Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Creditor

63 ẹsẹ · 3 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Bí ìwọ bá yá ọkùnrin Heberu ní ìwẹ̀fà, òun yóò sìn ọ́ fún ọdún mẹ́fà. Ṣùgbọ́n ní ọdún keje, òun yóò lọ ni òmìnira láìsan ohunkóhun padà.

  2. Bí ó bá wá ní òun nìkan, òun nìkan náà ni yóò padà lọ ní òmìnira; ṣùgbọ́n tí ó bá mú ìyàwó wá, ó ní láti mú ìyàwó rẹ̀ padà lọ.

  3. Bí olówó rẹ̀ bá fún un ní aya, tí aya náà sì bímọ ọkùnrin àti obìnrin, aya àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ ti olówó rẹ̀, yóò sì lọ ní òmìnira ní òun nìkan.

  4. “Bí ẹrú náà bá sì wí ní gbangba pé, mo fẹ́ràn olúwa mi, ìyàwó mi àti àwọn ọmọ, èmi kò sì fẹ́ ẹ́ gba òmìnira mọ́,

  5. nígbà náà ni olúwa rẹ̀ yóò mu wá sí iwájú ìdájọ́. Òun yóò sì mú un lọ sí ẹnu-ọ̀nà tàbí lọ sí ibi ọ̀wọ̀n, yóò sì fi ìlu lu etí rẹ̀, òun yóò sì máa sin olówó rẹ̀ títí ayé.

  6. “Bí ìwọ bá yá ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn mi tí ìyà ń jẹ láàrín yín lówó, má ṣe dàbí ayánilówó, kí o má sì gba èlé.

  7. Bí ìwọ bá gba aṣọ aládùúgbò rẹ ni ẹ̀jẹ́, ìwọ gbọdọ̀ fún un padà kí oòrùn tó ó wọ̀,

  8. nítorí aṣọ yìí nìkan ní ó ní ti ó lè fi bo àṣírí ara. Kí ni ohun mìíràn ti yóò fi sùn? Nígbà ti ó bá gbé ohun rẹ̀ sókè sí mi, èmi yóò gbọ́ nítorí aláàánú ni èmi.

  9. “ ‘Bí ẹ bá ta ilẹ̀ fún ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn yín tàbí bí ẹ bá ra èyíkéyìí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, ẹ má ṣe rẹ́ ara yín jẹ.

  10. Kí ẹ ra ilẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn yín ní gẹ́gẹ́ bí iye owó tí ó kù kí ọdún ìdásílẹ̀ pé, kí òun náà sì ta ilẹ̀ fún yín gẹ́gẹ́ bí iye ọdún rẹ̀ tókù láti kórè.

  11. Bí iye ọdún rẹ̀ bá gùn, kí iye owó rẹ̀ pọ̀, bí iye ọdún rẹ̀ bá kúrú, kí iye owó rẹ̀ kéré, torí pé ohun tí ó tà gan an ní iye èso rẹ̀.

  12. Ẹ má ṣe rẹ́ ara yín jẹ, ṣùgbọ́n ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

  13. “ ‘Bí arákùnrin yín kan bá tálákà tí kò sì le è pèsè fún àìní ara rẹ̀, ẹ pèsè fún un bí ẹ ti ń ṣe fún àwọn àlejò tàbí àwọn tí ẹ gbà sílé: kí ó ba à le è máa gbé láàrín yín.

  14. Ẹ kò gbọdọ̀ gba èlé kankan lọ́wọ́ rẹ̀, ẹ bẹ̀rù Olúwa kí arákùnrin yín le è máa gbé láàrín yín.

  15. Ẹ má ṣe gba èlé lórí owó tí ẹ yá a bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ èrè lórí oúnjẹ tí ẹ tà fún un.

  16. Báyìí ni kí ẹ máa ṣe é. Gbogbo ẹni tí wọ́n jẹ ní gbèsè gbọdọ̀ fojú fo gbèsè tí ó ti yá ará Israẹli ènìyàn rẹ̀. Kò gbọdọ̀ béèrè ohun náà, lọ́dọ̀ ará Israẹli ènìyàn rẹ̀ tàbí lọ́dọ̀ arákùnrin rẹ̀: nítorí pé a ti kéde àkókò Olúwa láti fojú fo gbèsè.

  17. Ẹ lè béèrè ìsanpadà lọ́dọ̀ àjèjì. Ṣùgbọ́n ẹ fa igi lé gbèsè yówù kó jẹ́ tí arákùnrin yín jẹ yín.

  18. Ìwọ kò gbọdọ̀ ka èlé sí arákùnrin rẹ lọ́rùn, bóyá lórí owó tàbí oúnjẹ tàbí ohunkóhun mìíràn tí ó lè mú èlé wá.

  19. Ìwọ lè ka èlé sí àlejò lọ́rùn, ṣùgbọ́n kì í ṣe arákùnrin ọmọ Israẹli, nítorí kí Olúwa Ọlọ́run rẹ lè bùkún ọ nínú ohun gbogbo tí o bá dáwọ́lé ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.

  20. Nígbà tí o bá wín arákùnrin rẹ ní ohunkóhun, má ṣe lọ sí ilé rẹ̀ láti gba ohun tí ó bá mú wá bí ẹ̀rí.

  21. Dúró síta gbangba kí o sì jẹ́ kí ọkùnrin tí o wín mú ògo rẹ jáde wá fún ọ.

  22. Bí ọkùnrin náà bá jẹ́ tálákà má ṣe lọ sùn ti ìwọ ti ògo rẹ.

  23. Dá aṣọ ìlekè rẹ padà ní àṣálẹ́ kí ó bá à le sùn lórí i rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, ó sì máa jásí ìwà òdodo níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ.

  24. Nísinsin yìí àwọn ènìyàn àti àwọn ìyàwó wọn kígbe ńlá sókè sí àwọn Júù arákùnrin wọn.

  25. Àwọn kan ń wí pé, “Àwa àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wa pọ̀; kí àwa kí ó le è jẹ, kí a sì wà láààyè, a gbọdọ̀ rí oúnjẹ.”