Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Persia: Prophecies concerning

94 ẹsẹ · 9 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Prophecies concerning

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Kíyèsi i, èmi yóò ru àwọn Media sókè sí wọn, àwọn tí kò bìkítà fún fàdákà tí kò sì ní inú dídùn sí wúrà.

  2. Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan aginjù lẹ́bàá Òkun. Gẹ́gẹ́ bí ìjì líle ti í jà kọjá ní gúúsù, akógunjàlú kan wá láti aginjù, láti ilẹ̀ ìpayà.

  3. Ìran tí a ń fojú ṣọ́nà fún ni a ti fihàn mí ọlọ̀tẹ̀ ti tu àṣírí, fọ́lé fọ́lé ti kẹ́rù. Elamu kojú ìjà! Media ti tẹ̀gùn! Èmi yóò mú gbogbo ìpayínkeke dópin, ni ó búra.

  4. Pẹ̀lú èyí, ìrora mu mi lára gírígírí, ìrora gbá mi mú, gẹ́gẹ́ bí i ti obìnrin tí ń rọbí, mo ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nítorí ohun tí mo gbọ́, ọkàn mi pòruurù nípa ohun tí mo rí.

  5. Ọkàn mí dàrú, ẹ̀rù mú jìnnìjìnnì bá mi, ìmọ́lẹ̀ tí mo ti ń fẹ́ ẹ́ rí ti wá di ìpayà fún mi.

  6. Wọ́n tẹ́ tábìlì, wọ́n tẹ́ ẹní àtẹ́ẹ̀ká, wọ́n jẹ, wọ́n mu! Dìde nílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ-aládé, ẹ fi òróró kún asà yín!

  7. Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi: “Lọ, kí o bojúwòde kí o sì wá sọ ohun tí ó rí.

  8. Nígbà tí ó bá rí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin, àwọn tó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí àwọn tí ó gun ìbákasẹ, jẹ́ kí ó múra sílẹ̀, àní ìmúra gidigidi.”

  9. Òun sì kígbe pé, kìnnìún kan, “Láti ọjọ́ dé ọjọ́, olúwa mi, mo dúró lórí ilé ìṣọ́ ní ọ̀sán, a sì fi mí ìṣọ́ mi ní gbogbo òru.

  10. Wò ó, ọkùnrin kan ni ó ń bọ̀ wá yìí nínú kẹ̀kẹ́ ogun àti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin. Ó sì mú ìdáhùn padà wá: ‘Babeli ti ṣubú, ó ti ṣubú! Gbogbo àwọn ère òrìṣà rẹ̀ ló fọ́nká sórí ilẹ̀!’ ”

  11. Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí a gún mọ́lẹ̀ ní ilẹ̀ ìpakà, mo sọ ohun tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Israẹli.

  12. Èyí ní ọ̀rọ̀ Olúwa èyí tí ó tọ Jeremiah wòlíì wá nípa Elamu ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekiah ọba Juda.

  13. Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ: “Wò ó, èmi yóò fọ́ ìtẹ̀gùn Elamu, ẹni tí wọ́n sinmi lé nípa agbára.

  14. Èmi yóò mú kí afẹ́fẹ́ orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé lòdì sí Elamu. Èmi yóò tú wọn ká sí ìpín afẹ́fẹ́ mẹ́rin àti pé, kò sí orílẹ̀-èdè tí ilẹ̀ àjèjì Elamu kò ní lọ.

  15. Èmi yóò kẹ́gàn Elamu níwájú àwọn ọ̀tá wọn, àti níwájú àwọn tí wọ́n ń wá ẹ̀mí wọn, Èmi yóò mú ibi wá sí orí wọn, àní, ìbínú gbígbóná mi,” bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí. “Èmi yóò lé wọn pẹ̀lú idà, di ìgbà tí èmi yóò rẹ́yìn wọn.

  16. Èmi yóò sì gbé ìtẹ́ mi kalẹ̀ ní Elamu, èmí yóò sì pa ọba wọn àti ìjòyè wọn run,” báyìí ni Olúwa wí.

  17. “Síbẹ̀, èmi yóò dá ìkólọ Elamu padà láìpẹ́ ọjọ́,” báyìí ni Olúwa wí.

  18. “Ṣe ọfà rẹ ní mímú, mú àpáta! Olúwa ti ru ọba Media sókè, nítorí pé ète rẹ̀ ni láti pa Babeli run. Olúwa yóò gbẹ̀san, àní ẹ̀san fún tẹmpili rẹ̀.

  19. Gbé àsíá sókè sí odi Babeli! Ẹ ṣe àwọn ọmọ-ogun gírí, ẹ pín àwọn olùṣọ́ káàkiri, ẹ ṣètò àwọn tí yóò sá pamọ́ Olúwa! Yóò gbé ète rẹ̀ jáde, òfin rẹ̀ sí àwọn ará Babeli.

  20. Ìwọ tí o gbé lẹ́bàá odò púpọ̀, tí o sì ni ọ̀rọ̀ púpọ̀; ìgbẹ̀yìn rẹ ti dé, àní àsìkò láti ké ọ kúrò!

  21. Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti búra fún ara rẹ̀, Èmi yóò fún ọ ní ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ eṣú, wọn yóò yọ ayọ̀, ìṣẹ́gun lórí rẹ.

  22. “Ó dá ilẹ̀ nípa agbára rẹ̀, o dá ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀, o sì tẹ́ ọ̀run pẹ̀lú ìmọ̀ rẹ̀.

  23. Nígbà tí ará omi ọ̀run hó ó mú kí òfúrufú ru sókè láti ìpẹ̀kun ayé. Ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò, ó sì mú afẹ́fẹ́ jáde láti ilé ìṣúra rẹ̀.

  24. “Olúkúlùkù ènìyàn ni kò lọ́pọlọ tí kò sì ní ìmọ̀, olúkúlùkù alágbẹ̀dẹ ni a kó ìtìjú bá nípa òrìṣà rẹ̀. Àwọn ère rẹ jẹ́ ẹ̀tàn; wọn kò ní èémí nínú.

  25. Asán ni wọ́n, àti iṣẹ́ ìsìnà, nígbà ìbẹ̀wò wọn, wọn ó ṣègbé.