Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Privileges of Saints: Secure during public calamities

13 ẹsẹ · 36 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Secure during public calamities

  1. Nínú ìyanu yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ ikú àti nínú ogun, yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ idà.

  2. Nítorí pé ìwọ ti bá òkúta igbó mulẹ̀, àwọn ẹranko igbó yóò wà pẹ̀lú rẹ ní àlàáfíà.

  3. Ti Dafidi. Olúwa ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi; ta ni èmi yóò bẹ̀rù? Olúwa ni ibi ìsádi ẹ̀mí mi, ẹ̀rù ta ni yóò bà mí?

  4. Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí mi láti jẹ ẹran-ara mi, àní àwọn ọ̀tá mi àti àwọn abínúkú mi, wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.

  5. Bí ọmọ-ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi, ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù; bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi, nínú èyí ni ọkàn mi yóò le.

  6. Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, òhun ni èmi yóò máa wá kiri: kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwa ní ọjọ́ ayé mi gbogbo, kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà Olúwa, kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀.

  7. Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀; níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́; yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta.

  8. Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru, tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán,

  9. tàbí fún àjàkálẹ̀-ààrùn tí ń rìn kiri ní òkùnkùn, tàbí fún ìparun tí ń rìn kiri ní ọ̀sán gangan.

  10. Ẹgbẹ̀rún (1,000) yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ, ṣùgbọ́n kì yóò súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.

  11. Ìwọ yóò máa wò ó pẹ̀lú ojú rẹ àti wo ìjìyà àwọn ẹni búburú.

  12. Nítorí ìwọ fi Olúwa ṣe ààbò rẹ, ìwọ fi Ọ̀gá-ògo ṣe ibùgbé rẹ.

  13. Búburú kan ki yóò ṣubú lù ọ́, Bẹ́ẹ̀ ni ààrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé rẹ.