Fò sí àkóónú

Jesus

3,872 ẹsẹ · 6 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jesus Christ, Immanuel, Emmanuel, Christ

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jesus

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àti níhìn-ín yìí pẹ̀lú ó wí pé, “Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi.”

  2. Àti pé, ó yan ọjọ́ kan, ó wí nínú ìwé Dafidi pé, “Lónìí,” lẹ́yìn ìgbà pípẹ́ bẹ́ẹ̀; bí a tí wí níṣàájú, “Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ má ṣe sé ọkàn yín le.”

  3. Nítorí, ìbá ṣe pé Joṣua tí fún wọn ní ìsinmi, òun kì bá tí sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ìsinmi mìíràn lẹ́yìn náà,

  4. Nítorí pé ẹni tí ó ba bọ́ sínú ìsinmi rẹ̀, òun pẹ̀lú sinmi kúrò nínú iṣẹ́ tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti sinmi kúrò nínú iṣẹ́ tirẹ̀.

  5. Kò sí ẹ̀dá kan tí kò farahàn níwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun gbogbo ni ó wà níhòhò tí a sì ṣípáyà fún ojú rẹ̀, níwájú ẹni tí àwa yóò jíyìn.

  6. Ǹjẹ́ bí a ti ní olórí àlùfáà ńlá kan, tí ó ti la àwọn ọ̀run kọjá lọ, Jesu Ọmọ Ọlọ́run, ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ wa mú ṣinṣin.

  7. Nítorí a kò ní olórí àlùfáà tí kò lè ṣàì ba ni kẹ́dùn nínú àìlera wa, ẹni tí a ti dánwò lọ́nà gbogbo gẹ́gẹ́ bí àwa, ṣùgbọ́n òun kò dẹ́ṣẹ̀.

  8. Bẹ́ẹ̀ ni Kristi pẹ̀lú kò sì ṣe ara rẹ̀ lógo láti jẹ́ olórí àlùfáà; bí kò ṣe ẹni tí o wí fún ún pé, “Ìwọ ni ọmọ mi, lónìí ni mo bí ọ.”

  9. Bí ó ti wí pẹ̀lú ní ibòmíràn pé, “Ìwọ ni àlùfáà títí láé ní ipasẹ̀ Melkisedeki.”

  10. Ní ìgbà ọjọ́ Jesu nínú ayé, ó fi ìkérora rara àti omijé gbàdúrà, tí ó sì bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí ó lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú, a sì gbóhùn rẹ̀ nítorí ó ní ẹ̀mí ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ̀.

  11. Bí òun tilẹ̀ ń ṣe Ọmọ Ọlọ́run, síbẹ̀ ó kọ́ ìgbọ́ran nípa ohun tí ó jìyà rẹ̀.

  12. Bí a sì ti sọ ọ di pípé, o wa di orísun ìgbàlà àìnípẹ̀kun fún gbogbo àwọn tí ó ń gbọ́ tirẹ̀,

  13. tí a yàn ní olórí àlùfáà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ní ipasẹ̀ Melkisedeki.

  14. Nítorí náà, ó yẹ kí á fi àwọn ẹ̀kọ́ ìgbà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Kristi sílẹ̀, kí á tẹ̀síwájú nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí yóò mú wa dàgbàsókè ní pípé. Láìtún ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ máa tẹnumọ́ ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ bí i ìrònúpìwàdà kúrò nínú òkú iṣẹ́ àti ìgbàgbọ́ nípa ti Ọlọ́run,

  15. láti tún sọ wọ́n di ọ̀tun sí ìrònúpìwàdà bí wọn bá ṣubú kúrò; nítorí tí wọ́n tún kan Ọmọ Ọlọ́run mọ́ àgbélébùú sí ara wọn lọ́tun, wọ́n sì dójútì í ní gbangba.

  16. níbi tí Jesu, aṣáájú wa ti wọ̀ lọ fún wa, òun sì ni a fi jẹ alábojútó àlùfáà títí láé ní ipasẹ̀ Melkisedeki.

  17. Láìní baba, láìní ìyá, láìní ìtàn ìran, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tàbí òpin ọjọ́ ayé; ṣùgbọ́n a ṣe é bí Ọmọ Ọlọ́run; ó wà ní àlùfáà títí.

  18. Nítorí ẹni tí à ń sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀ jẹ́ ẹ̀yà mìíràn, láti inú èyí tí ẹnikẹ́ni kò tì jọ́sìn rí níbi pẹpẹ.

  19. Nítorí ó hàn gbangba pé láti inú ẹ̀yà Juda ni Olúwa wa ti dìde; nípa ẹ̀yà yìí Mose kò sọ ohunkóhun ní ti àwọn àlùfáà.

  20. Nítorí a jẹ́rìí pé: “Ìwọ ni àlùfáà títí láé ní ipasẹ̀ ti Melkisedeki.”

  21. Níwọ́n bí ó sì ti ṣe pé kì í ṣe ní àìbúra ni. Nítorí àwọn àlùfáà tẹ́lẹ̀ jẹ oyè láìsí ìbúra,

  22. ṣùgbọ́n ti òun jẹ́ pẹ̀lú ìbúra nígbà tí Ọlọ́run wí fún un pé, “Olúwa búra, kí yóò sì yí padà: ‘Ìwọ ni àlùfáà kan títí láé.’ ”

  23. Níwọ́n bẹ́ẹ̀ ni Jesu ti di onígbọ̀wọ́ májẹ̀mú tí ó dára jù.

  24. Ṣùgbọ́n òun, nítorí tí o wà títí láé, ó ní oyè àlùfáà tí a kò lè rọ̀ ní ipò.

  25. Nítorí náà ó sì le gbà wọ́n là pẹ̀lú títí dé òpin, ẹni tí ó bá tọ Ọlọ́run wá nípasẹ̀ rẹ̀, nítorí tí o ń bẹ láààyè títí láé láti máa bẹ̀bẹ̀ fún wọn.