Fò sí àkóónú

Jesus

3,872 ẹsẹ · 6 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jesus Christ, Immanuel, Emmanuel, Christ

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jesus

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ní àkótán, ara mí, ẹ jẹ́ alágbára nínú Olúwa, àti nínú agbára ipá rẹ̀.

  2. Tikiku, arákùnrin olùfẹ́ àti ìránṣẹ́ olóòtítọ́ nínú Olúwa yóò sọ ohun gbogbo dí mí mọ̀ fún yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè mọ̀ bí nǹkan ti rí fún mí àti bí mo tí ń ṣe sí.

  3. Àlàáfíà fún àwọn ará, àti ìfẹ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wà, àti Olúwa wà Jesu Kristi.

  4. Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó fẹ́ Olúwa wa Jesu Kristi ni àìṣẹ̀tàn.

  5. Paulu àti Timotiu, àwọn ìránṣẹ́ Jesu Kristi, Sí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ nínú Kristi Jesu tí ó wà ní Filipi, pẹ̀lú àwọn alábojútó àti àwọn díákónì:

  6. Oore-ọ̀fẹ́ sí yín, àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Olúwa wa Jesu Kristi.

  7. Ohun kan yìí sá à dá mi lójú pé, ẹni tí ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere nínú yín, yóò ṣe àṣepé rẹ̀ títí di ọjọ́ náà tí Jesu Kristi yóò dé.

  8. Nítorí Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí mi, bí mo ti ń ṣàfẹ́rí yín gidigidi nínú ìfẹ́ Jesu Kristi.

  9. kí ẹ̀yin kí ó lè ní òye ohun tí ó dára jùlọ; kí ó sì jásí òdodo àti aláìjẹ́ ohun ìkọ̀sẹ̀ títí di ọjọ́ dídé Jesu Kristi,

  10. lẹ́yìn ìgbà ti ẹ ti kún fún àwọn ìwà òdodo láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, fún ògo àti ìyìn Ọlọ́run.

  11. Nítorí ìdí èyí, ó ti hàn gbangba sí gbogbo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààfin àti sí àwọn ẹlòmíràn wí pé mo wà nínú ìdè fún Kristi.

  12. Nítorí ìdè mi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará nínú Olúwa ni a ti mú lọ́kàn le láti sọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí i pẹ̀lú ìgboyà àti láìbẹ̀rù.

  13. Òtítọ́ ni pé àwọn ẹlòmíràn tilẹ̀ ń fi ìjà àti ìlara wàásù Kristi, ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn sì ń fi inú rere ṣe é.

  14. Àwọn kan ń fi ìjà wàásù Kristi, kì í ṣe pẹ̀lú òtítọ́ inú, wọ́n ń gbèrò láti fi ìpọ́njú kún ìdè mi.

  15. Kí ló tún kù? Kìkì í pé níbi gbogbo, ìbá à ní ìfẹ̀tànṣe tàbí ni ti òtítọ́ a sá à n wàásù Kristi, èmi sì ń yọ̀ nítorí èyí. Nítòótọ́, èmi ó sì máa yọ̀,

  16. nítorí tí mo mọ̀ pé èyí ni yóò yọrí sí ìgbàlà fún mi láti inú àdúrà yín wá, àti ìfikún ẹ̀mí Jesu Kristi.

  17. Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn àti ìrètí mi pé kí ojú kí ó má ṣe ti mi ní ohunkóhun, ṣùgbọ́n kí èmi kí ó le máa ni ìgboyà ní ìgbà gbogbo àti nísinsin yìí, kí a lè ti ipasẹ̀ mi gbé Kristi ga lára mi, ìbá à ṣe pé mo wà láààyè, tàbí mo kú.

  18. Nítorí, ní ti èmi, láti wa láààyè jẹ́ Kristi, láti kú pẹ̀lú sì jẹ́ èrè fún mi.

  19. Ṣùgbọ́n èmi n ṣiyèméjì, nítorí ti èmi fẹ́ láti lọ kúrò nínú ayé yìí, láti wà lọ́dọ̀ Kristi; nítorí ó dára púpọ̀ jù:

  20. kí ìṣògo yín kí ó lè di púpọ̀ gidigidi nínú Jesu Kristi, àti nínú mi nípa ìpadà wá mi sọ́dọ̀ yín.

  21. Ohun yówù kó ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ kí ìgbé ayé yín ri gẹ́gẹ́ bí ìyìnrere Kristi: pé yálà bi mo tilẹ̀ wá wò yín, tàbí bí èmi kò wá, kí èmi kí ó lè máa gbúròó bí ẹ ti ń ṣe, pé ẹ̀yin dúró ṣinṣin nínú Ẹ̀mí kan, ẹ̀yin jùmọ̀ jìjàkadì nítorí ìgbàgbọ́ ìyìnrere, pẹ̀lú ọkàn kan.

  22. Nítorí tí a ti fún yin ni àǹfààní, kì í ṣe láti gba Kristi gbọ́ nìkan, ṣùgbọ́n láti jìyà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú.

  23. Bí ìwọ bá ní ìmúlọ́kànle nítorí pé ìwọ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi, bi ìtùnú kan bá wà nínú ìfẹ́ rẹ̀, bí ìdàpọ̀ Ẹ̀mí kan bá wà, bí ìyọ́nú àti ìṣeun bá wà,

  24. Nínú ìbáṣepọ̀ yin pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ẹ ni irú ìlépa ọkàn náà bí ti Kristi Jesu.

  25. Ṣùgbọ́n ó bọ́ ògo rẹ̀ sílẹ̀, ó sì mú àwọ̀ ìránṣẹ́, a sì ṣe é ni àwòrán ènìyàn.