Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Judgments: Are frequently tempered with mercy

4 ẹsẹ · 91 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Are frequently tempered with mercy

  1. Háà, ẹ̀yin ilé Israẹli,” ni Olúwa wí, “Èmi yóò mú kí orílẹ̀-èdè láti ọ̀nà jíjìn dìde sí i yín Orílẹ̀-èdè àtijọ́ àti alágbára nì àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ èdè rẹ̀, tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì yé ọ.

  2. Apó-ọfà rẹ sì dàbí isà òkú tí a ṣí gbogbo wọn sì jẹ́ akọni ènìyàn.

  3. Wọn yóò jẹ ìkórè rẹ àti oúnjẹ rẹ, àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin, wọn yóò sì jẹ agbo àti ẹran rẹ, wọn yóò jẹ àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ. Pẹ̀lú idà ni wọn ó run ìlú tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé.

  4. “Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,” ni Olúwa wí, “Èmi kì yóò pa yín run pátápátá.