God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Ṣe èyí kí a má ṣe ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ni ilẹ̀ rẹ, èyí tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún, kí ìwọ kí ó má bá a jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ títa.
Má ṣe pa òkúta ààlà aládùúgbò rẹ dà tí aṣíwájú rẹ fi lélẹ̀ nínú ogún tí ó gbà nínú ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ láti ni ní ìní.
àwọn méjèèjì tí àríyànjiyàn wà láàrín wọn gbọdọ̀ dúró níwájú Olúwa níwájú àwọn àlùfáà àti àwọn adájọ́ tí ó wà ní ibi iṣẹ́ ní ìgbà náà.
Nígbà tí o bá lọ sí ogun pẹ̀lú ọ̀tá rẹ, tí o sì rí ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti ológun tí ó jù ọ́ lọ, má ṣe bẹ̀rù u wọn, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ tí ń mú ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti, yóò wà pẹ̀lú rẹ.
Nítorí Olúwa Ọlọ́run yín ní bá yín lọ, láti bá àwọn ọ̀tá yín jà fún yín, láti gbà yín là.”
Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá fi lé ọ lọ́wọ́, kí ẹ̀yin kí ó fi ojú idà pa gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó wà níbẹ̀.
Ní ti obìnrin, àwọn ọmọdé, ohun ọ̀sìn àti gbogbo ohun tí ó kù nínú ìlú náà, o lè mú ìwọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ìkógun fún ara rẹ. O sì lè lo ìkógun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá rẹ.
Ṣùgbọ́n, nínú àwọn ìlú ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún, má ṣe dá ohun ẹlẹ́mìí kankan sí.
Pa wọ́n run pátápátá, àwọn ọmọ Hiti, ọmọ Amori, ọmọ Kenaani, ọmọ Peresi, ọmọ Hifi, ọmọ Jebusi gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti pa á láṣẹ fún ọ.
Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò kọ́ ọ láti tẹ̀lé gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe nínú sí sin àwọn ọlọ́run wọn, ìwọ yóò sì ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.
Tí a bá rí ọkùnrin tí a pa, ní ìdùbúlẹ̀ ní pápá nínú ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ láti jogún, tí a kò sì mọ ẹni tí ó pa á,
Àwọn àlùfáà, ọmọ Lefi yóò wá síwájú, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti yàn wọ́n láti ṣe ìránṣẹ́ fún un àti láti bùkún ní orúkọ Olúwa àti láti parí gbogbo ẹjọ́ àríyànjiyàn àti ọ̀rọ̀ ìlú.
Dáríjì, Olúwa, àwọn ènìyàn rẹ ni Israẹli, tí ìwọ ti dá sílẹ̀, àti kí ìwọ má ṣe gba ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ ní àárín àwọn ènìyàn rẹ ní Israẹli. Ṣùgbọ́n kí a dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ yìí jì.
Nígbà náà ni ìwọ wẹ̀ kúrò láàrín rẹ ẹ̀bi títa ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí o ti ṣe èyí tí ó tọ́ níwájú Olúwa.
Nígbà tí o bá lọ sí ogun sí àwọn ọ̀tá rẹ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ tí o sì mú àwọn ìgbèkùn,
o kò gbọdọ̀ fi òkú rẹ̀ sílẹ̀ sára igi ní gbogbo òru. Gbìyànjú láti sin ín ní ọjọ́ náà gan an, nítorí ẹni tí a bá gbé kọ́ sórí igi wà lábẹ́ ègún Ọlọ́run. Ìwọ kò gbọdọ̀ ba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún jẹ́.
Obìnrin kò gbọdọ̀ wọ aṣọ ọkùnrin, tàbí kí ọkùnrin wọ aṣọ obìnrin, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó ṣe èyí.
Kí ẹnikẹ́ni tí a fọ́ ní kóró ẹpọ̀n nípa rírùn tàbí gígé má ṣe wọ inú ìjọ Olúwa wá.
Kí ọmọ àlè má ṣe wọ ìpéjọ Olúwa, pàápàá títí dé ìran kẹwàá.
Kí ọmọ Ammoni tàbí ọmọ Moabu, kì yóò wọ ìjọ Olúwa, àní títí dé ìran kẹwàá, ènìyàn wọn kan kì yóò wọ inú ìjọ ènìyàn Olúwa láéláé.
Síbẹ̀síbẹ̀, Olúwa Ọlọ́run rẹ kò ní fetí sí Balaamu ṣùgbọ́n ó yí ègún sí ìbùkún fún ọ, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ fẹ́ràn rẹ.
Ìran kẹta àwọn ọmọ tí a bí fún wọn lè wọ ìpéjọ Olúwa.
Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń rìn láàrín àgọ́ láti dáàbò bò ọ́ àti láti fi àwọn ọ̀tá à rẹ lé ọ lọ́wọ́. Àgọ́ rẹ ní láti jẹ́ mímọ́, nítorí kí ó má ba à rí ohun àìtọ́ láàrín yín kí ó sì yípadà kúrò lọ́dọ̀ yín.
Ìwọ kò gbọdọ̀ mú owó iṣẹ́ panṣágà obìnrin tàbí ọkùnrin wá sí ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ láti fi san ẹ̀jẹ́ kankan; nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ kórìíra àwọn méjèèjì.
Ìwọ lè ka èlé sí àlejò lọ́rùn, ṣùgbọ́n kì í ṣe arákùnrin ọmọ Israẹli, nítorí kí Olúwa Ọlọ́run rẹ lè bùkún ọ nínú ohun gbogbo tí o bá dáwọ́lé ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.