Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Judgments

271 ẹsẹ · 91 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí fún ejò náà pé, “Nítorí tí ìwọ ti ṣe èyí, “Ègún ni fún ọ ju gbogbo ohun ọ̀sìn àti gbogbo ẹranko igbó tókù lọ! Àyà rẹ ni ìwọ yóò fi máa wọ́, ìwọ yóò sì máa jẹ erùpẹ̀ ilẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

  2. Èmi yóò sì fi ọ̀tá sí àárín ìwọ àti obìnrin náà, àti sí àárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ obìnrin náà; òun yóò fọ́ orí rẹ, ìwọ yóò sì bù ú jẹ ní gìgísẹ̀.”

  3. Ọlọ́run sì wí fún Adamu pé, “Nítorí pé ìwọ fetí sí aya rẹ, ìwọ sì jẹ nínú èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀,’ “Ègún ni fún ilẹ̀ nítorí rẹ; nínú ọ̀pọ̀ làálàá ni ìwọ yóò jẹ nínú rẹ̀, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

  4. Ilẹ̀ yóò sì hu ẹ̀gún àti èṣùṣú fún ọ, ewéko igbó ni ìwọ yóò sì máa jẹ.

  5. Nínú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò máa jẹun títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀, nítorí inú ilẹ̀ ni a ti mú ọ jáde wá; erùpẹ̀ ilẹ̀ sá à ni ìwọ, ìwọ yóò sì padà di erùpẹ̀.”

  6. Láti ìsinsin yìí lọ, ìwọ ti wà lábẹ́ ègún, a sì ti lé ọ lórí ilẹ̀ tí ó ya ẹnu gba ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ lọ́wọ́ rẹ.

  7. Bí ìwọ bá ro ilẹ̀, ilẹ̀ kì yóò fi agbára rẹ̀ so èso rẹ̀ fún ọ mọ́. Ìwọ yóò sì jẹ́ ìsáǹsá àti alárìnkiri ni orí ilẹ̀ ayé.”

  8. Kaini wí fún Olúwa pé, “Ẹrù ìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi pọ̀ ju èyí tí mo le rù lọ.

  9. Lónìí, ìwọ lé mi kúrò lórí ilẹ̀, mó sì di ẹni tí ó fi ara pamọ́ kúrò ní ojú rẹ, èmi yóò sì di ìsáǹsá àti alárìnkiri ní ayé, ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi, yóò sì pa mí.”

  10. Ṣùgbọ́n, Olúwa wí fún pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ẹnikẹ́ni bá pa Kaini, èmi yóò gbẹ̀san ní ara onítọ̀hún ní ìgbà méje.” Nígbà náà ni Ọlọ́run fi àmì sí ara Kaini, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ri má ba à pa á.

  11. Ní àfẹ̀mọ́júmọ́, àwọn angẹli náà rọ Lọti pé, “Ṣe wéré, mú aya rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì tí ó wà níhìn-ín, àìṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò parun pẹ̀lú ìlú yìí nígbà tí wọ́n bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

  12. Nígbà tí ó ń jáfara, àwọn ọkùnrin náà nawọ́ mú un lọ́wọ́, wọ́n sì nawọ́ mú aya rẹ̀ náà lọ́wọ́ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì, wọ́n sì mú wọn jáde sẹ́yìn odi ìlú, nítorí Olúwa ṣàánú fún wọn.

  13. Ní kété tí wọ́n mú wọn jáde sẹ́yìn odi tán, ọ̀kan nínú wọn wí pé, “Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ! Má ṣe wo ẹ̀yìn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó má ṣe dúró ní gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀! Sá àsálà lọ sí orí òkè, kí ìwọ ó má ba ṣègbé!”

  14. Nígbà tí Lọti yóò fi dé ìlú Soari, oòrùn ti yọ.

  15. Nígbà náà ni Olúwa rọ̀jò iná àti sulfuru sórí Sodomu àti Gomorra láti ọ̀run lọ́dọ̀ Olúwa wá.

  16. Báyìí ni ó run àwọn ìlú náà àti gbogbo ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó wà ní ìlú ńlá ńlá wọ̀n-ọn-nì àti ohun gbogbo tí ó hù jáde nílẹ̀.

  17. nítorí nígbà yìí ni èmi yóò rán àjàkálẹ̀-ààrùn ti ó ní agbára gidigidi sí ọ, sí àwọn ìjòyè rẹ àti sí àwọn ènìyàn rẹ, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, kò sí ẹni bí èmi ni gbogbo ayé.

  18. Ó ti yẹ kí n ti na ọwọ́ mi jáde láti kọlù ọ́ àti àwọn ènìyàn rẹ pẹ̀lú ààrùn búburú ti kò bá ti run yín kúrò ni orí ilẹ̀.

  19. Ṣùgbọ́n nítorí èyí ni èmi ṣe mú ọ dúró, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, àti kí a bá à le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé.

  20. Ṣùgbọ́n Mose kígbe fún ojúrere Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, ó wí pé, “Olúwa, èéṣe tí ìbínú rẹ yóò ṣe gbóná sí àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ mú jáde láti Ejibiti wá pẹ̀lú agbára ńlá àti ọwọ́ agbára?

  21. Èéṣe tí àwọn ará Ejibiti yóò ṣe wí pé, ‘Nítorí ibi ni ó ṣe mọ̀ ọ́n mọ̀ mú wọn jáde, láti pa wọ́n ní orí òkè àti láti gbá wọn kúrò lórí ayé’? Yípadà kúrò nínú ìbínú rẹ tí ó múná, yí ọkàn padà, kí o má sì ṣe mú ìparun wá sórí àwọn ènìyàn rẹ.

  22. Rántí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Abrahamu, Isaaki àti Israẹli, ẹni tí ìwọ búra fún fúnra rẹ̀, ‘Tí o wí fún wọn pé, Èmi yóò mú irú-ọmọ rẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, Èmi yóò sì fún irú-ọmọ rẹ ní gbogbo ilẹ̀ tí mo ti pinnu fún wọn, yóò sì jẹ́ ogún ìní wọn láéláé.’ ”

  23. Nadabu àti Abihu tí í ṣe ọmọ Aaroni sì mú àwo tùràrí kọ̀ọ̀kan, wọ́n fi iná àti tùràrí sínú rẹ̀, wọ́n sì rú iná àjèjì níwájú Olúwa, èyí tó lòdì sí àṣẹ Olúwa.

  24. Torí èyí, iná jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì jó wọn pa, wọ́n sì kú níwájú Olúwa.

  25. Mose sì sọ fún Aaroni pé, “Ohun tí Olúwa ń sọ nípa rẹ̀ nìyìí nígbà tó wí pé, “ ‘Ní àárín àwọn tó súnmọ́ mi, Èmi yóò fi ara mi hàn ní mímọ́ ojú gbogbo ènìyàn Ní a ó ti bu ọlá fún mi.’ ” Aaroni sì dákẹ́.