Fò sí àkóónú

Levi

64 ẹsẹ · 18 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Levi

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Èmi kó wọn jọ pọ̀ si etí odò ti ń sàn lọ sí Ahafa, a pàgọ́ síbẹ̀ fún odidi ọjọ́ mẹ́ta, nígbà ti mo wo àárín àwọn ènìyàn àti àárín àwọn àlùfáà, ń kò rí ọmọ Lefi kankan níbẹ̀.

  2. Nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run wa wà lára wa, wọ́n sì mú Ṣerebiah wá fún wa, ẹni tí ó kún ojú òsùwọ̀n láti ìran Mahili, ọmọ Lefi, ọmọ Israẹli, àti àwọn ọmọ Ṣerebiah àti àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n jẹ́ ọkùnrin méjìdínlógún.

  3. Àwọn ènìyàn Israẹli, àti àwọn ọmọ Lefi gbọdọ̀ mú ọrẹ oúnjẹ, wáìnì tuntun àti òróró wá sí yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí níbi tí a pa ohun èlò ibi mímọ́ mọ́ sí àti ibi tí àwọn àlùfáà tí ń ṣe ìránṣẹ́ lọ́wọ́, àwọn aṣọ́nà àti àwọn akọrin máa ń dúró sí. “Àwa kì yóò gbàgbé tàbí ṣe àìbìkítà nípa ilé Ọlọ́run wa.”

  4. Àwọn olórí ìdílé láàrín àwọn ọmọ Lefi títí di àkókò Johanani ọmọ Eliaṣibu ni a kọ sílẹ̀ nínú ìwé ìtàn.

  5. Ẹ̀yin ará ilé Lefi, fi ìbùkún fún Olúwa; ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, fi ìbùkún fún Olúwa.

  6. Iyàrá ti iwájú rẹ̀ ti o wà níhà àríwá, wà fún àwọn àlùfáà, àwọn ti ń bojútó pẹpẹ náà, àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Sadoku nínú àwọn ọmọ Lefi, tí wọ́n ń súnmọ́ Olúwa láti ṣe ìránṣẹ́ fún un.”

  7. ẹnu-ọ̀nà ìlú ńlá náà ní àwa yóò fi orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli pè. Àwọn ọ̀nà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ní ìhà àríwá ní yóò jẹ́ ọ̀nà tí Reubeni, ọ̀nà tí Juda ọ̀nà tí Lefi.

  8. Ìdílé Lefi lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀; ìdílé Ṣimei lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀.

  9. Ẹ̀yin ó sì mọ̀ pé, èmi ni ó ti rán òfin yìí sí yín, kí májẹ̀mú mi pẹ̀lú Lefi lè tẹ̀síwájú,” ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  10. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yapa kúrò ní ọ̀nà náà; ẹ̀yin sì ti fi ìkọ́ni yín mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kọsẹ̀; ẹ̀yin ti ba májẹ̀mú tí mo da pẹ̀lú Lefi jẹ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  11. Òun yóò sì jókòó bí ẹni tí n yọ́, tí ó sì ń da fàdákà; yóò wẹ àwọn ọmọ Lefi mọ́, yóò sì tún wọn dàbí wúrà àti fàdákà, kí wọn bá a lè mú ọrẹ òdodo wá fún Olúwa,

  12. Àti nítòótọ́ àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Lefi, tí o gba oyè àlùfáà, wọ́n ní àṣẹ láti máa gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí òfin, èyí yìí, lọ́wọ́ àwọn arákùnrin wọn, bí ó tilẹ̀ ti jẹ́ pé, wọn ti inú Abrahamu jáde.

  13. Àti bí a ti lè wí, Lefi pàápàá tí ń gba ìdámẹ́wàá, ti san ìdámẹ́wàá nípasẹ̀ Abrahamu.

  14. Láti inú ẹ̀yà Simeoni a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). Láti inú ẹ̀yà Lefi a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). Láti inú ẹ̀yà Isakari a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000).