̀lú rẹ ní àlàáfíà.
Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, Olúwa; ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.
Fi etí sílẹ̀ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́, ọba mi àti Ọlọ́run mi, nítorí ìwọ ni mo gba àdúrà sí.
Olúwa ni àpáta àti odi mi, àti olùgbàlà mi; Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ìsádi mi. Òun ni àpáta ààbò àti ìwo ìgbàlà mi àti ibi ìsádi mi.
Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn mi kí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ, Ìwọ Olúwa àpáta mi, àti Olùdáǹdè mi.
Ti Dafidi. Olúwa ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi; ta ni èmi yóò bẹ̀rù? Olúwa ni ibi ìsádi ẹ̀mí mi, ẹ̀rù ta ni yóò bà mí?