Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Afflictions Made Beneficial: In leading us to seek God in prayer

8 ẹsẹ · 23 abala

Àwọn ẹsẹ nípa In leading us to seek God in prayer

  1. Nítorí tí ó ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900) kẹ̀kẹ́ ogun irin, ó sì ń pọ́n Israẹli lójú gidigidi fún ogún ọdún, Israẹli ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́.

  2. “Nítòótọ́, èmi ti gbọ́ ìpohùnréré Efraimu wí pé, ‘Ìwọ ti bá mi wí gẹ́gẹ́ bí ọmọ màlúù tí a kò kọ́ èmi sì ti gbọ́ ìbáwí. Rà mí padà, èmi yóò sì yípadà, nítorí ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run mi.

  3. Olúwa ti ṣe ohun tí ó pinnu; ó ti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ, tí ó sì pàṣẹ ní ọjọ́ pípẹ́. Ó ti ṣí ọ ní ipò láì láàánú, ó fún ọ̀tá ní ìṣẹ́gun lórí rẹ, ó ti gbé ìwo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ga.

  4. Ọkàn àwọn ènìyàn kígbe jáde sí Olúwa. Odi ọmọbìnrin Sioni, jẹ́ kí ẹkún rẹ̀ sàn bí odò ní ọ̀sán àti òru; má ṣe fi ara rẹ fún ìtura, ojú rẹ fún ìsinmi.

  5. Dìde, kígbe sókè ní àṣálẹ́, bí ìṣọ́ òru ti bẹ̀rẹ̀ tú ọkàn rẹ̀ jáde bí omi níwájú Olúwa. Gbé ọwọ́ yín sókè sí i nítorí ẹ̀mí àwọn èwe rẹ̀ tí ó ń kú lọ nítorí ebi ní gbogbo oríta òpópó.

  6. Nítorí pé, èmi ó dàbí kìnnìún sí Efraimu, bí i kìnnìún ńlá sí ilé Juda. Èmi ó fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ èmi ó sì lọ; Èmi ó gbé wọn lọ, láìsí ẹni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀.

  7. Nígbà náà ni èmi ó padà lọ sí ààyè mi títí di ìgbà tí wọn ó fi gbà pé àwọn jẹ̀bi wọn yóò sì wá ojú mi nínú ìpọ́njú wọn, wọn ó fi ìtara wá mi.”

  8. Nígbà náà ni Jona gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ láti inú ẹja náà wá,