Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Hypocrisy

246 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹ gbé ariwo orin yín sẹ́yìn! Èmi kò ní fetísí ohun èlò orin yín.

  2. Jẹ́ kí òtítọ́ sàn bí odò àti òdodo bí ìsun tí kò lé è gbẹ!

  3. “Àbí ẹ̀yin mú ẹbọ àti ọrẹ tọ̀ mí wá ní ogójì ọdún ní aginjù ìwọ ilé Israẹli?

  4. Ẹ̀yin ti gbé ibi ìrúbọ àwọn ọba yín sókè, ibùgbé àwọn òrìṣà yín, àní, ti àwọn òrìṣà yín tí ó níyì jùlọ, èyí tí ẹ̀yin fi ọwọ́ ara yín ṣe.

  5. Nítorí náà èmi yóò rán an yín lọ sí ìgbèkùn ní ìkọjá Damasku,” ni Olúwa wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọ́run alágbára.

  6. “Sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti fún àwọn àlùfáà pé, ‘Nígbà tí ẹ̀yin gbààwẹ̀, tí ẹ sì ṣọ̀fọ̀ ní oṣù karùn-ún àti keje, àní fun àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, ǹjẹ́ èmi ni ẹ̀yin ha ń gbààwẹ̀ yín fún?

  7. Nígbà tí ẹ sì jẹ, àti nígbà tí ẹ mu, fún ara yín kọ́ ni ẹ̀yin jẹ, àti fún ara yín kọ́ ni ẹ̀yin mú bí?

  8. “Ọmọ a máa bu ọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, ọmọ ọ̀dọ̀ a sì máa bu ọlá fún olúwa rẹ̀. Ǹjẹ́ bí èmí bá jẹ́ baba, ọlá tí ó tọ́ sí mi ha dà? Bí èmi bá sì jẹ́ olúwa, ẹ̀rù tí ó tọ́ sí mi dà?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Ẹ̀yin ni, ẹ̀yin àlùfáà, ni ẹ ń gan orúkọ mi. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe gan orúkọ rẹ?’

  9. “Ẹ̀yin gbé oúnjẹ àìmọ́ sí orí pẹpẹ mi. “Ẹ̀yin sì tún béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe ṣe àìmọ́ sí ọ?’ “Nípa sísọ pé tábìlì Olúwa di ẹ̀gàn.

  10. Nígbà tí ẹ̀yin mú afọ́jú ẹran wá fún ìrúbọ, ṣé èyí kò ha burú bí? Nígbà tí ẹ̀yin fi amúnkùn ún àti aláìsàn ẹran rú ẹbọ, ṣé èyí kò ha burú gidigidi bí? Ẹ dán an wò, ẹ fi wọ́n rú ẹbọ sí àwọn baálẹ̀ yín! Ṣé inú rẹ̀ yóò dùn sí yín? Ṣé yóò gbà yín?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  11. “Ní ìsinsin yìí, ẹ bẹ Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú irú àwọn ẹbọ wọ̀nyí láti ọwọ́ yín wá, ṣé yóò gbà yín?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  12. “Hó ò! Ẹnìkan ìbá jẹ́ wà láàrín yín ti yóò sé ìlẹ̀kùn tẹmpili, pé kí ẹ má ba à ṣe dá iná asán lórí pẹpẹ mi mọ́! Èmi kò ní inú dídùn sí i yín,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò gba ọrẹ kan lọ́wọ́ yín.

  13. Orúkọ mi yóò tóbi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, láti ìlà-oòrùn títí ó sì fi dé ìwọ̀-oòrùn. Ní ibi gbogbo ni a ó ti mú tùràrí àti ọrẹ mímọ́ wá fún orúkọ mi, nítorí orúkọ mi tóbi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  14. “Nítorí ẹ̀yin ti sọ ọ́ di àìmọ́, nínú èyí tí ẹ wí pé, ‘Tábìlì Olúwa di àìmọ́ àti èso rẹ̀,’ àní oúnjẹ rẹ̀ ni ohun ẹ̀gàn.

  15. Ẹ̀yin wí pẹ̀lú pé, ‘Wò ó, irú àjàgà kín ni èyí!’ Ẹ̀yin sì yínmú sí i,” ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Nígbà tí ẹ̀yin sì mú èyí tí ó fi ara pa, arọ àti ọlọkùnrùn ẹran tí ẹ sì fi rú ẹbọ, Èmi o ha gba èyí lọ́wọ́ yín?” ni Olúwa wí.

  16. “Ṣùgbọ́n ègún ni fún ẹlẹ́tàn náà, tí ó ni akọ nínú ọ̀wọ́ ẹran rẹ̀, tí ó sì ṣe ìlérí láti fi lélẹ̀ tí ó sì fi ẹran tó lábùkù rú ẹbọ sí Olúwa; nítorí ọba ńlá ni Èmi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “ẹ̀rù sì ni orúkọ mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

  17. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ àwọn Farisi àti Sadusi tí wọ́n ń wá ṣe ìtẹ̀bọmi, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀! Ta ni ó kìlọ̀ fún yín pé kí ẹ́ sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀?

  18. Ẹ so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà.

  19. “Ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe iṣẹ́ rere yín níwájú àwọn ènìyàn nítorí kí a le rí yín, Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin kò ni èrè kankan lọ́dọ̀ Baba yín ní ọ̀run.

  20. “Nítorí náà, nígbà ti ẹ́ bá ti ń fún aláìní, ẹ má ṣe fi fèrè kéde rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn àgàbàgebè ti í ṣe ní Sinagọgu àti ní ìta gbangba; kí àwọn ènìyàn le yìn wọ́n. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè tí wọn ní kíkún.

  21. “Kì í ṣe gbogbo ẹni tó ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run.

  22. Ọ̀pọ̀ ni yóò wí fún mi ní ọjọ́ náà pé, ‘Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, àti ní orúkọ rẹ kọ́ ni a fi lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí èṣù jáde, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu?’

  23. Ẹ̀yin àgàbàgebè, ní òtítọ́ ni Wòlíì Isaiah sọtẹ́lẹ̀ nípa yín wí pé:

  24. “ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń fi ẹnu lásán bu ọlá fún mi, ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà réré sí mi.

  25. Lásán ni ìsìn wọn; nítorí pé wọ́n ń fi òfin ènìyàn kọ́ ni ní ẹ̀kọ́.’ ”