Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Adultery

242 ẹsẹ · 4 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tọ Abimeleki wá ní ojú àlá lọ́jọ́ kan, ó sì wí fún un pé, “Kíyèsi, kò sí ohun tí o fi sàn ju òkú lọ, nítorí obìnrin tí ìwọ mú sọ́dọ̀ n nì, aya ẹni kan ní íṣe.”

  2. Nísinsin yìí, dá aya ọkùnrin náà padà, nítorí pé wòlíì ni, yóò sì gbàdúrà fún ọ, ìwọ yóò sì yè. Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá dá a padà, mọ̀ dájú pé ìwọ àti gbogbo ẹni tí í ṣe tìrẹ yóò kú.”

  3. Nígbà náà ni Abimeleki pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ọkùnrin yìí tàbí aya rẹ̀ yóò jẹ̀bi ikú.”

  4. Lẹ́yìn nǹkan bí oṣù mẹ́ta, wọn sọ fún Juda pé, “Tamari aya ọmọ rẹ̀ ṣe àgbèrè, ó sì ti lóyún.” Juda sì wí pé, “Ẹ mú un jáde, kí ẹ sì dá iná sun ún.”

  5. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.

  6. “Bí ọkùnrin kan bá fi àrékérekè mú wúńdíá kan, ẹni tí kò pinnu láti fẹ́, tí ó sì bá a lòpọ̀, yóò san owó orí rẹ̀, yóò sì fi ṣe aya rẹ̀.

  7. Bí baba ọmọbìnrin náà bá kọ̀ jálẹ̀ láti fi fún un ní aya, ó ni láti san owó tó tó owó orí rẹ̀ fún fífẹ́ ẹ ní wúńdíá.

  8. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá aya aládùúgbò rẹ lòpọ̀, kí ìwọ má ba à ba ara rẹ jẹ́ pẹ̀lú rẹ̀.

  9. “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá obìnrin tí ó jẹ́ ẹrú lòpọ̀, ẹni tí a ti mọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn tí a kò sì tí ì rà á padà tàbí sọ ọ́ di òmìnira. Ẹ gbọdọ̀ ṣe ìwádìí kí ẹ sì jẹ wọ́n ní ìyà tó tọ́ ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ pa wọ́n, torí pé kò ì tí ì di òmìnira.

  10. Kí ọkùnrin náà mú àgbò kan wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé bí i ẹbọ ẹ̀bi sí Olúwa.

  11. Àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù fún un, pẹ̀lú àgbò ẹbọ ẹ̀bi náà níwájú Olúwa fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀. A ó sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ náà jì í.

  12. “ ‘Ẹ má ṣe ba ọmọbìnrin yín jẹ́ láti sọ ọ́ di panṣágà, kí ilẹ̀ yín má ba à di ti àgbèrè, kí ó sì kún fún ìwà búburú.

  13. “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀: ọkùnrin àti obìnrin náà ni kí ẹ sọ ní òkúta pa.

  14. “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya baba rẹ̀ lòpọ̀ ti tàbùkù baba rẹ̀. Àwọn méjèèjì ni kí ẹ pa. Ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.

  15. “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá arábìnrin ìyàwó rẹ̀ lòpọ̀, àwọn méjèèjì ni kí ẹ pa, wọ́n ti ṣe ohun tí ó lòdì, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.

  16. “ ‘Bí ọmọbìnrin àlùfáà kan bá fi iṣẹ́ àgbèrè ba ara rẹ̀ jẹ́, ó dójútì baba rẹ̀, iná ni a ó dá sun ún.

  17. Olúwa sọ fún Mose wí pé,

  18. “Bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀ kí o sọ fún wọn pé, ‘Bí ìyàwó ọkùnrin kan bá yapa tó sì ṣe àìṣòótọ́ sí i,

  19. nípa mímú kí ọkùnrin mìíràn bá a lòpọ̀ tí ó sì fi èyí pamọ́ fún ọkọ rẹ̀, tí a kò si gbá a mú nínú ìwà àìmọ́ rẹ̀ (nítorí pé kò sí ẹlẹ́rìí àti pé wọn kò ká a mọ́ nígbà tí ó ń dẹ́ṣẹ̀ náà).

  20. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀mí owú jíjẹ bá bà lé ọkọ rẹ̀ dé bi pé ó ń funra sí ìyàwó rẹ̀ yìí tí ìyàwó rẹ̀ sì wà ní àìmọ́ nítòótọ́, tàbí tí ẹ̀mí owú bá bà lé ọkùnrin kan tó sì ń jowú ìyàwó rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wà ní mímọ́,

  21. nígbà náà ni ọkùnrin yìí yóò mú ìyàwó rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àlùfáà. Ọkùnrin náà yóò sì mú ọrẹ tí a yàn fún obìnrin náà, ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n efa ìyẹ̀fun barle. Kò gbọdọ̀ da òróró sí i, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ fi tùràrí dídùn sí i nítorí pé ẹbọ ohun jíjẹ fún owú ni, èyí ti n mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ìrántí.

  22. “ ‘Àlùfáà yóò sì mú un wá síwájú Olúwa.

  23. Àlùfáà yóò sì bu erùpẹ̀ ilẹ̀ àgọ́ sínú omi mímọ́ tó bù láti ìkòkò amọ̀.

  24. Lẹ́yìn èyí, àlùfáà yóò mú obìnrin náà dúró níwájú Olúwa yóò sì tú irun orí obìnrin náà lé e lọ́wọ́, èyí ni ẹbọ ohun jíjẹ ti owú, àlùfáà fúnra rẹ̀ yóò sì gbé omi kíkorò tí ń mú ègún lọ́wọ́.

  25. Àlùfáà yóò sì mú obìnrin náà búra, yóò wí pé, “Bí ọkùnrin mìíràn kò bá bá ọ lòpọ̀, tí ó kò sì yapa, tí o kò sì di aláìmọ́ níwọ̀n ìgbà tí ó wà lábẹ́ àṣẹ ọkọ rẹ̀, a jẹ́ pé omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí kò ní ṣe ọ́ níbi.