Fò sí àkóónú

Jerusalem

753 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jerusalem's

31.7700, 35.2300 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jerusalem

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Wọ̀nyí ni àwọn olórí agbègbè ìjọba tí wọ́n tẹ̀dó sí Jerusalẹmu (díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Israẹli àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi, àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ìran àwọn ìránṣẹ́ Solomoni ń gbé àwọn ìlú Juda, olúkúlùkù ń gbé lórí ilẹ̀ ìní rẹ̀ ní àwọn ìlú náà.

  2. Nígbà tí àwọn ènìyàn tókù nínú àwọn Juda àti Benjamini ń gbé ní Jerusalẹmu). Nínú àwọn ọmọ Juda: Ataiah ọmọ Ussiah ọmọ Sekariah, ọmọ Amariah, ọmọ Ṣefatia, ọmọ Mahalaleli, ìran Peresi;

  3. Àwọn ìran Peresi tó gbé ní Jerusalẹmu jẹ́ àádọ́rinlénírinwó ó dín méjì (468) alágbára ọkùnrin.

  4. Olórí òṣìṣẹ́ àwọn ọmọ Lefi ní Jerusalẹmu ní Ussi ọmọ Bani, ọmọ Haṣabiah, ọmọ Mattaniah ọmọ Mika. Ussi jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìran Asafu tí wọ́n jẹ́ akọrin ojúṣe nínú ìjọ́sìn ní ilé Ọlọ́run.

  5. Nígbà ìyàsímímọ́ odi Jerusalẹmu a mú àwọn ọmọ Lefi jáde wá láti ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú wọn wá sí Jerusalẹmu láti fi ayọ̀ ṣe ayẹyẹ ìyàsímímọ́ pẹ̀lú orin ìdúpẹ́ àti pẹ̀lú ohun èlò orin kimbali, haapu àti ohun èlò orin olókùn.

  6. A kó àwọn akọrin náà jọ papọ̀ láti àwọn ìletò tí ó yí Jerusalẹmu náà ká—láti àwọn abúlé Netofa,

  7. láti Beti-Gilgali, àti láti àwọn agbègbè Geba àti Asmafeti, nítorí àwọn akọrin ti kọ́ àwọn ìletò fúnra wọn ní agbègbè Jerusalẹmu.

  8. Ní ọjọ́ náà wọ́n rú ẹbọ ńlá, wọ́n ṣe àjọyọ̀ nítorí Ọlọ́run ti fún wọn ní ayọ̀ ńlá. Àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé sì yọ̀ pẹ̀lú. A lè gbọ́ ariwo ayọ̀ tí ó jáde láti Jerusalẹmu ní jìnnà réré.

  9. Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo èyí ń lọ lọ́wọ́, èmi kò sí ní Jerusalẹmu, nítorí pé ní ọdún kejìlélọ́gbọ̀n Artasasta ọba Babeli ni mo padà tọ ọba lọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ṣe díẹ̀, mo gba ààyè lọ́dọ̀ọ rẹ̀.

  10. Mo sì padà sí Jerusalẹmu. Níhìn-ín ni mo ti mọ̀ nípa onírúurú ohun búburú tí Eliaṣibu ti ṣe ní ti pípèsè yàrá fún Tobiah nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run.

  11. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, mo rí àwọn ènìyàn ní Juda tí wọ́n ń fúntí ní ọjọ́ ìsinmi, tí wọ́n sì ń gbé ọkà wọlé, tí wọn ń di ẹrù lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pẹ̀lú wáìnì, èso àjàrà, ọ̀pọ̀tọ́ àti onírúurú ẹrù. Wọ́n sì ń kó gbogbo èyí wá sí Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi. Nítorí náà, mo kìlọ̀ fún wọn nípa títa oúnjẹ ní ọjọ́ náà.

  12. Àwọn ará Tire ti ń gbé nínú Jerusalẹmu ń gbé ẹja àti onírúurú ọjà wá fún títà ní ọjọ́ ìsinmi fún àwọn ènìyàn Jerusalẹmu àti fún àwọn ọmọ Juda.

  13. Nígbà tí ojú ọjọ́ ń bora ní ẹnu ibodè Jerusalẹmu, ṣáájú ọjọ́ ìsinmi, mo pàṣẹ pé kí a ti àwọn ìlẹ̀kùn, kí wọn má sì ṣí i títí tí ọjọ́ ìsinmi yóò fi kọjá. Mo yan àwọn ìránṣẹ́ mi láti ṣọ́ ẹnu ibodè, kí a má ba à lè gbé ẹrù kankan wọlé ní ọjọ́ ìsinmi.

  14. Síbẹ̀, àwọn tí ń tà àti àwọn tí ń rà sùn ẹ̀yìn odi Jerusalẹmu ní ẹ̀ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀mejì.

  15. ẹni tí Nebukadnessari ọba Babeli ti gbé lọ sí ìgbèkùn láti Jerusalẹmu, lára àwọn tí wọ́n kó ní ìgbèkùn pẹ̀lú ọba Jekoniah ọba Juda.

  16. Ṣe rere ní dídùn inú rẹ sí Sioni, ṣe rere; tún odi Jerusalẹmu mọ.

  17. Nítorí tẹmpili rẹ ni Jerusalẹmu àwọn ọba yóò mú ẹ̀bùn wá fún ọ.

  18. Saamu ti Asafu. Ọlọ́run, àwọn orílẹ̀-èdè ti wá ilẹ̀ ìní rẹ; wọ́n ti ba tẹmpili mímọ́ rẹ jẹ́, wọn di Jerusalẹmu kù sí òkìtì àlàpà.

  19. Wọ́n tu ẹ̀jẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí omi yí Jerusalẹmu ká, kò sì ṣí àwọn tí yóò sìn wọ́n.

  20. Kí a lè sọ orúkọ Olúwa ní Sioni àti ìyìn rẹ̀ ní Jerusalẹmu.

  21. nínú àgbàlá ilé Olúwa ní àárín rẹ̀, ìwọ Jerusalẹmu. Ẹ yin Olúwa.

  22. Ẹsẹ̀ wa yóò dúró ní ẹnu ibodè rẹ, ìwọ Jerusalẹmu.

  23. Jerusalẹmu, ìwọ tí a kọ́ bí ìlú tí o fi ara mọ́ra pọ̀ ṣọ̀kan.

  24. Gbàdúrà fún àlàáfíà Jerusalẹmu; àwọn tí ó fẹ́ ọ yóò ṣe rere.

  25. Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yí ènìyàn ká láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.