Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Afflictions Made Beneficial

104 ẹsẹ · 23 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n òun mọ ọ̀nà tí èmi ń tọ̀, nígbà tí ó bá dán mí wò, èmi yóò jáde bí wúrà.

  2. “Nítorí pé ẹnìkan ha lè wí fún Ọlọ́run pé, èmi jẹ̀bi, èmi kò sì ní ṣẹ̀ mọ́?

  3. Èyí tí èmi kò rí ìwọ fi kọ́ mi bi mo bá sì dẹ́ṣẹ̀ èmi kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.

  4. Bí ó bá sì dè wọ́n nínú àbà, tí a sì fi okùn ìpọ́njú dè wọ́n,

  5. nígbà náà ni ó ń sọ àwọn ohun tí wọn ti ṣe fún wọn, wí pé wọ́n ti ṣẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga wọn.

  6. Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ àti pé èmi kò sì fi àìṣòdodo mi pamọ́. Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Olúwa,” ìwọ sì dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Sela.

  7. Ìpọ́njú àwọn olódodo pọ̀, ṣùgbọ́n Olúwa gbà wọ́n kúrò nínú gbogbo rẹ̀.

  8. Ó pa gbogbo egungun wọn mọ́; kò sí ọ̀kan tí ó dá nínú wọn.

  9. Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dúró de Olúwa; ó sì dẹtí sí mi, ó sì gbọ́ ẹkún mi.

  10. Nítorí mo mọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi, nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi wà níwájú mi.

  11. Nítòótọ́, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni a ti bí mi, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mí sì lóyún mi.

  12. Nítorí ìwọ, Ọlọ́run, dán wa wò; ìwọ dán wa bí a tí ń dán fàdákà wò.

  13. Nígbàkígbà tí Ọlọ́run bá pa wọ́n, wọn yóò wá a kiri; wọn yóò fi ìtara yípadà sí i.

  14. Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti ṣìnà, ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí èmi gbọ́rọ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ.

  15. Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójú nítorí kí èmi lè kọ́ òfin rẹ.

  16. Iná ni a fi fọ́ fàdákà àti wúrà, ṣùgbọ́n Olúwa ló ń dán ọkàn wò.

  17. Ó dára láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ ju ibi àsè, nítorí pé ikú jẹ́ àyànmọ́ gbogbo ènìyàn; kí alààyè ní èyí ní ọkàn.

  18. Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọ, ó le è mú kí ojú rẹ̀ dàrú, ṣùgbọ́n yóò jẹ́ kí àyà rẹ le.

  19. Èmi yóò pa ọwọ́ mi dà sí ọ, èmi ó sì ku ìpẹ́pẹ́ rẹ dànù, n ó sì mú gbogbo ìdọ̀tí rẹ kúrò.

  20. Èmi yóò mú àwọn adájọ́ rẹ bọ̀ sí ipò gẹ́gẹ́ bí i ti àtijọ́, àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ bí i ti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Lẹ́yìn náà ni a ó pè ọ ní ìlú òdodo, ìlú òtítọ́.”

  21. Ní ọjọ́ náà, àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Israẹli, àwọn tí ó yè ní ilé e Jakọbu, kò ní gbẹ́kẹ̀lé ẹni náà tí ó lù wọ́n bolẹ̀, ṣùgbọ́n ní òtítọ́ yóò gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, Ẹni Mímọ́ Israẹli.

  22. Àwọn ìyókù yóò padà, àwọn ìyókù ti Jakọbu yóò padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Alágbára.

  23. Ọkàn mi ń pòùngbẹẹ̀ rẹ ní ọ̀gànjọ́ òru; ní òwúrọ̀ ni ẹ̀mí mi ń ṣàfẹ́rí rẹ. Nígbà tí ìdájọ́ rẹ bá sọ̀kalẹ̀ sórí ayé àwọn ènìyàn yóò kọ́ ìṣòdodo.

  24. Wò ó, èmi ti tún ọ ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe bí i fàdákà; Èmi ti dán ọ wò nínú ìléru ìpọ́njú.

  25. Ó ń gbé ní àárín ẹ̀tàn; wọ́n kọ̀ láti mọ̀ mí nínú ẹ̀tàn wọn,” ni Olúwa wí.