Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa All Christians Should Be As Missionaries

198 ẹsẹ · 66 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ó sọ fún ọ̀gá rẹ̀ obìnrin pé, “Tí ó bá jẹ́ wí pé ọ̀gá mi lè rí wòlíì tí ó wà ní Samaria! Yóò wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”

  2. Pẹ̀lú gbogbo ìrànlọ́wọ́ mi èmi ti pèsè fún ilé Ọlọ́run mi wúrà fún iṣẹ́ wúrà, fàdákà fún ti fàdákà, idẹ fún ti idẹ, irin fún ti irin àti igi fún ti igi àti òkúta oníyebíye fún títọ́ rẹ̀, òkúta lóríṣìíríṣìí, àwọ̀ àti oríṣìíríṣìí ẹ̀yà òkúta àti òkúta dáradára kan gbogbo wọ̀nyí ní iye púpọ̀.

  3. Yàtọ̀ fún èyí, nínú ìfọkànsìn mi sí ilé Ọlọ́run mi, èmí fi ìṣúra mi tìkára mi ti wúrà àti fàdákà fún ilé Ọlọ́run mi. Jù gbogbo rẹ̀ lọ, èmi ti pèsè fún ilé mímọ́ ti Olúwa yìí,

  4. Àwọn ènìyàn láyọ̀ nínú ìṣesí àtọkànwá fi sílẹ̀ àwọn olórí wọn, nítorí tí wọ́n ti fi sílẹ̀ ní ọ̀fẹ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn sí Olúwa. Dafidi ọba pẹ̀lú yọ̀ gidigidi.

  5. “Ṣùgbọ́n ta ni èmi, àti ta ni àwọn ènìyàn mi, tí a fi lè ṣe ìrànlọ́wọ́ tinútinú bí irú èyí? Gbogbo nǹkan wá láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ti wá, àwa sì ti fífún ọ láti ara ohun tí ó wá láti ọwọ́ rẹ.

  6. Olúwa Ọlọ́run wa tí fi gbogbo púpọ̀ yìí tí àwa ti pèsè fún kíkọ́ ilé Olúwa fun orúkọ, mímọ́ rẹ̀, ó wá láti ọwọ́ ọ̀ rẹ, gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ tirẹ̀.

  7. Nígbà náà àwọn olórí ìdílé Juda àti Benjamini àti àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi—olúkúlùkù ẹni tí Ọlọ́run ti fọwọ́ tọ́ ọkàn rẹ̀—múra láti gòkè lọ láti kọ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu.

  8. Láti ẹnu ọmọ ọwọ́ àti ọmọ ọmú ni o ti yan ìyìn nítorí àwọn ọ̀tá rẹ, láti pa àwọn ọ̀tá àti àwọn olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́.

  9. Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, òhun ni èmi yóò máa wá kiri: kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwa ní ọjọ́ ayé mi gbogbo, kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà Olúwa, kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀.

  10. Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé Olúwa dára; ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú rẹ̀.

  11. Wá, ẹ̀yin ọmọ mi, fi etí sí mi; èmi yóò kọ́ ọ yín ní ẹ̀rù Olúwa.

  12. Ẹnu olódodo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n, ahọ́n rẹ̀ a sì máa sọ̀rọ̀ ìdájọ́.

  13. Nígbà náà ni èmi yóò máa kọ́ àwọn olùrékọjá ní ọ̀nà rẹ, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò sì yí padà sí ọ.

  14. Ẹ wá gbọ́ gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run; ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí ó ṣe fún mi.

  15. Láti ìgbà èwe, Ọlọ́run ni ìwọ ti kọ́ mi títí di òní ni mo ń sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ.

  16. Pẹ̀lúpẹ̀lú, nígbà tí èmi di arúgbó tán tí mo sì hewú, má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọ́run mi, títí èmi ó fi ipá rẹ han ìran tí ń bọ̀, àti agbára rẹ fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn.

  17. Ahọ́n mi yóò sọ ti òdodo rẹ ní gbogbo ọjọ́, fún àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára, a sì dójúti àwọn tí ń wá ìdààmú mi.

  18. Èmi ṣàṣàrò lórí iṣẹ́ rẹ gbogbo, pẹ̀lú, ènìyàn sì máa sọ̀rọ̀ gbogbo iṣẹ́ agbára rẹ.

  19. Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jakọbu o sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Israẹli, èyí tí ó pàṣẹ fún àwọn baba ńlá wa láti kọ́ àwọn ọmọ wọn,

  20. nítorí náà, àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò mọ̀ wọ́n bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí tí yóò dìde tí wọn yóò sọ fún àwọn ọmọ wọn.

  21. Nígbà náà ni wọ́n ò fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú Ọlọ́run wọn kò sì ní gbàgbé iṣẹ́ Ọlọ́run ṣùgbọ́n wọn ó pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.

  22. Kí wọn kí ó má ṣe dàbí àwọn baba ńlá wọn, ìran alágídí àti ọlọ́tẹ̀, ìran tí ọkàn wọn kò ṣọ òtítọ́ si olóore, àti ẹ̀mí ẹni tí kò bá Ọlọ́run dúró ṣinṣin.

  23. Ó ti pín ká, ó ti fi fún àwọn olùpọ́njú, nítorí òdodo rẹ̀ dúró láé; ìwo rẹ̀ ní a ó gbé sókè pẹ̀lú ọlá.

  24. Olúwa, nítòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ ni mo jẹ́; èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ; ó ti tú mi sílẹ̀ nínú ìdè mi.

  25. Èmi yóò rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ èmi yóò sì ké pe orúkọ Olúwa.