Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Faith

543 ẹsẹ · 124 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àwọn ènìyàn púpọ̀ níbẹ̀ sì gbà á gbọ́.

  2. Nígbà náà, ni Marta wí fún Jesu pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú.

  3. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí náà, mo mọ̀ pé, ohunkóhun tí ìwọ bá béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run yóò fi fún ọ.”

  4. Jesu wí fún un pé, “Èmi ni àjíǹde àti ìyè, ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè.

  5. Ẹnikẹ́ni tí ó ń bẹ láààyè, tí ó sì gbà mí gbọ́, kì yóò kú láéláé ìwọ gbà èyí gbọ́?”

  6. Ó wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, èmi gbàgbọ́ pé, ìwọ ni Kristi náà Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí ń bọ̀ wá sí ayé.”

  7. Ẹ gbà mí gbọ́ pé, èmi wà nínú Baba, Baba sì wà nínú mi, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ gbà mí gbọ́ nítorí àwọn ẹ̀rí iṣẹ́ náà pàápàá!

  8. Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, iṣẹ́ tí èmi ń ṣe ni òun yóò ṣe pẹ̀lú; iṣẹ́ tí ó tóbi ju wọ̀nyí lọ ni yóò sì ṣe; nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba.

  9. “Bí mo sì ti bẹ̀rẹ̀ sì sọ, Ẹ̀mí Mímọ́ sì bà lé wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti bà lé wa ni àtètèkọ́ṣe.

  10. Nígbà náà ni mo rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí pé, ‘Johanu fi omi bamitiisi nítòótọ́; ṣùgbọ́n a ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi yín.’

  11. Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run sì ti fi irú ẹ̀bùn kan náà fún wọn bí ó ti fi fún àwa pẹ̀lú nígbà tí a gba Jesu Kristi Olúwa gbọ́, ta ni èmi tí n ó fi rò pé mo le è de Ọlọ́run ní ọ̀nà?”

  12. Ṣùgbọ́n, èmí jẹ́wọ́ fún ọ pé, èmi ń sin Ọlọ́run àwọn baba wa gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń tẹ̀lé ọ̀nà tí wọ́n ń pè ni ìyapa ìsìn. Èmi ń gbá gbogbo nǹkan ti a kọ sínú ìwé òfin gbọ́, àti tí a kọ sínú ìwé àwọn wòlíì,

  13. mo sí ní ìrètí kan náà nínú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí àwọn tìkára wọn jẹ́wọ́ pẹ̀lú, wí pé àjíǹde òkú ń bọ̀, àti tí olóòtítọ́, àti tí aláìṣòótọ́.

  14. Èmi kò tijú ìyìnrere Jesu, nítorí agbára Ọlọ́run ní ín ṣe láti gba gbogbo àwọn tí ó bá gbàgbọ́ là, ọ̀rọ̀ yìí ni a kọ́kọ́ wàásù sí àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nísinsin yìí fún àwọn Helleni pẹ̀lú.

  15. Nítorí nínú ìyìnrere ni òdodo Ọlọ́run ti farahàn, òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú Ìwé Mímọ́ pé, “Olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.”

  16. àní òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi, sí gbogbo ènìyàn àti gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́, nítorí tí kò sí ìyàtọ̀ láàrín Júù àti Helleni.

  17. Gbogbo ènìyàn ni ó ṣá ti ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọ́run,

  18. àwọn ẹni tí a ń dá láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, nípa ìdáǹdè tí ó wà nínú Kristi Jesu.

  19. Ẹni tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ ètùtù nípa ìgbàgbọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, láti fi òdodo rẹ̀ hàn nítorí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti kọjá, nínú ìpamọ́ra Ọlọ́run,

  20. láti fi òdodo rẹ̀ hàn ní ìgbà ìsinsin yìí: kí ó lè jẹ́ olódodo àti olùdáláre ẹni tí ó gba Jesu gbọ́.

  21. Ọ̀nà ìṣògo dà? A ti mú un kúrò. Nípa òfin wo? Nípa iṣẹ́? Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n nípa òfin ìgbàgbọ́.

  22. Nítorí náà, a parí rẹ̀ sí pé nípa ìgbàgbọ́ ni a ń dá ènìyàn láre láìsí iṣẹ́ òfin.

  23. Ǹjẹ́ kín ni àwa ó ha wí nípa Abrahamu, baba wa ti o ṣàwárí èyí? Májẹ̀mú láéláé jẹ́rìí sí i wí pé, a gba Abrahamu là nípa ìgbàgbọ́.

  24. Nítorí bí a bá dá Abrahamu láre nípa iṣẹ́, ó ní ohun ìṣògo; ṣùgbọ́n kì í ṣe níwájú Ọlọ́run.

  25. Ìwé Mímọ́ ha ti wí? “Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.”