Fò sí àkóónú

Pharaoh

138 ẹsẹ

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Pharaoh

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olúwa sé ọkàn Farao ọba Ejibiti le, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn ọmọ Israẹli ti ń jáde lọ ní àìbẹ̀rù.

  2. Àwọn ará Ejibiti ń lépa wọn pẹ̀lú gbogbo ẹṣin kẹ̀kẹ́ ogun Farao àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀, wọ́n sì lé wọn bá ni ibi tí wọ́n pa àgọ́ sí lẹ́bàá òkun ní ìhà Pi-Hahirotu, ni òdìkejì Baali-Ṣefoni.

  3. Bí Farao ti súnmọ́ tòsí ọ̀dọ̀ wọn, àwọn ọmọ Israẹli gbé ojú wọn sókè, wọn sì rí àwọn ará Ejibiti tó súnmọ́ wọn. Ẹ̀rù ńlá sì bá àwọn ará Israẹli, wọ́n kígbe sókè sí Olúwa.

  4. Nígbà náà ni èmi yóò sé ọkàn àwọn ará Ejibiti le, wọn yóò sì máa lépa wọn; Èmi yóò gba ògo fún ara mi lórí Farao; lórí gbogbo ogun rẹ̀, lórí kẹ̀kẹ́ ogun àti lórí àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.

  5. Àwọn ará Ejibiti yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa nígbà ti èmi bá gba ògo fún ara mi lórí Farao: lórí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti lórí àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.”

  6. Àwọn ará Ejibiti sì ń lépa wọn, gbogbo ẹṣin Farao, kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ wọ́ tọ̀ wọ́n lọ sínú òkun.

  7. Omi òkun sì ya padà, ó sì bo kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin: àní, gbogbo ọmọ-ogun Farao tiwọn wọ inú òkun tọ àwọn ọmọ Israẹli lọ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó yè.

  8. kẹ̀kẹ́ ogun Farao àti ogun rẹ̀ ni ó mú wọ inú Òkun. Àwọn ọmọ-ogun Farao tó jáfáfá jùlọ ni ó rì sínú Òkun Pupa.

  9. Nígbà ti ẹṣin Farao, kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ wọ inú Òkun, Olúwa mú kí omi òkun padà bò wọ́n mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli rìn lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ la òkun kọjá.

  10. Èkejì ń jẹ́ Elieseri; ó wí pé, “Ọlọ́run baba mi ni alátìlẹ́yìn mi, ó sì gbà mí là kúrò lọ́wọ́ idà Farao.”

  11. Mose sọ fún àna rẹ̀ nípa ohun gbogbo ti Olúwa tí ṣe sí Farao àti àwọn ará Ejibiti nítorí Israẹli. Ó sọ nípa gbogbo ìṣòro tí wọn bá pàdé ní ọ̀nà wọn àti bí Olúwa ti gbà wọ́n là.

  12. Jetro sì wí pé, “Ìyìn ni fún Olúwa, ẹni tí ó gba yín là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti àti lọ́wọ́ Farao, ẹni tí ó sì gba àwọn ènìyàn là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti.

  13. Sọ fún un pé: “Ẹrú Farao ní ilẹ̀ Ejibiti ni wá tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n Olúwa fi ọwọ́ agbára ńlá yọ wá jáde lóko ẹrú Ejibiti.

  14. Lójú wa ni Olúwa tí ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu: tí ó lágbára tí ó sì ba ni lẹ́rù: lórí Ejibiti àti Farao, àti gbogbo ènìyàn rẹ̀.

  15. Ṣùgbọ́n torí Olúwa fẹ́ràn yín, tí ó sì pa ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín mọ́ ni ó ṣe fi ọwọ́ agbára ńlá mú un yín jáde tí ó sì rà yín padà nínú oko ẹrú, àti láti ọwọ́ agbára Farao ọba Ejibiti.

  16. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, ẹ rántí dáradára ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín ṣe sí Farao àti gbogbo Ejibiti.

  17. iṣẹ́ àmì rẹ̀ àti ohun tí ó ṣe ní àárín àwọn ará Ejibiti, sí Farao ọba Ejibiti àti gbogbo orílẹ̀-èdè rẹ̀.

  18. Mose pàṣẹ fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ó sì wí fún wọn wí pé, ojú rẹ ti rí gbogbo ohun tí Olúwa ti ṣe ní Ejibiti sí Farao àti, sí gbogbo àwọn ìjòyè e rẹ̀ àti sí ilẹ̀ ẹ rẹ̀.

  19. tí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tí Olúwa rán an láti lọ ṣe ní Ejibiti sí Farao àti sí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ àti sí gbogbo ilẹ̀ náà.

  20. Ènìyàn Ọlọ́run kan tọ Eli wá, ó sì wí fún un pé, “Báyìí ni Olúwa wí, ‘Èmi fi ara mi hàn ní gbangba fún ilé baba rẹ, nígbà tí wọ́n ń bẹ ní Ejibiti nínú ilé Farao.

  21. Kí ni ó dé tí ẹ fi ń sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Ejibiti àti Farao ti ṣe? Nígbà tí ó fi ọwọ́ líle mú wọn, ṣé wọn kò rán àwọn ọmọ Israẹli jáde kí wọn kí ó lè lọ ní ọ̀nà wọn?

  22. Solomoni sì bá Farao ọba Ejibiti dá àna, ó sì fẹ́ ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìyàwó. Ó sì mú un wá sí ìlú Dafidi títí tí ó fi parí kíkọ́ ààfin rẹ̀ àti tẹmpili Olúwa, àti odi tí ó yí Jerusalẹmu ká.

  23. Ààfin rẹ̀ níbi tí yóò sì gbé wà ní àgbàlá lẹ́yìn ààfin, irú kan náà ni wọ́n. Solomoni sì kọ́ ààfin tí ó rí bí gbàngàn yìí fún ọmọbìnrin Farao tí ó ní ní aya.

  24. Lẹ́yìn ìgbà tí ọmọbìnrin Farao ti gòkè láti ìlú Dafidi wá sí ààfin tí Solomoni kọ́ fún un, nígbà náà ni ó kọ́ Millo.

  25. Arábìnrin Tapenesi bí ọmọkùnrin kan fún un tí à ń pe orúkọ rẹ̀ ní Genubati, ẹni tí Tapenesi tọ́ dàgbà ní ààfin ọba. Níbẹ̀ ni Genubati ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ Farao fúnra rẹ̀.