Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Affections

39 ẹsẹ · 12 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ǹjẹ́ ayọ̀ yín ìgbà náà ha dà? Nítorí mo gba ẹ̀rí yín pé, bi o bá ṣe é ṣe, ẹ̀ ò bá yọ ojú yín jáde, ẹ̀ bá sì fi wọ́n fún mi.

  2. Wọ́n ń fi ìtara wá yin, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún rere; wọ́n ń fẹ́ já yin kúrò, kí ẹ̀yin lè máa wá wọn.

  3. Ṣùgbọ́n ó dára láti máa fi ìtara wá ni fún ohun rere nígbà gbogbo, kì í sì í ṣe nígbà tí mo wà pẹ̀lú yín nìkan.

  4. Àwọn tí í ṣe ti Kristi Jesu ti kan ara wọn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀.

  5. Ẹ máa pa ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ ní ayé run: àgbèrè, panṣágà, ìwà àìmọ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìwọra, nítorí pé ìwọ̀nyí jásí ìbọ̀rìṣà.

  6. kì í ṣe ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìkọlà, ẹni tí kò mọ Ọlọ́run;

  7. Aláìnífẹ̀ẹ́, aláìlèdáríjì, abanijẹ́, aláìlè-kó-aràwọn-níjánu, òǹrorò, aláìnífẹ̀ẹ́ ohun rere,

  8. Nítorí nínú irú èyí ni àwọn ti ń rákò wọ inú ilé, tí wọ́n sì ń di àwọn obìnrin aláìlọ́gbọ́n tí a di ẹ̀ṣẹ̀ rù ní ìgbèkùn, tí a sì ń fi onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ fà kiri.

  9. Nínú ìwà wọ̀bìà wọn, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ òdì wọ̀nyí yóò máa rẹ́ ẹ yín jẹ nípa ìtàn asán. Ìdájọ́ ẹni tí kò falẹ̀ láti ìgbà yìí wá àti ìparun wọn tí kò sí tòògbé.

  10. Ṣùgbọ́n pàápàá àwọn tí ó ń tọ ẹran-ara lẹ́yìn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìwà èérí, tí wọ́n sì ń gan àwọn ìjòyè. Àwọn ọ̀dájú àti agbéraga, wọn kò bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí àwọn ẹni ògo.

  11. Nítorí ìgbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ ìhàlẹ̀ asán, nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, wọn a máa tan àwọn tí wọ́n fẹ́rẹ̀ má tí ì bọ́ tán kúrò lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n wà nínú ìṣìnà.

  12. Síbẹ̀ èyí ni mo rí wí sí ọ, pé, ìwọ ti fi ìfẹ́ ìṣáájú rẹ sílẹ̀.

  13. Ṣùgbọ́n mo ni nǹkan díẹ̀ wí sí ọ; nítorí tí ìwọ ní àwọn kan tí ó di ẹ̀kọ́ Balaamu mú síbẹ̀, ẹni tí ó kọ́ Balaki láti mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá síwájú àwọn ọmọ Israẹli, láti máa jẹ ohun tí a pa rú ẹbọ sí òrìṣà, àti láti máa ṣe àgbèrè.

  14. Ṣùgbọ́n èyí ni mo rí wí sí ọ, nítorí tí ìwọ fi ààyè sílẹ̀ fún obìnrin Jesebeli tí ó ń pe ara rẹ̀ ní wòlíì. Nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì ń kọ́ àwọn ìránṣẹ́ mi, ó sì ń tàn wọ́n láti máa ṣe àgbèrè, àti láti máa jẹ ohun tí a pa rú ẹbọ sì òrìṣà.