Fò sí àkóónú

Egypt

561 verses · 4 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Egyptian, Egyptians, Egyptian's

30.1000, 31.3300 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Egypt

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ìwọ fúnra à rẹ mọ bí a ṣe gbé ní Ejibiti àti bí a ṣe kọjá láàrín àwọn orílẹ̀-èdè nílẹ̀ ibí yìí.

  2. Ìdáhùn yóò sì jẹ́ báyìí: “Nítorí tí ènìyàn yìí kọ Olúwa Ọlọ́run baba wọn sílẹ̀, májẹ̀mú tí ó ti bá wọn dá nígbà tí ó mú wọn jáde wá láti Ejibiti.

  3. tí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tí Olúwa rán an láti lọ ṣe ní Ejibiti sí Farao àti sí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ àti sí gbogbo ilẹ̀ náà.

  4. Àwa ti gbọ́ bí Olúwa ti mú omi Òkun Pupa gbẹ níwájú u yín nígbà tí ẹ̀yin jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, àti ohun tí ẹ̀yin ṣe sí Sihoni àti Ogu, àwọn ọba méjèèjì ti Amori ti ìlà-oòrùn Jordani, tí ẹ̀yin parun pátápátá.

  5. Wàyí o, ìdí tí Joṣua fi kọ wọ́n nílà nìyìí. Gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó ti Ejibiti jáde wá, gbogbo àwọn ọkùnrin ogun kú ní aginjù ní ọ̀nà lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.

  6. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, gbogbo àwọn ọkùnrin tó jáde láti Ejibiti ni a ti kọ ní ilà, síbẹ̀ gbogbo ènìyàn tí a bí nínú aginjù lẹ́yìn tí wọ́n jáde ní Ejibiti ni wọn kò kọ ní ilà.

  7. Àwọn ará Israẹli rìn ní aginjù fún ogójì ọdún títí gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó tó ogun n jà nígbà tí wọ́n kúrò ni Ejibiti fi kú, nítorí wọn kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa. Nítorí Olúwa ti búra fún wọn pé wọn kò ní rí ilẹ̀ tí òun ṣe ìlérí fún àwọn baba wọn láti fi fun wa, ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti fún oyin.

  8. Nígbà náà ní Olúwa wí fún Joṣua pé, “Ní òní ni mo yí ẹ̀gàn Ejibiti kúrò ní orí yín.” Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ ibẹ̀ ní Gilgali títí ó fi di òní yìí.

  9. Wọ́n sì dáhùn pé, “Ní ilẹ̀ òkèèrè ní àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wá, nítorí orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ. Nítorí tí àwa ti gbọ́ òkìkí rẹ àti ohun gbogbo tí ó ti ṣe ní Ejibiti,

  10. láti odò Ṣihori ní ìlà-oòrùn Ejibiti sí agbègbè Ekroni ìhà àríwá, gbogbo rẹ̀ ni a kà kún Kenaani (agbègbè ìjòyè Filistini márùn-ún ní Gasa, Aṣdodu, Aṣkeloni, Gitti àti Ekroni; ti àwọn ará Affimu);

  11. àti fún Isaaki ni mo fún ní Jakọbu àti Esau, mo sì fún Esau ní ilẹ̀ orí òkè Seiri ní ìní, ṣùgbọ́n Jakọbu àti àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti.

  12. “ ‘Nígbà náà ni mo rán Mose àti Aaroni, mo sì yọ Ejibiti lẹ́nu ní ti nǹkan tí mo ṣe níbẹ̀, mo sì mú yín jáde.

  13. Nígbà tí mo mú àwọn baba yín jáde kúrò ní Ejibiti, ẹ wá sí Òkun, àwọn ará Ejibiti lépa wọn pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin títí ó fi dé Òkun Pupa.

  14. Ṣùgbọ́n wọ́n ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́, ó sì fi òkùnkùn sí àárín yín àti àwọn ará Ejibiti, ó sì mú òkun wá sí orí wọn; ó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ẹ sì fi ojú yín rí ohun tí mo ṣe sí àwọn ará Ejibiti. Lẹ́yìn náà ẹ sì gbé ní aginjù fún ọjọ́ pípẹ́.

  15. “Nísinsin yìí ẹ bẹ̀rù Olúwa, kí ẹ sì máa sìn ín ní òtítọ́ àti òdodo. Kí ẹ sì mú òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò Eufurate àti ní Ejibiti kúrò, kí ẹ sì máa sin Olúwa.

  16. Nítorí Olúwa Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni ó gba àwọn baba ńlá wa là kúrò ní Ejibiti, ní oko ẹrú. Òun ni Ọlọ́run tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá níwájú àwọn ọmọ Israẹli. Ó pa wá mọ́ nínú gbogbo ìrìnàjò wa àti ní àárín gbogbo orílẹ̀-èdè tí a là kọjá.

  17. Egungun Josẹfu, èyí tí àwọn ọmọ Israẹli kó kúrò ní Ejibiti, ni wọ́n sin ní Ṣekemu ní ìpín ilẹ̀ tí Jakọbu rà fún ọgọ́rùn-ún fàdákà ní ọwọ́ Hamori, baba Ṣekemu. Èyí sì jẹ́ ilẹ̀ ìní àwọn ọmọ Josẹfu.

  18. Ní ọjọ́ kan angẹli Olúwa dìde kúrò láti Gilgali lọ sí Bokimu ó sì wí pé, “Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá, èmi sì síwájú yín wá sí ilẹ̀ tí mo ti búra láti fi fún àwọn baba ńlá yín. Èmi sì wí pé, ‘Èmi kì yóò yẹ májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín,

  19. Wọ́n kọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀, ẹni tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, wọ́n ń tọ àwọn òrìṣà lẹ́yìn, wọ́n sì ń sin àwọn oríṣìíríṣìí òrìṣà àwọn ará ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú Olúwa bínú,

  20. Olúwa fi etí sí igbe wọn, ó sì rán wòlíì kan sí wọn, ẹni tí ó wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí: mo mú yín gòkè ti Ejibiti wá, láti oko ẹrú.

  21. Gideoni dáhùn pé, “Alàgbà, bí Olúwa bá wà pẹ̀lú wa, kí ló dé tí gbogbo ìwọ̀nyí fi ń ṣẹlẹ̀ sí wa? Níbi gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ tí àwọn baba wa ròyìn rẹ̀ fún wa nígbà tí wọ́n wí pé, ‘Olúwa kò ha mú wa gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá?’ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Olúwa ti kọ̀ wá sílẹ̀, ó sì ti fi wá lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́.”

  22. Ọba àwọn Ammoni dá àwọn oníṣẹ́ Jefta lóhùn pé, “Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli jáde ti Ejibiti wá. Wọ́n gba ilẹ̀ mi láti Arnoni dé Jabbok, àní dé Jordani, nítorí náà dá wọn padà lọ ní àlàáfíà àti ní pẹ̀lẹ́ kùtù.”

  23. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Ejibiti àwọn ọmọ Israẹli la aginjù kọjá lọ sí ọ̀nà Òkun Pupa wọ́n sì lọ sí Kadeṣi.

  24. Gbogbo ẹni tí ó rí i sì wí pé, “A kò ti rí i, bẹ́ẹ̀ a kò tí ì ṣe irú nǹkan yìí rí, kì í ṣe láti ọjọ́ tí Israẹli ti jáde tí Ejibiti wá títí di òní olónìí. Ẹ rò ó wò, ẹ gbìmọ̀ràn, kí ẹ sọ fún wa ohun tí a yóò ṣe!”

  25. Ènìyàn Ọlọ́run kan tọ Eli wá, ó sì wí fún un pé, “Báyìí ni Olúwa wí, ‘Èmi fi ara mi hàn ní gbangba fún ilé baba rẹ, nígbà tí wọ́n ń bẹ ní Ejibiti nínú ilé Farao.