- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1010–970 BC
The Reign of David
David unites the tribes, conquers Jerusalem, and establishes Israel's golden age—even through deep personal failure.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- 1 Kronika 27:6nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Èyí ni Benaiah náà tí ó jẹ́ ọkùnrin ńlá láàrín àwọn ọgbọ̀n àti lórí àwọn ọgbọ̀n. Ọmọ rẹ̀ Amisabadi jẹ́ alákòóso lórí ìpín tirẹ̀.
- 1 Kronika 27:7nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Ẹlẹ́ẹ̀kẹrin fún oṣù kẹrin, jẹ́ Asaheli arákùnrin Joabu: ọmọ rẹ̀ Sebadiah jẹ́ arọ́pò rẹ̀. Ẹgbàá méjìlá (24,000) ọkùnrin ni ó wà ní ìpín rẹ̀.
- 1 Kronika 27:8nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Ẹ̀karùnún fún oṣù karùn-ún, jẹ́ olórí Ṣamhuti ará Israhi. Ẹgbàá méjìlá (24,000) ọkùnrin ní ó wà ní ìpín tirẹ̀.
- 1 Kronika 27:9nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Ẹ̀kẹfà fún oṣù kẹfà jẹ́ Ira ọmọ Ikẹsi, ará Tekoi. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀.
- 1 Kronika 27:10nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Èkeje fún oṣù keje jẹ́ Helesi ará Peloni, ará Efraimu. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni o wà ní ìpín rẹ̀.
- 1 Kronika 27:11nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Ẹ̀kẹjọ fún oṣù kẹjọ jẹ́ Sibekai ará Huṣati, ará Sera ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀.
- 1 Kronika 27:12nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Ẹ̀kẹsànán fún oṣù kẹsànán jẹ́. Abieseri ará Anatoti, ará Benjamini ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀.
- 1 Kronika 27:13nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Ẹ̀kẹwàá fún oṣù kẹwàá jẹ́ Maharai ará Netofa, ará Sera ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀.
- 1 Kronika 27:14nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Ìkọkànlá fún oṣù kọkànlá jẹ́ Benaiah ará Piratoni ará Efraimu ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.
- 1 Kronika 27:15nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Èkejìlá fún oṣù kejìlá jẹ́ Heldai ará Netofa láti ìdílé Otnieli. Ẹgbàá méjìlá (24,000) ọkùnrin ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.
- 1 Kronika 27:16nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Àwọn ìjòyè lórí àwọn ẹ̀yà tí Israẹli: lórí àwọn ará Reubeni: Elieseri ọmọ Sikri; lórí àwọn ọmọ Simeoni: Ṣefatia ọmọ Maaka;
- 1 Kronika 27:17nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
lórí Lefi: Haṣabiah ọmọ Kemueli; lórí Aaroni: Sadoku;
- 1 Kronika 27:18nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
lórí Juda: Elihu arákùnrin Dafidi; lórí Isakari: Omri ọmọ Mikaeli;
- 1 Kronika 27:19nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
lórí Sebuluni: Iṣmaiah ọmọ Obadiah; lórí Naftali: Jerimoti ọmọ Asrieli;
- 1 Kronika 27:20nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
lórí àwọn ará Efraimu: Hosea ọmọ Asasiah; lórí ààbọ̀ ẹ̀yà Manase: Joẹli ọmọ Pedaiah;
- 1 Kronika 27:21nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
lórí ààbọ̀ ẹ̀yà Manase ní Gileadi: Iddo ọmọ Sekariah; lórí Benjamini: Jaasieli ọmọ Abneri;
- 1 Kronika 27:22nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
lórí Dani: Asareeli ọmọ Jerohamu. Wọ̀nyí ni àwọn ìjòyè lórí ẹ̀yà Israẹli.
- 1 Kronika 27:23nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Dafidi kò kọ iye àwọn ọkùnrin náà ní ogún ọdún sẹ́yìn tàbí dín nítorí Olúwa ti ṣe ìlérí láti ṣe Israẹli gẹ́gẹ́ bí iye ìràwọ̀ ojú ọ̀run.
- 1 Kronika 27:24nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Joabu ọmọ Seruiah bẹ̀rẹ̀ sí ní kà wọ́n, ṣùgbọ́n kò parí kíkà wọ́n nítorí, ìbínú dé sórí àwọn Israẹli nípasẹ̀ kíka iye àti iye náà, a kò kọ ọ́ sínú ìwé ìtàn ayé ti ọba Dafidi.
- 1 Kronika 27:25nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Asmafeti ọmọ Adieli wà ní ìdí ilé ìṣúra ti ọba. Jonatani ọmọ Ussiah wà ní ìdí ilé ìṣúra ní iwájú agbègbè nínú àwọn ìlú, àwọn ìletò àti àwọn ilé ìṣọ́.
- 1 Kronika 27:26nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Esri ọmọ Kelubu wà ní ìdí àwọn òṣìṣẹ́ lórí pápá, tí wọ́n ń ko ilẹ̀ náà.
- 1 Kronika 27:27nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Ṣimei ará Ramoti wà ní ìdí àwọn ọgbà àjàrà. Sabdi ará Sifmi wà ní ìdí mímú jáde ti èso àjàrà fún ọpọ́n ńlá tí a ń fi ọ̀tún èso àjàrà sí.
- 1 Kronika 27:28nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Baali-Hanani ará Gederi wà ní ìdí olifi àti àwọn igi sikamore ní apá ìhà ìwọ̀-oòrùn àwọn ní ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀. Joaṣi wà ní ìdí fífún ni ní òróró olifi.
- 1 Kronika 27:29nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Ṣitrai ará Ṣaroni wà ní ìdí fífi ọwọ́ ẹran jẹ oko ní Ṣaroni. Ṣafati ọmọ Adlai wà ní ìdí àwọn ọ̀wọ́ ẹran ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀.
- 1 Kronika 27:30nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Obili ará Iṣmaeli wà ní ìdí àwọn ìbákasẹ. Jehdeiah ará Meronoti wà ní ìdí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.