Fò sí àkóónú

Jerusalem

753 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jerusalem's

31.7700, 35.2300 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jerusalem

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Sioni, àwọn tí o kù ní Jerusalẹmu, ni a ó pè ní mímọ́, orúkọ àwọn ẹni tí a kọ mọ́ àwọn alààyè ní Jerusalẹmu.

  2. Olúwa yóò wẹ ẹ̀gbin àwọn obìnrin Sioni kúrò yóò sì fọ gbogbo àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ kúrò ní Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹ̀mí ìdájọ́ àti ẹ̀mí iná.

  3. “Ní ìsinsin yìí ẹ̀yin olùgbé Jerusalẹmu àti ẹ̀yin ènìyàn Juda ẹ ṣe ìdájọ́ láàrín èmi àti ọgbà àjàrà mi.

  4. Nígbà tí Ahasi ọmọ Jotamu ọmọ Ussiah jẹ́ ọba Juda, ọba Resini ti Aramu àti Peka ọmọ Remaliah ọba Israẹli gòkè wá láti bá Jerusalẹmu jà, ṣùgbọ́n wọn kò sì le è borí i rẹ̀.

  5. Òun yóò sì jẹ́ ibi mímọ́ ṣùgbọ́n fún ilé Israẹli méjèèjì ni yóò jẹ́, òkúta tí í mú ni kọsẹ̀ àti àpáta tí ó mú wọn ṣubú àti fún àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ni yóò jẹ́ tàkúté àti ìdẹ̀kùn.

  6. Gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ti gbá ìjọba àwọn òrìṣà mú, ìjọba tí ère rẹ̀ pọ̀ ju ti Jerusalẹmu àti Samaria lọ.

  7. Èmi kì yóò a bá Jerusalẹmu wí àti àwọn ère rẹ̀?’ ” Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣe sí Samaria àti àwọn ère rẹ̀?

  8. Nígbà tí Olúwa ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ sí òkè Sioni àti Jerusalẹmu, yóò sọ wí pé, “Èmi yóò fi ìyà jẹ ọba Asiria nítorí gààrù àyà rẹ̀ àti ìgbéraga ojú rẹ̀.

  9. Ní ọjọ́ yìí, wọn yóò dúró ní Nobu wọn yóò kan sáárá, ní òkè ọmọbìnrin Sioni ní òkè Jerusalẹmu.

  10. Ìwọ ka àwọn ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu ó sì wó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé lulẹ̀ láti fún ògiri lágbára.

  11. Èmi yóò fi aṣọ rẹ wọ̀ ọ́, n ó sì so ẹ̀wọ̀n rẹ mọ́ ọn ní ọrùn, èmi ó sì gbé àṣẹ rẹ lé e lọ́wọ́. Òun yó sì jẹ́ baba fún gbogbo olùgbé e Jerusalẹmu àti fún ilé e Juda.

  12. A ó rẹ òṣùpá sílẹ̀, ojú yóò sì ti oòrùn; nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò jẹ ọba ní orí òkè Sioni àti ní Jerusalẹmu, àti níwájú àwọn àgbàgbà rẹ ní ògo.

  13. Àti ní ọjọ́ náà, a ó fun fèrè ńlá kan. Gbogbo àwọn tí ń ṣègbé lọ ní Asiria àti àwọn tí ń ṣe àtìpó ní Ejibiti yóò wá sin Olúwa ní òkè mímọ́ ní Jerusalẹmu.

  14. Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn, tí ń jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní Jerusalẹmu.

  15. Ẹ̀yin ènìyàn Sioni, tí ń gbé ní Jerusalẹmu, ìwọ kì yóò sọkún mọ́. Báwo ni àánú rẹ̀ yóò ti pọ̀ tó nígbà tí ìwọ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́! Bí ó bá ti gbọ́, òun yóò dá ọ lóhùn.

  16. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹyẹ ti ń rábàbà lókè Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bo Jerusalẹmu, Òun yóò dáàbò bò ó, yóò sì tú u sílẹ̀ Òun yóò ré e kọjá yóò sì gbà á sílẹ̀.”

  17. Àpáta rẹ yóò kọjá lọ fún ẹ̀rù; àwọn olórí rẹ yóò bẹ̀rù asia náà,” ni Olúwa wí, ẹni tí iná rẹ̀ ń bẹ ní Sioni, ẹni tí ìléru rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu.

  18. Gbójú sókè sí Sioni, ìlú àjọ̀dún wa, ojú rẹ yóò rí Jerusalẹmu, ibùgbé àlàáfíà n nì, àgọ́ tí a kò ní yí padà; àwọn òpó rẹ̀ ni a kì yóò fàtu tàbí èyíkéyìí nínú okùn rẹ̀ kí já.

  19. Lẹ́yìn náà, ọba Asiria rán olórí ogun rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ-ogun láti Lakiṣi sí ọba Hesekiah ní Jerusalẹmu. Nígbà tí ọ̀gágun náà dúró níbi ojúṣàn adágún ti apá òkè, ní ojú ọ̀nà sí pápá alágbàfọ̀,

  20. Bí o bá sì sọ fún mi pé, “Àwa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run wa,” kì í ṣe òun ni Hesekiah ti mú àwọn ibi gíga àti pẹpẹ rẹ̀ kúrò, tí ó sì wí fún Juda àti Jerusalẹmu pé, “Ẹ̀yin gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ yìí”?

  21. Èwo nínú àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ló ha ti dáàbò bo ilẹ̀ ẹ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi? Báwo ni Olúwa ṣe wá le gba Jerusalẹmu kúrò lọ́wọ́ mi?”

  22. “Ẹ sọ fún Hesekiah ọba Juda pé: Má ṣe jẹ́ kí òrìṣà tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tàn ọ́ jẹ nígbà tí ó sọ pé, ‘A kì yóò jọ̀wọ́ Jerusalẹmu fún ọba Asiria.’

  23. èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀: “Wúńdíá ọmọbìnrin Sioni ti kẹ́gàn rẹ, ó sì ti fi ọ ṣe ẹlẹ́yà. Ọmọbìnrin Jerusalẹmu ti mi orí rẹ̀ bí ó ti ń sálọ.

  24. Nítorí láti Jerusalẹmu ni àwọn àṣẹ́kù yóò ti wá, àti láti òkè Sioni ni ikọ̀ àwọn tí ó sálà. Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú èyí ṣẹ.

  25. Sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fún Jerusalẹmu kí o sì kéde fún un pé iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ ti parí, pé à ti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, pé ó ti rí i gbà láti ọwọ́ Olúwa ìlọ́po méjì fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.