Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Old Age

39 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ọkùnrin kan le è ní ọgọ́rùn-ún ọmọ kí ó sì wà láààyè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, síbẹ̀ kò sí bí ó ti le wà láààyè pẹ́ tó, bí kò bá le è gbádùn ohun ìní rẹ̀ kí ó sì gba ìsìnkú tí ó tọ́, mo sọ wí pé ọlẹ̀ ọmọ tí a sin sàn jù ú lọ.

  2. Kódà, bí ó wà láààyè fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún méjì yípo ṣùgbọ́n tí ó kùnà láti gbádùn ohun ìní rẹ̀. Kì í ṣe ibìkan ni gbogbo wọn ń lọ?

  3. Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ ní ọjọ́ èwe rẹ, nígbà tí ọjọ́ ibi kò tí ì dé àti tí ọdún kò tí ì ní súnmọ́ etílé, nígbà tí ìwọ yóò wí pé, “Èmi kò ní ìdùnnú nínú wọn,”

  4. kí oòrùn àti ìmọ́lẹ̀ àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tó ṣókùnkùn, àti kí àwọsánmọ̀ tó padà lẹ́yìn òjò;

  5. nígbà tí olùṣọ́ ilé yóò wárìrì tí àwọn ọkùnrin alágbára yóò tẹríba, nígbà tí àwọn tí ó ń lọ dákẹ́ nítorí pé wọn kò pọ̀, tí àwọn tí ń wo òde láti ojú fèrèsé yóò ṣókùnkùn;

  6. nígbà tí ìlẹ̀kùn sí ìgboro yóò tì tí ariwo ọlọ yóò dákẹ́; nígbà tí àwọn ènìyàn yóò dìde sí ariwo àwọn ẹyẹ ṣùgbọ́n gbogbo orin wọn yóò máa lọ ilẹ̀.

  7. Nígbà tí ènìyàn yóò bẹ̀rù ibi gíga àti ti ìfarapa ní ìgboro; nígbà tí igi almondi yóò tanná àti tí ẹlẹ́ǹgà yóò wọ́ ara rẹ̀ lọ tí ìfẹ́ kò sì ní ru sókè mọ́ nígbà náà ni ènìyàn yóò lọ ilé rẹ́ ayérayé tí àwọn aṣọ̀fọ̀ yóò máa rìn kiri ìgboro.

  8. Rántí rẹ̀ kí okùn fàdákà tó já, tàbí kí ọpọ́n wúrà tó fọ́; kí iṣà tó fọ́ níbi ìsun, tàbí kí àyíká kẹ̀kẹ́ kí ó tó kán níbi kànga.

  9. Tí erùpẹ̀ yóò sì padà sí ilẹ̀ ibi tí ó ti wà, tí ẹ̀mí yóò sì padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tí ó fi í fún ni.

  10. Pẹ̀lúpẹ̀lú sí àwọn arúgbó àti ewú orí yín, Èmi ni ẹni náà, Èmi ni ẹni tí yóò gbé ọ ró. Èmi ti mọ ọ́, èmi yóò sì gbé ọ; Èmi yóò dì ọ́ mú èmi ó sì gbà ọ́ sílẹ̀.

  11. Ó sì ṣe opó títí ó fi di ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin, ẹni tí kò kúrò ní tẹmpili, ṣùgbọ́n ó ń fi àwẹ̀ àti àdúrà sin Ọlọ́run lọ́sàn án àti lóru.

  12. Kọ́ àwọn àgbà ọkùnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti ní ìrònú àti láti jẹ́ ẹni àpọ́nlé àti ẹni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Wọn gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó jinlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, nínú ìfẹ́ àti nínú ìpamọ́ra.

  13. Bákan náà, ni kí ó kọ́ àwọn àgbà obìnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti kọ́ bí à a tí gbé ìgbé ayé ẹni ọ̀wọ̀, wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ afọ̀rọ̀kẹ́lẹ́ batẹnijẹ́ tàbí olùfẹ́ ọtí mímu, ṣùgbọ́n wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ olùkọ́ni ní ohun rere.

  14. síbẹ̀ nítorí ìfẹ́ èmí kúkú bẹ̀ ọ́. Èmi gẹ́gẹ́ bí Paulu, arúgbó, àti nísinsin yìí òǹdè Jesu Kristi.