Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Perfection

71 ẹsẹ · 19 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí náà, ẹ jẹ́ pípé, gẹ́gẹ́ bí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ṣe jẹ́ pípé.

  2. Jesu wí fún un pé, “Bí ìwọ bá fẹ́ di ẹni pípé, lọ ta ohun gbogbo tí ìwọ ní, kí o sì fi owó rẹ̀ tọrẹ fún àwọn aláìní. Ìwọ yóò ní ọrọ̀ ńlá ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, wá láti máa tọ̀ mi lẹ́yìn.”

  3. Ẹni tí a ń kọ́ kì í ju olùkọ́ rẹ̀ lọ: ṣùgbọ́n olúkúlùkù ẹni tí a bá kọ dáradára, yóò dàbí olùkọ́ rẹ̀.

  4. Èmi nínú wọn, àti ìwọ nínú mi, kí a lè ṣe wọ́n pé ní ọ̀kan; kí ayé kí ó lè mọ̀ pé, ìwọ ni ó rán mi, àti pé ìwọ sì fẹ́ràn wọn gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fẹ́ràn mi.

  5. Ṣùgbọ́n àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n láàrín àwọn tí a pè, ṣùgbọ́n kì í ṣe ọgbọ́n ti ayé yìí tàbí ti àwọn olórí ayé yìí, èyí tí yóò di asán.

  6. Nítorí náà, ẹ̀yin olùfẹ́, bí a ti ní àwọn ìlérí wọ̀nyí, ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ara àti ti ẹ̀mí, kí a sọ ìwà mímọ́ dí pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

  7. Nítorí àwa ń yọ̀, nígbà ti àwa jẹ́ aláìlera, tí ẹ̀yin sì jẹ́ alágbára; èyí ni àwa sì ń gbàdúrà fún pẹ̀lú, àní pípé yín.

  8. Ní àkótán, ará ó dì gbòóṣe, ẹ ṣe àtúnṣe ọ̀nà yín, ẹ tújúká, ẹ jẹ́ onínú kan, ẹ máa wà ní àlàáfíà, Ọlọ́run ìfẹ́ àti ti àlàáfíà yóò wà pẹ̀lú yín.

  9. Nítorí náà ó sì ti fi àwọn kan fún ni bí aposteli; àti àwọn mìíràn bí i wòlíì; àti àwọn mìíràn bí efangelisti, àti àwọn mìíràn bí olùṣọ́-àgùntàn àti olùkọ́ni.

  10. Fún àṣepé àwọn ènìyàn mímọ́ fun iṣẹ́ ìránṣẹ́, fún ìmúdàgbà ara Kristi.

  11. Títí gbogbo wa yóò fi dé ìṣọ̀kan ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ Ọmọ Ọlọ́run, títí a ó fi di ọkùnrin, títí a ó fi dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwọ̀n Kristi.

  12. kí ẹ̀yin kí ó lè ní òye ohun tí ó dára jùlọ; kí ó sì jásí òdodo àti aláìjẹ́ ohun ìkọ̀sẹ̀ títí di ọjọ́ dídé Jesu Kristi,

  13. Kí ẹ̀yin lè jẹ́ aláìlẹ́gàn àti oníwà mímọ́, ọmọ Ọlọ́run, aláìlábàwọ́n, láàrín oníwà wíwọ́ àti alárékérekè orílẹ̀-èdè láàrín àwọn ẹni tí a ń rí yín bí ìmọ́lẹ̀ ní ayé.

  14. Kì í ṣe pé ọwọ́ mi ti tẹ̀ ẹ́ ná, tàbí mo ti di pípé, ṣùgbọ́n èmi ń lépa sí i, bí ọwọ́ mi yóò lè tẹ èrè náà nítorí èyí tí a ti dì mímú pẹ̀lú, láti ọ̀dọ̀ Kristi Jesu wá.

  15. Ará, èmi kò kara mi sí ẹni ti ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ́ ná, ṣùgbọ́n ohun kan yìí ni èmi ń ṣe, èmi ń gbàgbé àwọn nǹkan tí ó ti kọjá. Lẹ́yìn náà mo ń nàgà wo àwọn nǹkan tí ó wà níwájú.

  16. Èmi ń lépa láti dé òpin eré ìje náà fún èrè ìpè gíga Ọlọ́run nínú Kristi Jesu.

  17. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí àwa tí a dàgbà nípa ti ẹ̀mí ni èrò yìí; bí ẹ̀yin bá sì ní èrò mìíràn nínú ohunkóhun, èyí náà pẹ̀lú ni Ọlọ́run yóò fihàn yín.

  18. Ẹ̀yin ya ara yín nípá kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà kan rí, ẹ jẹ́ ọ̀tá nínú ọkàn yín nítorí ìwà búburú yín.

  19. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó ti bá yín làjà nípa ara Kristi nípa ikú láti mú un yín lọ sí iwájú rẹ̀ ní mímọ́, aláìlábàwọ́n àti kúrò nínú ìdálẹ́bi,

  20. Àwa ń wàásù rẹ̀, a ń gbani níyànjú a sì ń kọ olúkúlùkù ènìyàn ní ọgbọ́n gbogbo, kí a lè mú olúkúlùkù dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní pípé nínú Kristi.

  21. Nítorí nínú Kristi ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwàláàyè Ọlọ́run gbé ní ara,

  22. ẹ̀yin sì ní ohun gbogbo ní kíkún nínú Kristi, ẹni tí i ṣe orí fún gbogbo agbára àti àṣẹ.

  23. Nínú ẹni tí a kò fi ìkọlà tí a fi ọwọ́ kọ kọ yín ní ilà, ni bíbọ ara ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀, nínú ìkọlà Kristi.

  24. Àti borí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀, tí í ṣe àmùrè ìwà pípé.

  25. Epafira, ẹni tí ń ṣe ọ̀kan nínú yín àti ìránṣẹ́ Kristi Jesu kí i yín. Òun fi ìwàyáàjà gbàdúrà nígbà gbogbo fún un yín, kí ẹ̀yin kí ó lè dúró ní pípé nínú ohun gbogbo nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.