God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Bí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, má ṣe lọ́ra láti san án, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ, o sì máa jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀.
Rí i dájú pé o ṣe ohunkóhun tí o bá ti ètè rẹ jáde, nítorí pé ìwọ fi tinútinú rẹ jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú ẹnu ara rẹ.
nígbà náà ni ọkọ, tí ó ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, kò gbọdọ̀ fẹ́ ẹ mọ́ lẹ́yìn tí ó ti di àìmọ́. Nítorí èyí ni ìríra níwájú Olúwa. Má ṣe mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sórí ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ bí ogún.
Rántí ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ṣe sí Miriamu lójú ọ̀nà lẹ́yìn ìgbà tí o jáde kúrò ní Ejibiti.
Dá aṣọ ìlekè rẹ padà ní àṣálẹ́ kí ó bá à le sùn lórí i rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, ó sì máa jásí ìwà òdodo níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ.
San owó iṣẹ́ rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà kí ó tó di àṣálẹ́, nítorí ó jẹ́ tálákà, ó sì gbẹ́kẹ̀lé e bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ ó lè ké pe Olúwa sí ọ, o sì máa gba ìdálẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀.
Rántí pé o jẹ́ ẹrú ní Ejibiti tí Olúwa Ọlọ́run rẹ sì gbà ọ́ níbẹ̀. Ìdí nìyí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ṣe èyí.
Nígbà tí o bá ń kórè oko rẹ tí o sì fojú fo ìtí kan, má ṣe padà lọ mú u. Fi í kalẹ̀ fún àwọn àlejò, aláìní baba àti opó, kí Olúwa Ọlọ́run rẹ lè bùkún fún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ.
O gbọdọ̀ ní ìtẹ̀wọ̀n àti òsùwọ̀n pípé àti ti òtítọ́ nítorí náà kí ìwọ kí ó lè pẹ́ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún ọ.
Nítorí Olúwa Ọlọ́run kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe nǹkan wọ̀nyí, àní ẹnikẹ́ni tí ń ṣe àìṣòdodo.
Nígbà tí àárẹ̀ mú un yín tí agara sì dá a yín, wọ́n pàdé e yín ní ọ̀nà àjò o yín, wọ́n gé àwọn tí ó rẹ̀yìn kúrò, wọn kò ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.
Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá fún un yín ní ìsinmi lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá yín tí ó yí i yín ká ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run ń fi fún yín láti ni ní ìní, ẹ̀yin yóò sì pa ìrántí Amaleki rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run. Má ṣe gbàgbé.
Nígbà tí ìwọ bá wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní tí ìwọ sì ti jogún, tí ìwọ sì ti ń gbé níbẹ̀,
mú díẹ̀ nínú ohun tí o pèsè láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fi fún ọ, kó wọn sínú agbọ̀n. Nígbà náà kí o lọ sí ibi tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibi tí orúkọ rẹ̀ yóò máa gbé.
Kí o sì sọ fun àlùfáà tí ó wà ní ibi iṣẹ́ ní àsìkò náà, pé, “Mo sọ ọ́ di mí mọ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pé mo ti wá sí ilẹ̀ tí Olúwa búra fún àwọn baba wa.”
Àlùfáà yóò gbé agbọ̀n náà kúrò ní ọwọ́ rẹ, yóò sì gbé e kalẹ̀ níwájú pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ.
Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní iwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ pé, “Baba mi jẹ́ alárìnkiri ará Aramu, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Ejibiti pẹ̀lú ènìyàn díẹ̀, ó sì ń gbé níbẹ̀, ó sì wá di orílẹ̀-èdè olókìkí, alágbára, tí ó kún fún ọ̀pọ̀ ènìyàn.
Nígbà náà ni a kégbe pe Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wa, Olúwa sì gbọ́ ohùn wa, ó sì rí ìrora, làálàá àti ìnira wa.
Nígbà náà ni Olúwa mú wa jáde wá láti Ejibiti pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà, pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá àti iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu.
Ó mú wa wá síbí, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin;
àti pé ní báyìí, mo mú àkọ́so ilẹ̀ tí ìwọ Olúwa ti fún mi wá.” Ìwọ yóò gbé agbọ̀n náà síwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì wólẹ̀ níwájú u rẹ̀.
Ìwọ àti àwọn ọmọ Lefi àti àjèjì láàrín yín yóò máa yọ̀ nínú gbogbo oore tí Olúwa ti fi fún ọ àti fún àwọn ará ilé rẹ.
Nígbà náà ní kí o wí fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pé, “Èmi ti mú ohun mímọ́ kúrò nínú ilé mi, èmi sì ti fi fún àwọn Lefi, àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba àti àwọn opó, gẹ́gẹ́ bí ohun gbogbo tí ìwọ ti pàṣẹ. Èmi kò yípadà kúrò nínú àṣẹ rẹ bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gbàgbé ọ̀kankan nínú wọn.
Èmi kò jẹ lára ohun mímọ́ ní ìgbà tí mo ń ṣọ̀fọ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mu nínú wọn ní ìgbà tí mo wà ní àìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi nínú wọn fún òkú. Èmi ti ṣe ìgbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run mi, èmi sì ti ṣe gbogbo ohun tí ó pàṣẹ fún mi.
Wo ilẹ̀ láti ọ̀run wá, ibùgbé mímọ́ rẹ, kí o sì bùkún fún àwọn ènìyàn Israẹli, àti fún ilẹ̀ náà tí ìwọ ti fi fún wa, bí ìwọ ti búra fún àwọn baba ńlá wa, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti fún oyin.”