Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Kings

580 ẹsẹ · 175 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Bene-Dekeri ní Makasi, Ṣaalbimu, Beti-Ṣemeṣi, àti Eloni Beti-Hanani;

  2. Bene-Hesedi, ní Aruboti (tirẹ̀ ni Soko àti gbogbo ilẹ̀ Heferi ń ṣe);

  3. Bene-Abinadabu, ní Napoti (Dori; òun ni ó fẹ́ Tafati ọmọbìnrin Solomoni ní aya).

  4. Baana ọmọ Ahiludi, ní Taanaki àti Megido, àti ní gbogbo Beti-Ṣeani tí ń bẹ níhà Saretani ní ìsàlẹ̀ Jesreeli, láti Beti-Ṣeani dé Abeli-Mehola títí dé ibi tí ń bẹ ní ìkọjá Jokimeamu.

  5. Ọmọ Geberi ní Ramoti Gileadi (tirẹ̀ ni àwọn ìletò Jairi ọmọ Manase tí ń bẹ ní Gileadi, tirẹ̀ sì ni agbègbè Argobu, tí ń bẹ ní Baṣani, ọgọ́ta ìlú tí ó tóbi pẹ̀lú odi tí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ irin).

  6. Ahinadabu ọmọ Iddo ní Mahanaimu

  7. Ahimasi ní Naftali (ó fẹ́ Basemati ọmọbìnrin Solomoni ní aya).

  8. Baana ọmọ Huṣai ní Aṣeri àti ní Aloti;

  9. Jehoṣafati ọmọ Parua ni ó wà ní Isakari;

  10. Ṣimei ọmọ Ela ni Benjamini;

  11. Geberi ọmọ Uri ní Gileadi (orílẹ̀-èdè Sihoni ọba àwọn ará Amori àti orílẹ̀-èdè Ogu ọba Baṣani). Òun nìkan ni ìjòyè lórí ilẹ̀ náà.

  12. Rehoboamu sì lọ sí Ṣekemu, nítorí gbogbo Israẹli ti lọ síbẹ̀ láti fi í jẹ ọba.

  13. Nígbà tí Jeroboamu ọmọ Nebati, tí ó wà ní Ejibiti síbẹ̀ gbọ́, nítorí tí ó ti sá kúrò níwájú Solomoni ọba, ó sì wà ní Ejibiti.

  14. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ránṣẹ́ sí Jeroboamu, òun àti gbogbo ìjọ Israẹli sì lọ sọ́dọ̀ Rehoboamu, wọ́n sì wí fún un pé,

  15. “Baba rẹ sọ àjàgà wa di wúwo, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, mú kí ìsìn baba rẹ̀ tí ó le, àti àjàgà rẹ̀ tí ó wúwo, tí ó fi sí wa ní ọrùn kí ó fẹ́rẹ̀ díẹ̀, àwa yóò sì sìn ọ́.”

  16. Rehoboamu sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ná títí di ọjọ́ mẹ́ta, nígbà náà ni kí ẹ padà tọ̀ mí wá.” Àwọn ènìyàn náà sì lọ.

  17. Nígbà náà ni Rehoboamu ọba fi ọ̀rọ̀ lọ àwọn àgbàgbà tí ń dúró níwájú Solomoni baba rẹ̀ nígbà tí ó wà láààyè. Ó sì béèrè pé, “Ìmọ̀ràn wo ni ẹ̀yin yóò gbà mí láti dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí lóhùn?”

  18. Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Bí ìwọ yóò bá jẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí lónìí, kí o sì sìn wọ́n, àti kí o sì sọ ọ̀rọ̀ rere sí wọn nígbà tí ìwọ bá ń dá wọn lóhùn, wọn yóò máa ṣe ìránṣẹ́ rẹ títí láé.”

  19. Ṣùgbọ́n Rehoboamu kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbàgbà fún un, ó sì fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn ọmọdé tí wọ́n dàgbà pẹ̀lú rẹ̀, tí wọ́n sì ń sìn ín.

  20. Ó sì bi wọ́n pé, “Kí ni ìmọ̀ràn yín? Báwo ni a ó ṣe dá àwọn ènìyàn yí lóhùn, tí wọ́n wí fún mi pé, ‘Ṣé kí àjàgà tí baba rẹ fi sí wa lọ́rùn kí ó fúyẹ́ díẹ̀’?”

  21. Àwọn ọmọdé tí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Sọ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n wí fún ọ pé, ‘Baba rẹ̀ mú kí àjàgà wa wúwo ṣùgbọ́n ìwọ mú kí ó fúyẹ́ díẹ̀ fún wa’; sọ fún wọn pé, ìka ọwọ́ mi kékeré nípọn ju ẹ̀gbẹ́ baba mi lọ.

  22. Baba mi ti gbé àjàgà wúwo lé e yín; Èmi yóò sì fi kún àjàgà yín. Baba mi ti fi pàṣán nà yín, Èmi yóò fi àkéekèe nà yín.”

  23. Jeroboamu àti gbogbo àwọn ènìyàn náà wá sọ́dọ̀ Rehoboamu ní ọjọ́ kẹta, gẹ́gẹ́ bí ọba ti wí pé, “Ẹ padà tọ̀ mí wá ní ọjọ́ kẹta.”

  24. Ọba sì fi ohùn líle dá àwọn ènìyàn lóhùn, ó sì kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbàgbà fún un,

  25. Ó sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ọmọdé, ó sì wí pé, “Baba mí sọ àjàgà yín di wúwo, èmi yóò sì jẹ́ kí ó wúwo sí i, baba mi fi pàṣán nà yín èmi yóò fi àkéekèe nà yín.”