Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Ingratitude to God

52 ẹsẹ · 14 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Orílẹ̀-èdè kan ha á pa ọlọ́run rẹ̀ dà? (Síbẹ̀, wọ́n kì í ṣe iṣẹ́ ọlọ́run.) Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi ti pààrọ̀ Ọlọ́run ògo wọn fún àwọn ère tí kò níyì.

  2. Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì kí ẹ sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù ńlá,” ni Olúwa wí.

  3. “Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì, wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, Èmi orísun omi ìyè, wọ́n sì ti ṣe àmù, àmù fífọ́ tí kò lè gba omi dúró.

  4. “Kí ni ṣe tí èmi ó ṣe dáríjì ọ́? Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀ àti pé wọ́n ti fi ọlọ́run tí kì í ṣe Ọlọ́run búra. Mo pèsè fún gbogbo àìní wọn, síbẹ̀ wọ́n tún ń ṣe panṣágà wọ́n sì kórajọ sí ilé àwọn alágbèrè.

  5. Wọ́n jẹ́ akọ ẹṣin tí a bọ́ yó, tí ó lágbára, wọ́n sì ń sọkún sí aya arákùnrin wọn.

  6. Èmi kì yóò ha ṣe ìbẹ̀wò nítorí nǹkan wọ̀nyí?” ni Olúwa wí. “Èmi kì yóò wá gba ẹ̀san fúnra mi lára irú orílẹ̀-èdè bí èyí bí?

  7. “Lọ sí ọgbà àjàrà rẹ̀, kí ẹ sì pa wọ́n run, ẹ má ṣe pa wọ́n run pátápátá. Ya ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, nítorí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ti Olúwa.

  8. Ilé Israẹli àti ilé Juda ti jẹ́ aláìṣòdodo sí mi,” ni Olúwa wí.

  9. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

  10. “Ọmọ ènìyàn, mú kí Jerusalẹmu mọ gbogbo ìwà ìríra rẹ̀.

  11. Sọ pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí Jerusalẹmu, ìran rẹ àti ilẹ̀ ìbí rẹ wà ní ilẹ̀ Kenaani; ará Amori ni baba rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ ará Hiti.

  12. Ní ọjọ́ tí a bí ọ, a kò gé okùn ìwọ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì fi omi wẹ̀ ọ́ láti mú kí o mọ́, a kò fi iyọ̀ pa ọ́ lára rárá, bẹ́ẹ̀ ni a kò fi aṣọ wé ọ.

  13. Kò sí ẹni tó ṣàánú tàbí kẹ́dùn rẹ dé bi à ti ṣe nǹkan kan nínú ìwọ̀nyí fún ọ, ṣùgbọ́n lọ́jọ́ ìbí rẹ, ìta la jù ọ́ sí torí wọ́n kórìíra rẹ.

  14. “ ‘Nígbà tí mo sì kọjá tí mo rí ọ tó ń jàgùdù nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ, mo sọ fún ọ pé, “Yè!” Nítòótọ́, nígbà tí ìwọ wà nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ pé, “Yè.”

  15. Mo mú ọ dàgbà bí ohun ọ̀gbìn inú oko. O ga sókè, o sì dàgbà, o wá di arẹwà jùlọ, ọmú rẹ yọ, irun rẹ gùn, ìwọ tí o wà ní ìhòhò láìfi nǹkan kan bora.

  16. “ ‘Nígbà tí mo tún kọjá, tí mo rí ọ, mo rí i pé àsìkò àti nífẹ̀ẹ́ rẹ ti tó, mo fi ìṣẹ́tí aṣọ mi bo ìhòhò rẹ. Mo búra fún ọ, èmi sì bá ọ dá májẹ̀mú ìwọ sì di tèmi, ni Olúwa Olódùmarè wí.

  17. “ ‘Nígbà náà ni mo fi omi wẹ ẹ̀jẹ̀ kúrò ní ara rẹ, mo fi ìpara pa ọ́ lára.

  18. Mo fi aṣọ oníṣẹ́-ọnà sí ọ lára láti wọ̀ ọ́, mo wọ bàtà aláwọ fún ọ. Mo fi aṣọ funfun gbòò àti aṣọ olówó iyebíye ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́.

  19. Mo fi ohun ọ̀ṣọ́ ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, mo fi ẹ̀gbà ọwọ́ sí ọ ní ọwọ́, mo fi ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn sí ọ ní ọrùn,

  20. mo sì tún fi òrùka sí ọ ní imú, mo fi yẹtí sí ọ ní etí, mo sì fi adé tó rẹwà dé ọ ní orí.

  21. Báyìí ni mo ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú wúrà àti fàdákà; tí aṣọ rẹ jẹ́ funfun gbòò, aṣọ olówó iyebíye àti aṣọ tí a ṣiṣẹ́ ọnà sí. Ìyẹ̀fun kíkúnná, oyin àti òróró ni oúnjẹ rẹ. Ó di arẹwà títí ó fi dé ipò ayaba.

  22. Òkìkí rẹ sì kàn káàkiri orílẹ̀-èdè nítorí ẹwà rẹ, nítorí dídán tí mo fi ṣe ẹwà rẹ ní àṣepé, ni Olúwa Olódùmarè wí.

  23. “ ‘Ṣùgbọ́n, ìwọ gbẹ́kẹ̀lé ẹwà rẹ, ìwọ sì di alágbèrè nítorí òkìkí rẹ. Ìwọ sì fọ́n ojúrere rẹ káàkiri sí orí ẹni yówù tó ń kọjá lọ, ẹwà rẹ sì di tìrẹ.

  24. “Ìwọ ọba, Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo fún Nebukadnessari baba rẹ ní ìjọba, títóbi ògo àti ọlá.

  25. Nítorí ipò ńlá tí a fi fún un, gbogbo ènìyàn orílẹ̀-èdè àti èdè gbogbo fi ń páyà tí wọ́n sì ń bẹ̀rù rẹ̀. Ó ń pa àwọn tí ó bá wù ú, ó sì ń dá àwọn tí ó bá wù ú sí, ó ń gbé àwọn tí ó bá wù ú ga, ó sì ń rẹ àwọn tí ó bá wù ú sílẹ̀.